Hílíọ̀mù, Hélíọ̀m, tabi Helium (pípè /ˈhiːliəmu/, HEE-lee-əm) ni ẹ́límẹ̀ntì kẹ́míkà tó ní nọ́mbà átọ́mù 2 àti iwuwo atomu to je 4.002602, àmì ìdámọ̀ rẹ̀ ni He. O je efuufuoniatomukan, alaigbera, aláìláwọ̀, alailoorun, alainitowo, ati alailewu to siwaju ẹgbẹ́ ẹ̀fúùfù abíire ninu tabili asiko. Awon ojuami ìhó àti ìyọ́ rẹ̀ je awon ti won kerejulo larin awon ẹ́límẹ̀ntì, o si wa pere gege bi efuufu ayafi nigba to ba wa nipo lounloun. Leyin hydrogen, ohun ni elimenti keji to pojulo ni agbalaaye, o si je bi 24% gbogbo akojo elimenti ninu galaksi wa.
↑Meija, Juris; Coplen, Tyler B.; Berglund, Michael; Brand, Willi A.; De Bièvre, Paul; Gröning, Manfred; Holden, Norman E.; Irrgeher, Johanna et al. (2016). "Atomic weights of the elements 2013 (IUPAC Technical Report)". Pure and Applied Chemistry88 (3): 265–91. doi:10.1515/pac-2015-0305.