Jump to content

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣiyan Oyèwẹ̀sọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Professor Siyan Oyeweso at a conference

Ṣiyan Oyèwẹ̀sọ̀ tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kíní oṣù Kejì, ọdún 1961 [1] ní Ìta Ìdí-Ọmọ ní agbègbè Màpó Ọjà Ọba, ní ìlú Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni oriilẹ-ede Nàìjíríà. Wọn bi Ṣiyan sínú ẹbí ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Ìdílé Oyeweso ni wọ́n ṣẹ̀ wá láti agbolé Olójò ní ìlú Ẹdẹìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [2]


Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣiyan Oyèwẹ̀sọ̀ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Peter's Anglican Primary School, tí ó wà ní agbèbgè Ṣẹ́kọ́nà-Ẹdẹ, láàrín ọdún 1967 sí ọdún 1972 lẹ́yìn tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́fà gbáko. Lẹ́yìn èyí, ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Oke Iragbiji Grammar School láàrín ọdún 1973 sí ọdún 1978. Lẹ́yìn èyí ni ó tẹ̀ síwàjù nìgbà tí ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ ti Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìtàn láàrín ọdún 1978 sí 1982, tí ó sì jáde pẹ̀lú ìpele gíga jùlọ ẹlẹ́kejì (Second Class Upper). Ó ṣe Agùnbánirọ̀ rẹ̀ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ìtàn àti ẹ̀kọ́ àgbáyé ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ti Ilorin. Ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè M.A àti Ph.D tí ó sọọ́ di Ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ Intellectual History ní Ilé-ẹ̀kọ́ yí kan náà. [3]. Ṣiyan Oyèwẹ̀sọ̀ dara pọ̀ mọ́ Fásitì ìlú Èkó gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ọ́ ní ọdún 1985 gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ adánilẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ̀ Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó tí ó wà ní agbègbè Ọ̀jọ́, wọ́n sì fun ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ sí ipò olùkọ́ni onípele ìkejì ní ọdún 1987 àti ipò olùkọ́ni onìpele kínní ní ọdún 1989. Wọ́n sọọ́ di olùkọ́ni àgbà ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìtàn ní ọdún 1992. Ó sì tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ òun ìwádí tí tí ó fi gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ ìtàn ní ọdún 2004.[4]

Àwọn ipo ti o dimu nile-ẹkọ LASU

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ipò adarí ẹ̀ka ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lásìkò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àgbà àti ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìtàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ nílè-ẹ̀kọ́ Lasu, Ṣiyan di àwọn ipò pàtàkì kọ̀ọ̀kan mú gẹ́gẹ́ bí alẹ́nulọ́rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nílè ẹ̀kọ́ náà.

  • Ó di ipò Adarí (HoD) fún ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ nípa ìtàn àti Ẹ̀kọ́ kárí-ayé (Department of History and International Studies),
  • Ó ti ṣe Alábòójútó gbogbo gbòò (Dean) fún abala Ìmọ̀ Àtinudá (Faculty of Arts).
  • Ó tún wà lára àwọn ìgbìmọ̀ olùfọkàntán ilé-ẹ̀kọ́ náà (International Board of Trustees of Lagos State University Centre for Democracy and Development Studies) (CDDS). [5]

Ipò Igbìmọ̀ Aláṣẹ ní LASU

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kò tán síbẹ̀, Oyèwẹ̀sọ̀ tún di ipò pàtàkì mú láàrín àwọn aláṣẹ ilé-ẹ̀kọ́ fásitì Ipinle Eko, lára rẹ̀ ni:

  • Director, Centre for General Studies; Deputy Director, School of Part-Time Studies (Internal Operations);
  • Chairman, of the Ceremonials Committee;
  • Member, Implementation Committee for the establishment of the Faculty of Management Sciences ati
  • Member, Implementation Committee for the establishment of LASU School of Communication.

Oyèwẹ̀sọ̀ tún ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kaàrún ún àti ẹlẹ́kẹfà ilé-ẹ̀kọ́ Lasu lábẹ́ àwọn adarì bíi: Otunba J.K. Randle (1995-1998) àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Deji Femi-Pearse (1999-2003).

Ó tún ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìgbìmọ̀ alákòóso ẹlẹ́ẹ̀keje ilé-ẹ̀kọ́ náà lábẹ adari wọn Ọ̀gbẹ́ni Akin Kekere-Ekun tí ò jẹ́ Alàga tí Pro-Chancellor fun igbimọ naa laarin ọdun 2004 si ọdun 2006.

Ipa rẹ̀ ní Uniosun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2007, Oyèwẹ̀sọ̀ darapọ̀ mọ́ ilé-ẹ̀kọ́ fàsitì ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọdún 2007 níbi tí wọ́n ti fi ṣe adarí àti alákòóso Ágbà yányán fún ilé-ẹ̀kọ́ College of Humanities and Culture lati ibẹrẹ oṣù kẹjọ ọdún 2007 sí 2011. Lásìkò yí, àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè nírúurú ni Oyèwẹ̀sọ̀ ń gbéṣe láti lè mú ìdàgbàsókè bá ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ó dipò oríṣiríṣi mú nìlè ẹ̀kọ́ náà láti orí olùkọ́, Alábòójútò ilé-ẹ̀kọ́, Alága, Adarí ìgbìmọ̀ ilé-ẹ̀kọ́, Alábòójútó àgba, Adarí àgba fún ohun àmúṣọrọ̀ ọmọnìyàn òun ìdàgbàsókè ( Centre for Human Resource Development). Ó tún ṣe adarí ẹ̀ka ìmọ̀ ìkẹ́kọ́ títí láé-làé (Life-Long Learning) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[6]

Awọn awujọ ti o ti jẹ ọmọ-ẹgbẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣiyan Oyewẹsọ je ikan pataki ninu awọn opo ti o gbe ajọ Centre for Black Culture and International Understanding[7] ti o jẹ ẹka keji fun ajọ UNESCO, ti o wa nilu Òṣogbo, nibi ti o ti jẹ ikan ninu awọn igbimọ alakooso ajọ naa. O jẹ ikan ninu ọmọ igbimọ ajọ Institute for African Culture and International Understanding[8]. O tun jẹ ikan lara ọmọ igbimọ ajọ Olusegun Obasanjo Presidential Library (OOPL), ti o wa nilu Abẹ́òkúta. O tun jẹ olugbanimọran ati alakooso igbimọ fun ajo US Based Historical Africa Cultural Centre, ti o jẹ ajọ oniṣẹ ọfẹ ti ko gbara le ijọba ti wọn si gbe igbega ati ifihan Itan ilẹ Adulawo aye-ijọun ti o fi mọ àṣà, iṣe ọnà, orin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn to laami-laaka laarin awọn onimọ itan, Oyewẹsọ ti kọ awọn ènìyàn oriṣiriṣi ti awọn naa ti di igi araba ni awọn ile-ẹko giga oriṣiriṣi nibi ti wọn wa lonii.[9]

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn to laami-laaka, Oyewẹsọ ti ṣe agbejade awọn iṣẹ iwadi lori awon koko oriṣiriṣi gẹgẹ bi ìwé atẹjade ti wọn ti ju igba lọ. Bakan naa ni Ọjọgbọn Oyewẹsọ ti kọ awọn iwe apilẹkọ ti wọn jẹ ẹri maajeminiṣo fun imọ. Lara awọn iwe atẹjade rẹ ni:

  • Eminent Yoruba Muslims (Ibadan, Rex Charles, 1999);
  • Journey from Epe: Biography of S.L. Edu (Lagos: West African Book Publishers, 1996);
  • Torch Bearers of Islam in Lagos State (Ibadan: Matrix Books Ltd, 2008) ati
  • Actors and Institutions in the Development of Islam in Lagos State (Ibadan: Matrix Books Ltd, 2013), ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹwẹ, Oyewẹsọ ti pawọpọ pelu Ọgbeni Ṣola Akinnrinade lati kọ iwe lori Perspectives on Higher Education and Good Governance in Nigeria (Ibadan: Noirledge Publishing, 2019), ati Pivotal Issues in Higher Education Development in Nigeria (University Press Plc, Ibadan, 2020). Oun ati Ọjọgbọn Olutayo Adesina ti pawọpọ kọ iwe ti wọn pe akori rẹ ni Oyo: History, Tradition and Royalty (Ibadan, Ibadan University Press, 2021. 201pp.); ati The Royal Institution in Yoruba Tradition and Popular Culture (Ibadan, John Archers, 2021, 266 pp.) ti o fi mọ A Celebration of God’s Grace: Folorunso Alakija @ 70 (Osogbo: UNIOSUN Publishing House) ti o kọ pẹlu Olukoya Ogen. [10]

Àwọn àmì ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Si yan ti gba ọpọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ ìdáni lọ́lá ní ilẹ̀ Nàìjíríà àti òkè òkun. [11]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "50 GOLDEN CHEERS TO SIYAN OYEWESO". Nigerian Voice. Retrieved 2019-12-29. 
  2. benfestus@federalpolyede.edu.ng. "Federal Polytechnic Ede, Osun State, Nigeria". Federal Polytechnic Ede, Osun State, Nigeria. Retrieved 2019-12-29. 
  3. "Mobolaji Johnson Colloquium: Leaders advised to render impactful governance". P.M. News. 2019-11-28. Retrieved 2019-12-29. 
  4. "Aisha Buhari Speaks On Arrest Of Her ADC, Sani Baban-Inna Over N2.5Billion Fraud - Politics". Nigeria. 2019-12-29. Retrieved 2019-12-29. 
  5. Premium Times Nigeria https://www.premiumtimesng.com/opinion/440326-oyeweso-a-celebrated-historian-ascends-the-sixth-floor-by-tunde-akanni.html?tztc=1. Retrieved 2023-09-18.  Missing or empty |title= (help)
  6. "Siyan OYEWESO — Professor — Osun State University, Osogbo — Department of History and International Studies". ResearchGate. 2021-08-17. Retrieved 2023-09-18. 
  7. Oluwafunminiyi, RAHEEM (2019). "The Ulli Beier Archives at the Centre for Black Culture and International Understanding (CBCIU), Nigeria, and a Summary of Holdings". Africa Bibliography (Cambridge University Press (CUP)) 2018: vii–xxii. doi:10.1017/s0266673119000023. ISSN 0266-6731. 
  8. "Home". The Institute for African Culture and International Understanding (IACIU). 2022-01-26. Archived from the original on 2023-12-31. Retrieved 2023-09-18. 
  9. Oladosu, Rahma (2021-02-01). "OYEWESO: Distinguished Historian, ascension to the Sixth Floor". Economic Confidential. Retrieved 2023-09-18. 
  10. "Siyan Oyeweso". ‪Google Scholar‬. 2011-10-13. Retrieved 2023-09-18. 
  11. "OYEWESO, Prof. Siyan". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-03-03. Retrieved 2019-12-29.