Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Málì
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Málì | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Mali |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Bamako, Kayes |
Arrival date | 25 March 2020 (4 years, 8 months, 1 week and 2 days) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 2,467 (as of 17 July)[1] |
Active cases | 555 (as of 17 July)[1] |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,791 (as of 17 July)[1] |
Iye àwọn aláìsí | 121 (as of 17 July)[1] |
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Málì ní oṣù kẹta ọdún 2020.
Ìpìnlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejìlá oṣù ìkíní ọdún 2020, àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ni àgbáyé (World Health Organization) fìdí rẹ múlẹ̀ pé kòkòrò àrùn ẹ̀rankòrónà ni ó fa àrùn atégùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan, agbègbè Hube ní orílẹ̀-èdè China èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]
Ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ti SARS tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2003[3][4] sùgbọ́n bí àrùn yí ṣe ń tàn káàkà kiri pọ̀ púpọ̀ ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsì.[5]
Àwọn àkókò tí àrùn yí ń tàn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó n ṣẹlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oṣù Kẹta Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè Málì fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 méjì àkọ́kọ́ múlẹ̀.[6]
Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ilé-iṣẹ́ ti ìlera àti àwùjọ ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méjì. Ní èròngbà àti dojúkọ àjàkálẹ̀-àrùn tí ó n ja orílẹ̀-èdè yí, Ààre orílẹ̀-èdè olómìnira ti Málì, Ibrahim Boubacar keta, kéde ipò pàjáwìrì ní ìlú àti òfin kónílé ó gbélé láti agogo ̀mẹ́sán án àsálẹ́ sí agogo márùn ún òwúrọ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Málì.[7]
Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, pẹ̀lú àyẹ̀wò tuntun méje tí ó fìdí ẹ̀rankòrónà múlẹ̀ ní Málì, ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀rankòrónà ní orílẹ̀-èdè Málì lọ sókè sí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kànlá.[8]
Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, wọ́n fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méje múlẹ̀, àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ti ní àrùn COVID-19 wá di méjìdínlógún.[9] Isele eni akoko ti o je alaisi latipase ajakale-arun COVID-19 ni o waye ni osu yi.[10]
Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ènìyàn márùndínlọ́gbọ̀n ni àyèwò fìdí rẹ múlẹ̀ pé wọ́n ní àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19. Àwọn tí ń ṣe àkóso ètò ìlera sọ wípé àwọn ènìyàn méjì ló jẹ́ aláìsí.[11]
Oṣù Kẹrin Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ìparí oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ 490 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn 329 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ́n si ti jẹ́ aláìsí.
Oṣù Kárùn ún Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ìparí oṣù kárùn ún, ìṣẹ̀lẹ̀ 1265 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn 472 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn mẹ́tàdínlógórin ti jẹ́ aláìsí.
Oṣù Kẹfà Ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ìparí oṣú kẹfà, ìṣẹ̀lẹ̀ 2181 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nínú èyí tí ̀awọn ènìyàn 591 ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn 116 ti jẹ́ aláìsí.
Osu Keje Odun 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ni osu keje, isele 354 ni won fidi re mule, eyi ti o mu ki apapo gbogbo isele arun korona ni orile-ede mali di 2,535 ninu eyi ti awon eniyan 474 ti won n se aisan lowolowo ni opin osu keje. Iye awon alaisan ti won ti je alaisi lo soke lati mejo si merinlelogofa(124).
Osu Kejo Odun 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lati ojo kini osu kejo si ojo kerindinlogun osu kejo,eyi ti i se ojo meji saaju isote ti o yori si eyi ti awon ologun fi gba ijoba ni orile-ede yi, isele 2,640 ni won fidi re mule. awon alaisan 528 ni won n gba itoju lowolowo nigbati awon 1,987 alaisan ti ri iwosan gba ti awon alaisan ti o ti ku je marundinlaadoje(125). Ni osu kejo yi, awon isele ojilenigba le kan(241) ni won tun suyo eyi ti o mu ki apapo iye awon isele arun yi di 2,776. Iye awon alaisan ti o ku lo soke si merindinlaadoje(126). Ni opin osu yi, awon ti o n gba itoju lowolowo je 481.
Osun Kesan an Odun 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Titi di ojo kejila osu kesan an, 2,916 ni iye awon isele ti won fidi re mule , ninu eyi ti o je wipe awon ti o n gba itoju lowolowo je 512, awon alaisan ti o ti ri iwosan gba je 2,276 nigba ti awon alaisan ti o ti ku je mejidinlaadoje(1280). Ninu awon ojo ti o seku ninu osu kesan an, awon isele marundinlaadowaa(185) miran ni o tun suyo eyi ti o mu ki apapo iye awon isele arun korona di 3,101 ni orile-ede Mali. Awon meta ti o tun je alaisi mu ki apapo iye awon ti o ti ku di mokanlelaadoje(131). Iye awon alaisan ti won ti gba iwosan lo soke si 2,443 eyi ti o wa mu ki iye awon alaisan ti o n gba itoju lowolowo je 527 ni opin osu kesan an.
Àwọn ọ̀nà láti dènà àrùn COVID-19
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejídínlógún oṣù kẹta, Ààrẹ Ibrahim Boubacar Keita dá àwọn ọkọ̀ òfurufú tí wọ̀n ń bọ̀ láti orílẹ̀-èdè tí àjàkálẹ̀ àrùn yí ti ń ṣẹlẹ̀ dúró. Ààrẹ tún ti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ pa, ó sì fagilé àwọn àpèjọ tí ó bá tóbi. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìdìbò tí wọ́n ti gbèrò pé yí ò wáyé ní oṣù kẹta sí oṣù kẹrin, èyí tí wọ́n ti ń sún síwájú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀ nítorí pé ipò tí ètò ààbò wa ní orílẹ̀-èdè kò dára, ni wọ́n tẹ̀ síwájú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti gbèrò rẹ.[12]
Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 "Coronavirus in Africa tracker". bbc.co.uk. Retrieved 17 July 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-07-24.
- ↑ Higgins, Annabel (2020-07-24). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "Mali reports first 2 confirmed cases of COVID-19 - English.news.cn". Xinhua (in Edè Ṣáínà). 2020-03-25. Archived from the original on 2020-03-25. Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "Coronavirus au Mali : •4 cas enregistrés en deux jours • Le Président déclare l’état d’urgence sanitaire et instaure le couvre-feu". maliweb.net (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24. horizontal tab character in
|title=
at position 57 (help) - ↑ COULIBALY, Mariam. "7 nouveaux tests positifs de Coronavirus : le Mali passe à 11 cas". Studio Tamani : Toutes les voix du Mali : articles, journaux et débats en podcast (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24.
- ↑ Boureima (2020-03-28). "Coronavirus au Mali: sept nouveaux cas confirmés, le total passe à 18". Wakat Séra (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24.
- ↑ Dakaractu (2020-03-28). "Coronavirus : Le Mali enregistre son premier décès.". DAKARACTU.COM (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "Mali: Situation du Coronavirus au Mali ; Le pays enregistre 25 cas et 2 décès en mois d’une semaine". maliactu.net (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-07-24.
- ↑ "Mali Proceeds With Elections Despite Coronavirus Fears". Channels Television. 2020-03-19. Retrieved 2020-07-24.