Chiwetalu Agu
Chiwetalu Agu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Chiwetalu Agu 1956 Ìpínlẹ̀ Enugu, |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Orúkọ míràn | Okpantuecha |
Iṣẹ́ | Òṣèré |
Chiwetalu Agu jẹ́ ògbóntagì òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí ní ọdún 1956. [1] ó jẹ́ aláwàdà ati olùgbéré-jáde tí ó gba amì-ẹ̀yẹ ti Òṣèré kùrin tó peregedé jùlọ nínú eré ìbílẹ̀ níbi ìsàmì ayẹyẹ Nollywood ní ọdún 2012. [2] Àwọn ọlọ́kan-ò-jọkan ìpèdè rẹ̀ tí ó ma ń lò nínú eré ni ó sọọ́ di ààyò àwọn ènìyàn ní ilé àti lókè òkun.[3]Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwàdà jẹ́ ọ̀kan nínú irinṣẹ́ tí a lè máa lò láti gbé àṣà ati ìṣe orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga ní ojú àwọn ènìyàn ilẹ̀ òkèrè.[4]Agu ṣe ìgbéyàwó pẹ́lú aya rẹ̀ Nkechi, wọ́n sì bí ọmọ [ọkùnrin]] mẹ́ta ati obìnrin méjì.
Ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Agu bẹ̀rẹ̀ eré ní pẹrẹ́u pẹ́lú àwọn ipa irísirṣi tí ó ti kó nínú àwọn eré onípele àtìgbà-dégbà tí wọ́n má ń ṣàfihàn wọn lórí àwọn ìkanì ẹ̀rọ amóhù-máwòrán ilẹ̀ wa ṣáájú kí wọ́n tó dá ilé-iṣẹ́ Nollywood sílẹ̀ ní nkan bí ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹ́yìn. [5] [6] Ó kópa nínú àwọn eré onípele bíi: Baby Come Now ati Ripples (inLagos), tí Zeb, abúrò Chico Ejiro gbé jáde. Agu tún kópa ní eré mìíràn bíi ẹ̀dá ìtàn Abunna.
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A rí akọsílẹ̀ tí ó fìdí rẹ̀.múlẹ̀ wípé Agu ti kópa ní ú eré tí ó ti tó àádọ́ta. [7]
Ọdún | Eré | Ipa tí ó kó | Àríwísí |
---|---|---|---|
Last Ofalla 1-4 | |||
Taboo | Ichie Ogwu | ||
1986 | Things Fall Apart | ||
Ripples | |||
2008 | Return of Justice By Fire | ||
Traditional Marriage 1 & 2 | |||
Fire on the Mountain 1 & 2 | |||
Price of the Wicked | |||
Dr. Thomas | with Sam Loco Efe | ||
The Priest Must Die | |||
The Price of Sacrifice | |||
The Catechist | |||
Police Recruit | |||
Sunrise 1 & 2 | |||
Old School 1-3 | |||
Honorable 1 & 2 | |||
Sounds of Love 1 & 2 | |||
Nkwocha | |||
Across the Niger | |||
The Plain Truth 1 7 2 |
Sounds of Love 1 & 2 | |||
Church Man 1 & 2 | Ukpabi | ||
Holy Anger 1 & 2 | |||
Evil Twin | with Pete Edochie | ||
Beauty and the Beast 1-3 | |||
Royal Messengers 1 & 2 | |||
Royal Destiny 1 & 2 | |||
2007 | Burning kingdom 1 & 2 | ||
The Maidens | with Clarion Chukwurah | ||
Battle of the Gods 1 & 2 | |||
2017 | The Wedding Party 2 | with Adesua Etomi | |
2019 | Ordinary Fellows[8] | Mr. Mgbu | a film by Lorenzo Menakaya |
Àwọn sinimá agbéléwò rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Title | Director | Ref |
---|---|---|---|
2016 | Agbommma Cameo appearance | Tchidi Chekere | [9] |
Àìgbọ́ra-ẹni- yé tí ó wáyé lórí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Agu fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn wípé òun yoo ma bèrè fún owó gidi nígba-kúùgbà tí wọ́n bá fẹ́ kí òun kópa nínú eré kan tàbí òmíràn. [10] Ó sì tún ṣàfiwé awuye-wuye tí ó ń jà ràìn ní ìgboro ẹnu lórí ìhùwà ẹ̀gbin síni nípq ìbálòpọ̀ tí ṣẹlẹ̀ ní agbo Nollywood gẹ́gẹ́ bí ìṣesí ọmọ ènìyàn. Ó tún fi kun wípé àwọn olóríire ni àwọn òṣèré Nollywood. [11][12]
Àwọn ìfisọrí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n yàn án fún amì-ẹ̀yẹ òṣèré ìbílẹ̀ tí ó gbayì jùlọ nínú eré ìbílẹ̀ ní ú ayẹyẹ ìdánilọ́lá ti Nollywood alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ tí ó wáyé ní ọdún 2012, fún ipa rẹ̀ tí ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn Nkwocha.[13] Ipa tí Agu kó nínú eré The Maidens fún ní ànfaní láti jẹ́ kí wọ́n yàn án fún amì-ẹ̀yẹ ti "Òṣèrékùnrin amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ tó peregedé jùlọ níbi ayẹ ti * Zulu African Film Academy Awards (ZAFAA London) 2011.[14]
Àwọn Amì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Agu ni ó gba amì-ẹ̀yẹ ti Nollywood alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ ní ọdún 2012, fún Òṣèrékùnrin tí ó peregedé jùlọ nínú eré ìbílẹ̀. Ó sì tún gba amì-ẹ̀yẹ fún ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn Nkwocha.Àdàkọ:Cn
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "AMAA Nominees and Winners 2009". Retrieved 2013-08-01.
- ↑ "Nollywood Movie Awards 2012". Archived from the original on 18 November 2012. Retrieved 7 Jan 2013. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Nigeria Films news "I'll act for good price-chiwetalu agu". Archived from the original on 9 November 2011. Retrieved 8 Jan 2013. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Supple Magazine "nollywood: reconstructing the historical and socio-cultural contexts of the Nigerian video film industry". Retrieved 27 Dec 2012.
- ↑ Ghana Visions "nollywood movie actors-chiwetalu agu". Archived from the original on 25 July 2014. Retrieved 8 Jan 2013. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Cooper-Chen, Anne (2005), p106 Global entertainment media: content, audiences, issues LEA's communication series.. Routledge. ISBN 0-8058-5169-0. https://books.google.com/books?id=gb8Bkmq5254C&pg=PA106&redir_esc=y#v=onepage&q&f=false.
- ↑ IMDb "chiwetalu agu movies". Retrieved 8 Jan 2013.
- ↑ "Wale Ojo, Somadina Adinma and Chiwetalu Agu star in “Ordinary Fellows,” new Nollywood movie produced by Lorenzo Menakaya » YNaija". YNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-07. Retrieved 2020-05-17.
- ↑ "Kcee Patience Ozorkwor, Chiwetalu Agu, star in singer's 'Agbomma' video". Pulse.com.gh. David Mawuli. Retrieved 9 February 2016.
- ↑ Nigerian Voice "I'll act for good price-chiwetalu agu". Retrieved 7 Jan 2013.
- ↑ Nigeria Films news "sexual harassment: nollywood actresses are well endowed-chiwetalu agu". Archived from the original on 31 October 2012. Retrieved 10 Nov 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Daily Independent "Acting has opened door for me". Archived from the original on 27 October 2012. Retrieved 29 Dec 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Daily Times "Nollywood movie Awards set hold". Archived from the original on 2013-03-16. Retrieved 23 Dec 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ African Movie News "African Movie news". Archived from the original on 23 June 2012. Retrieved 11 Dec 2012.
- Pages with citations using unsupported parameters
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- No local image but image on Wikidata
- Nigerian male film actors
- Àwọn ènìyàn alààyè
- Male actors from Enugu State
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1956
- Date of birth missing (living people)
- 20th-century Nigerian male actors
- 21st-century Nigerian male actors