Ijogbon

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ijogbon
AdaríKunle Afolayan
Olùgbékalẹ̀Kunle Afolayan
Òǹkọ̀wéTunde Babalola
Àwọn òṣèré
OlùpínNetflix
Déètì àgbéjáde
  • Oṣù Kẹ̀wá 13, 2023 (2023-10-13)
Orílẹ̀-èdèNigeria

Ijogbon jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí Kunle Afolayan gbé jáde, tí Netflix gbe síta fún wíwò.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn fíìmù mẹ́ta tí Kunle Afolayan tọwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú Netflix láti gbé jáde.[2] Tunde Babalola ló kọ fíìmù yìí, tí Netflix sì gbé jáde ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹwàá ọdún 2023.[3][4] Lára àwọn akópa inú fíìmù náà ni Gabriel Afolayan, Adunni Ade, Dorathy Bachor, Sam Dede, Femi Branch, Yemi Sodimu, Bimbo Manuel, Yemi Solade àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5] Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọ́n ti ya fíìmù yìí, ní KAP Film Village and Resort.[3]

Ìtàn ní ṣókí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ijogbon, dá lórí ìtàn àwọn ọ̀dọ́mọdé mẹ́rin tó wà ní ìlú kékeré kan, ní apá Ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.[6] Àwọn ọ̀dọ́mọdé mẹ́rin yìí ṣàwárí àpò kan tó kún fún àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì, tí wọ́n sì pinnu láti fi pamọ́, ìpinnu yìí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ búburú wá, tí ó sì fi wọ́n sínú ewu ńlá.[1][7]

Àwọn akópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àṣàyàn àwọn akópa fíìmù náà ni:[2][7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "Trailer Gives a Glimpse of Afolayan’s ‘Ijogbon’ – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-09-30. 
  2. 2.0 2.1 "Afolayan’s ‘Ijogbon’ Explores the Universality of Human Emotions – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-09-30. 
  3. 3.0 3.1 Chikelu, Chinelo (2023-09-15). "Netflix Releases Trailer For Kunle Afolayan’s Ijogbon" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-30. 
  4. Stephen, Onu (2023-10-15). "MOVIE REVIEW: Ijogbon: Another ‘diamond’ coming-of-age story that shines brighter on morals". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-22. 
  5. Udodiong, Inemesit (2023-01-28). "'Ijogbon': Here's your first look at Kunle Afolayan's new movie". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-30. 
  6. Afolayan, Kunle (2023-10-13), Ijogbon (Drama, Thriller), Fawas Aina, Ebiesuwa Oluwaseyi, Ruby Akubueze, Golden Effects, retrieved 2024-01-22 
  7. 7.0 7.1 "Kunle Afolayan wraps up shoot on Ijogbon". guardian.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-30.