Jump to content

Ìkàrẹ́-Akóko

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ikare, Nigeria)
Ìkàrẹ́-Akóko
Ilu
Orílẹ̀-èdè Naijiria
IpinleOndo
Agbegbe Ijoba IbileAriwa-Ilaorun Akoko
Ìtàn ṣókí nípa Ikare-Akoko láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Ikare-Akoko.

Ìkàrẹ́-Akóko tabi Ìkàrẹ́ ni soki je olú ìlú Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá-Ìlà òrùn Àkókó̀Ipínlẹ̀ Òndó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó tún jé olú-ìlú tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ fún gbogbo agbègbè Àkókó lápapò ní Ìpínlè Ondó. Àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè Ìkàrẹ́ tẹ́lẹ̀ ni Ọ̀kà-Àkókó ,Ìṣùà Àkókó , Ọ̀gbàgì-Àkókó,  Òkèàgbè-Àkókó, Ìrùn-Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìkàrẹ́-Àkókó ni olú ilé ịṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Àkókó North-East Local Government wà. Ìlú náà sì tó iye ọgọ́rùn ún kìlọ́mítà (100 km) sí ìlú Àkúrẹ́ tí ó jẹ́ olú ìlú fún gbogbo Ìpínlẹ̀ Òndó lápapọ̀. Àkókó wà ní agbede-méjì àríwá àti ìlà oòrùn Ìpínlè Ondó.̀ Ohun tí wọ́n fi ń ṣọrọ̀ ajé ní ìlú Ìkàrẹ́ ni ǹkan ọ̀gbìn bíi: obì, kòkó, iṣu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn ìlú tí Ìkàrẹ́ bá pààlà ni: Arigidi, Ùgbè, Ọ̀gbàgì,Ọ̀kà-Àkókó ,Àkùngbá-Àkókó àti Ṣúpárè .[1]

Tí a bá ń sọ nípa ẹ̀kọ́ kíkọ́, Ìkàrẹ́ kò gbẹ́yìn láàrín àwọn ìlú tí wọ́n gbé ẹ̀kọ́ lárugẹ ní Ilẹ̀ Yorùbá. Lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n wà ní ìlú Ìkàrẹ́ ni: '''Agóló High School, Mount Carmel Secondary School, Ondo State College of Art and Science (tí ó ti di Federal Technical College, Òkegbèé quarters, Ìkàrẹ́); Ansar Ud-Deen Grammar School (AUD) Ikare Akoko, Agbaode Orimolade Grammar school Ikare; Osele High School Ikare Akoko, Victory College Ikare; Lennon Jubilee High School Ikare; Ikare Grammar School Ikare Akoko, Everlasting Premier College Ikare Akoko, Citadel International College, Ikare; Comprehensive high School, Ikare; Greater Tomorrow Primary School''' àti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni tí wọ́n wà ní Ìlú Ìkàrẹ́. Bákan náà ni àwọn ọmọ Ìkàrẹ́ kò fi ìwé kíkà ṣeré, tí ó sì ti gbé wọn dé ibi àti ipò gíga ní gbogbo àgbáyé.

Ètò ọrọ̀-ajé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìkàre jẹ́ ojúkò ọjà fún ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọjà tí wọ́n wà ní ìlú Ìkàrẹ́ bí Ọjà Ọba tí ó wà ní àdojúkọ ilé ìfowó-pamọ́ First Bank tẹ́lẹ̀, Ọjà Ọ̀kọrẹ̀ , Ọjà Òṣèlè ni ó jẹ́ ọjà tí wọ́n ti ń sábà ma ń ta àwọn ǹkan ìṣèmbáyé ìbílẹ̀ jùlọ ní Ìkàrẹ́, Ọjà Jubilee , àti àwọn ọjà míràn tí wọ́n so ìkàrẹ́ pọ̀ mọ́ àwọn ìlú míràn tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀. Ìlú ìkàrẹ́ tún jẹ́ ìlú tí àwọn tí wọ́n jẹ́ awakọ̀ èrò jẹun pọ̀ sí jùlọ.

Àwọn ènìyàn ìkàrẹ́ jẹ́ olùsìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ bí òrìṣà oríṣiríṣi bí :Ògún, Ọya, Ṣàngó Aringíyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà ni wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Ìmàle, kiristeni.

Ìṣesí ìlú náà bá ti àwọn ará ilẹ̀ Pọ́túgà àti ti àwọn Lárúbáwá mu nínú ẹ̀sìn, ìṣesí ti àwọn Potogí ni ó wọ ìlú náà ní àárín ọ̀rùndún Kẹrìndínlógún (16th century) nígbà tí òwò ẹrú bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè náà. Nígbà tí ìṣesí àwọn lárúbáwá wọ ìlú náà ní ǹkan bí ọ̀rùndún kọkàndínlógún(19th century) látàrí gbígba ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí wọ́n gba ẹ̀sìn náà.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Olusanya, Faboyede (2015). › ijah › article "Akokoland before Colonial Rule: Earliest Times to 1900". International Journal of Arts and Humanities 4: 46-65. https://www.ajol.info › ijah › article. 
  2. "Western Africa - The beginnings of European activity". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-06-16.