Jump to content

Iléṣà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Iléshà)
Ilesa
Ilesa is located in Nigeria
Ilesa
Ilesa
Location in Nigeria
Coordinates: 7°37′0″N 4°43′0″E / 7.61667°N 4.71667°E / 7.61667; 4.71667Coordinates: 7°37′0″N 4°43′0″E / 7.61667°N 4.71667°E / 7.61667; 4.71667
CountryNigeria
StateOsun State
Government
 • Owa Obokun AdimulaAromolaran II
Population
 (2016)
 • Total384,334
 (metropolitan area)
National languageYorùbá

Iléṣà jẹ́ ìlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ìtàn ṣókí nípa Ìlú Iléṣà

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ.

Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì. Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá)

Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ.

Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí Ọwálùsẹ padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀

òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro. Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí. Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ pé

“Ọ̀pá Ìpólé ku ogun

Ọ̀pá ijakuro ku ọgbọ̀n

Ọ̀pá Ẹ̀fọ̀n-Aláayè wọ́n ku mẹ́ta gege”

Àti ìgbàyí lo ti di òrìsà sí ìlú Ìpólé àti agbègbè Ìjẹ̀sà.

ÀWỌN ÌLÚ ÌJẸ̀SÀ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré. Àwọn ìlú naa nì wọ̀nyí

(1) Ìpólé

(2) Ìrógbó

(3) Ìwukùn

(4) Ìbòdì

(5) Ìtapá

(6) Òdò

(7) Olówu

(8) Ìperindó

(9) Ìlokò

(10) Ìwáráya

(11) Ìsè-Ìjẹ̀sà

(12) Ìlérín

(13) Ìjẹ̀bú- Jẹ̀sà

(14) Ìpetu- jẹ̀sà

(15) Èrìn –Ìjèsà

(16) Ìdómínàà

(17) Ìlásè

(18) Ìlówá

(19) Ìkíyìnwá

(20) Ifẹ̀wàrà

(21) Èsà-òkè

(22) Èsà-odò

(23) Ìbòkun

(24) Òtan-ilé

(25) Ìmèsí-ilé

(26) Òsú

(27) Ìpetu-ilé

(28) Ìlàrè

(29) Ìlayè

(30) Ìtagúnmodu

(31) Mogbàrà

(32) Òmò

(33) Ìgángán

(34) Ilésà gan-an

(35) Ẹ̀rìnmọ̀ Ìjẹ̀sà



ÀWỌN OYÈ PÀTÀKÌ NI ÌJẸ̀SÀ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí.

(1) Léjòfì

(2) Àrápaté

(3) Risawe

(4) Òdolé

(5) Lórò

(6) Ọbańlá

(7) Léjọ̀kà

(8) Sàwè

(9) Bajimọ

(10) sàlórò àti

(11) Yèyé ríse




ÈTÒ ÒSÈLÚ ÀTI ÈTÒ ÌJỌBA ÀWON ÌJẸ̀SÀ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl.

Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀.

ÀSÀ ÀWỌN ÌJẸ̀SÀ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn.

Lára àwọn ohun tí a ti le kíyèsí àsà dada ni

(1) oúńjẹ

(2) oge síse

(3) ijó

(4) orin

(5) Ìwọsọ

(1) OÚŃJẸ:-oúńjẹ jẹ́ ohun tí kò sé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwùjọ, bẹ si ni àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní àwọn oúńjẹ tí wọ́n fẹ́ràn. Tí a ba sọ̀rọ̀ nípa oúńjẹ tí Ìjẹ̀sà fẹ́ràn jù tàbí oúńjẹ ti o jẹ́ oúńjẹ pàtàkì a o ni sai lai dárúkọ iyán, nítorí iyán ní oúńjẹ pàtàkì tí Ìjẹ̀sà maa n jẹ, bí o tìlẹ́jẹ́ pé wọn tun ni àwọn oúńjẹ míràn bi àmàlà, Ẹ̀bà, Fùfú, ẹ̀wà, Ìrẹsì abbl. Sùgbọ́n iyán ni ọba oúńjẹ wọn .Ìjẹ̀sà le jẹ iyán ni ẹmẹẹta ni ojúmọ́ tàbí ni gbogbo Ìgbà àti àkókò nítorí náà, iyán jẹ oúńjẹ fún Ìjẹ̀sà.

(2) IJÓ :- Nípa ti ijó jíjó kò sí àdúgbò tí kò ní ijó tàbí orin ti wọn, àwọn ondo n ko obitun, Ìlàjẹ àti Ìkálẹ̀ ń kọ bírípo, bẹ́ nì ti àwọn Ìjẹ̀sà pẹlú ilésà ń kọ orin Àdàmọ̀, bẹ́nì wọ́n tun jọ ijó Ìkàngá ati ijó lóye pẹ̀lú Ìlù bẹ̀nbẹ́ àti orin Ìkàngá bákannáà. Onírúrurú orin ni a mọ̀ Ìjẹ̀sà mọ́ sùgbọ́n Ìkàngá àti loye ni o jẹ́ orin Ìpílẹ̀ wọn ti wọn maa ń kọ.

(3) ÌWỌSỌ:-maa tú jẹ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a tì lé rì àsà àti èdè Yorùbá bákannáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà kọọkan tún ní àsà ìwọsọ tí wọn. Àwọn obìnrín Ìjẹ̀sà maa nwọ àsọ̀ àfì tó jẹ́ Ìró àti bùbá bẹ́ni àwọn okùnrin wọn máà ń wọ esikí àti sòkòtò ẹlẹ́nu ńlá pẹ̀lú fìlà alabankata.

(4) OGE SÍSE:-jẹ́ àsà tí o sábà maa ń súyọ láàárín àwọn obìnrin pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn obìnrin Ìjẹ̀sà máà n lo lali, tiro, osùn láti fi soge.


ÀWỌN AKỌNI ÌJẸ̀SÀ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Ògèdèngbé
  • Ọrárálàdá
  • Ọlọ́pọ̀idà

Àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀sà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìjẹ̀sà jẹ́ alákíkánjú àti jagunjagun ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ní àwọn Ìjẹ̀sà ni pa nínú rẹ̀, ní àkókò ogun kariaye ilè Yorùbá. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ìjẹ̀sà ja a ni ogun Ìbàdàn, ogun Jalumu àti ogun Kiriji tàbí ogun Ekìtì parapọ̀. Ogun Èkìtì parapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1877, o sì perí ní ọdún 1886. Ẹni tí ó jẹ́ bí asíwájú ogun pàtàkì yìí ni okùnrin alajagun Ìjẹ̀sà kan ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ògèdèngbé .Ogun Èkìtì parapọ̀ yìí ni ó mú orúkọ Ògèdèngbe dúró sinsin nínú ìtàn Yorùbá ogn náà si ja fún ọdún mẹsan gbáko ọdún 1910 ní ògèdèngbé kú.

Ohun kan tí àwọn Ìjẹ̀sà se ni Ìrántí Ògèdèngbé tí ó jẹ́ olórí àwọn Ìjẹ̀sà wà ni eréjà Ilésà ní iwájú ilé Ìfowópamọ́ ti “National Bank of Nigeria Limited” lsẹ́ Àwọn Ìjẹ̀sà

Gbogbo àwọn ẹ̀yà ìyókù ní ilẹ̀ Yorùbá ní wọ́n mọ àwọn Ìjẹ̀sà sí onísòwò paraku idi ni yi tí wọn fi ń pe àwọn Ìjẹ̀sà ni “Òsómàáló”. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí kà nínú ìwé, a gbọ́ pẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà ni ó dá àsà san an díẹ̀dị́ẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìsòwò. Wọ́n màá n lọ láti ìlú dé ìlú àti ìletò de ìletò láti se isẹ́ ọjà títà wọn, ohun tí wọn si n ta ní pàtàkì ní asọ. Sùgbọ́n lónìí Ìjẹ̀sà ti kúrò ni a n kiri láti Ìlú de ìlú tàbí Ìletò de Ìletò, wọ́n ti wà nínú ilé ìtajà ní àwọn ìlú ńláńlá bíi, Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, Ògbómọ̀sọ́, Kano, Kaduna, òṣogbo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́hìn isẹ́ òwò síse ti a mọ si Òsómàló tí wọ́n máa ń kiri, wọ́n tún máa ń se isẹ́ àgbẹ̀ paraku nínú oko wọn, àwọn Ìjẹ̀sà a maa gbin kòkó, obì, isu, àgbàdo, káfé, ìrẹsì, àti orísì́ àwọn ohun jíjẹ míìràn. orísì àwọn isẹ́ míìràn tí àwọn Ìjẹ̀sà n se ni isẹ́ àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀de góòlù, isẹ́ gbénàgbénà, asọ híhun, aró dídá àti orísi isẹ́ míràn.

Àwọn ilé isẹ́ ti a lè rí ní ilésà ní “ International Breweries Limited Nigeria” ni ibití wọ́n ti ń se ọtí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Trophy Larger Beer” àti àwọn ohun amúlúdùn ti a lè rí ni ilésà lónìí ni iná mọ̀nàmọ́ná, pápá ìseré àti ilé ìtura. Ẹ̀sìn Àwọn Ìjẹ̀sà. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, kí àwọn òyìnbó tó kó ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá de orílè-èdè wa, àwọn Yorùbá ti ni ẹ̀́sìn ti wọn. llésà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ilẹ́ Yorùbá maa n sin àwọn òrìsà bii ògún, ọ̀sun, ifá, èsù, ọya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti o wá sí orilè - èdè yìí wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà ni nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́hìn ni a mọ̀ sí ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó ti àwọn lárúbáwá wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà.

Ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì náà ni a ti rí Ìjọ Àgùdà (Catholic), Ìjọ onítẹ̀bomi (Baptist) Ìjọ Elétò (Methodist) Ajíhìnrere Kírísítì (Christ Apostelic Church) kérúbù àti séráfù (Cherubim and Seraphim) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìjẹ̀sà ní Ìmọ̀ tí ó gbámúsé ní pa ètò ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjẹ̀sà ni o di ipò gíga mú ní ilé isẹ́ ìjọba fún àǹfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. tị́tí di àkòkò yìí ó tó nǹkan bí aadọta ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní igboro ilésà, ilé ẹ̀kọ́ girama méjìdínlógún àti ilé ìwé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ onípòkejì méjì. Ni àfikún, ìjọba tún ti dá ilé- ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkóni, fún ilé ẹ̀kọ́ giga sílẹ ni llésà ni ọdún 1977(Osun State College of Education) Àwọn òrìsà ilẹ̀ Ìjẹ̀sà Owari, Owaluse, Oludu, Oluaye, Ajitafa, Ogun, Omi/Osun. Sùgbọ́n àwọn òrìsà kò se bẹ gbilẹ̀ mọ́ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ọ̀kan soso lalè ri níbú wọn ti o dàbí ẹni pé wọn sin se ọdún rẹ.

Coordinates: 7°37′N 4°44′E / 7.617°N 4.733°E / 7.617; 4.733{{#coordinates:}}: cannot have more than one primary tag per page