Ilu Owu
Ẹ̀yà Owu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Yorùbá ní Ìwọ̀-Oòrùn Áfíríkà. Ago-Owu ní Abeokuta ni ibi ti àwọn Owu ti pọ̀jù sí, káàkiri ile Yoruba ni a sì ti máa ń rí àwọn Owu. Àjọṣepọ̀ ìjọba ilẹ̀ Yorùbá gbòòrò kọjá ilẹ̀ Nàìjíríà dé Orílẹ̀-èdè Benin àti Togo.[1][2]
Orísun
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn Owu kọ́kọ́ wáyé lẹ́yìn ìtẹ̀dó wọn ní Ago-Owu ní ọdún 1820. Ìtàn àròsọ Yorùbá mú wa gbàgbọ́ pé àwọ Owu tẹ̀dó sí agbègbè kan tààrà lẹ́ẹ̀bá odò Odò Ọya ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìṣílọ wọn sí apá Gúúsù wáyé látàrí ogun ẹ̀yà tó bẹ́ sílẹ̀. Láìfarajọ àwọn ìletò tẹ́lẹ̀, àwọn Owu ò gbìyànjú láti bá àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn jà, dípò èyí, wọ́n tẹ̀dó pẹ̀lú àlàáfíà nítorí àwọn aláṣẹ ìlú Ìbàdàn ti rán àwọn òjíṣẹ́ àlàáfíà sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn Owu ń bọ̀ láti wá kógun ja ìlú wọn. Àwọn olórí ìlú Ìbàdàn fi ilẹ̀ fún àwọn Owu láti máa gbé, wọ́n sì tàn láti Ita Lisa títí dé Owu Ipole lágbègbè Ikire.
Àjọ̀dún ọdún ìbílẹ̀ Owu
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìdí kan pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣàjọyọ̀ àjọ̀dún Owu ni láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlódùmarè fún ìpèsè gbogbo àìní wọn. Àṣà ṣíṣayẹyẹ ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999, ó sì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlọ́wọ́sí àwọn ará Owu mọ́ra àti àwọn ènìyàn káàkiri ayé. Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá, ọdún 2010, Olowu ti ilu Owu, tí ń ṣe Adegboyega Dosunmu Amororo II ṣe ìkéde ìta gbangba pé òpin ọ̀sẹ̀ kejì ní oṣù kẹwàá ni àwọn yóò máa ṣe àjọyọ̀ àti ìdúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè. Ìkéde yìí wáyé láti àjọ̀dún ọdún ìbílẹ̀ Owu pẹ̀lú àjọ̀dún Ọmọ Olówu. Àjọ̀dú Ọmọ Olówu yìí dàpọ̀ mọ́ àjọ̀dún iṣu tuntun, èyí tí Olówu fúnra rẹ̀ sọ, tí gbogbo ènìyàn sì tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú àtẹ́wọ́. Àwọn ènìyàn tó fi ìjókòó yẹ́ àjọ̀dún ti ọdún 2010 náà sí ni Ọọ̀ni Ifẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, tí ń ṣe Oba Okunade Sijuade Olubuse II (tó ti wàjà), Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí àti Balógun ti Owu, tí ń ṣe Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Chief of staff sí ààrẹ Goodluck Jonathan, Olóyè Mike Oghiedome, igbákejì Gómìnà ti ipinle Ogun nígbà kan rí àti alákòóso ECOMOG, tí ń ṣe Rtd General Tunji Olurin .
Ìwé àkọsílẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Owu in Yoruba history, Mabogunje, Akin L., Omer-Cooper, John D., Ibadan University Press, 1971
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Olowu to Alake on Ogun paramount rulership: Owu is not under your control". The Eagle Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-02-19.
- ↑ admin (2018-06-03). "A Commune of Brothers". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-02-19.