Laolu Akande
Laolu Akande | |
---|---|
Akande ní National Press Club Washington DC, US | |
Ọjọ́ìbí | Ibadan, Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Akọ̀ròyìn, òǹkọ̀wé |
Laolu Akande jẹ́ akọ̀ròyìn, olóòtú, ọ̀mọ̀wé àti olùkọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́, òun ni agbẹnusọ fún igbákejì ààrẹ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Prof. Yemi Osinbajo, SAN.[1][2][3][4] Ṣáájú kí ó tó di agbẹnusọ fún igbákejì ààrẹ, Akande ń jábọ̀ ìròyìn fún Empowered Newswire, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn kan tó wà ní orílẹ̀èdè Amerika, ó tún jẹ́ North America Bureau Chief fún The Guardian ní ìlú New York, ní America.[5]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìlú Ibadan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọ́n bí Akande sí. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Omolewa, àti Loyola College, ní Ibadan. Ó parí A-Levels ní ilé-ẹ̀kọ́ gihga ti Oyo State College of Arts and Sciences, ní Ilé-Ifẹ̀. [6] Ó kàwé gboyè ní yunifasiti ti Ibadan ní ọdún 1990, ó sì tún gboyè Masters ní Yunifasiti kan náà ní ọdún 1992.[7]
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdún 1989 ni Akande bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn kíkọ, ní ọdún 1989, nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn The Guardian gẹ́gẹ́ bíi ajábọ̀ ìròyìn.
Akande jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ News Magazine team nihgbà tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1993, gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé àgbà. Ó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Tempo publication nígbà tí ìjọba ológun fagi lé The News fún ìròyìn rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kí òmìnira tó dé.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Buhari Names Deputy Chief of Staff, Media Aide for Vice President Osinbajo". 4 September 2015. Archived from the original on 18 August 2021. Retrieved 27 March 2023.
- ↑ "2023 Presidential Polls: Osinbajo remains best man for the job - Laolu Akande, spokesman". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-06-04. Retrieved 2022-06-30.
- ↑ "Ignore speculations on Osinbajo announcing presidential bid after APC convention, Laolu Akande tells Nigerians". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-07. Retrieved 2022-06-30.
- ↑ "2023: Osinbajo'll build on Buhari's gains -Aide". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-12. Retrieved 2022-06-30.
- ↑ "Enahoro, Soyinka To Begin US PRONACO Confab Next Week". www.nigeriavillagesquare.com. Archived from the original on 2019-03-27. Retrieved 2023-03-27.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "6 Things You Should Know About Osinbajo's Spokesperson, Laolu Akande". 23 June 2015.