Yaba College
Coordinates: 6°31′07″N 3°22′27″E / 6.518615°N 3.37423°E
Yaba Higher College | |
---|---|
Active: | 1932—1948 |
Location: | Yaba |
Yábàá Higher College ni wọ́n dá kalẹ̀ ní ọdún 1932 ní Yábàá, ìpínlẹ̀ Ẹkó ní orílẹ̀-èdè Nàjíríà léte àti fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ẹ̀kọ́ gíga, pàá pàá jùlọ nípa ẹ̀kọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ àti ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́ni. Lẹ́yìn tí wọ́n bá tikọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yanjú tán ni wọn yóò gbàwọ́n tì wọn yóò sì gbé wọn lọ sí Fásitì Ìbàdàn . Ní ọdún 1948, wọ́n yí iké-ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ náà padà dí ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìyẹn Yaba College of Technology.
Ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yaba Higher College jẹ́ ọgbọ̀n àtinúdá ọ̀gbẹ́ni E.R.J. Hussey, ẹni tí ó padà di Alákòóso ètò-ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà (Director of Education in Nigeria) ní ọdún 1929. Nígbàbtí dépò yí tán ni ó tẹ́ pẹpẹ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Yábàá, gẹ́gẹ́ bì ó ṣe ṣe àgbékalẹ̀ irú ètò yí ní Makerere College ní Uganda nì ibi tí wọ́nb ti gbe wá sí orílẹ̀ èdè Nàjíríà. Ìdí pàtàkì tí wọ́n figba ọ̀gvẹ́ni yìí ni wá láti kọ́ àwọn amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìjọba àti àwọn àdáni , kí ètò-ẹ̀kọ́ le dàgbà sókè tó ti Fásitì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀gbẹ́ni Hussey bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ láti ilé-ìwé ìmọ̀ ìṣègùn King's College". Lásìkò ọdùn 1932, ilé ẹ̀kọ́ náà ti ní àwọn itàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tirẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ àfikún kọ̀ọ̀kan.[1]
.[2] Wọ́n fi Yábàá Colleg lọ́lẹ̀ ní January 1934.[3] níba tí wọ́n ti ń kọ́ni nímọ̀ iṣẹ-ọwọ́ tó fi mọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, aṣọ́gbó, ìṣègùn, ìtọ́jú ohun ọ̀sìn, ìwọnlẹ̀, àti ìmọ̀ iṣẹ́ àmúṣe-múlò ìmọ̀ ẹ̀rọ. Bákan náà ni wọ́n fún àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ọlọ́dún mẹ́fà onípele kejì(Secondary school teachers) ní ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ pàá pàá jùlọ nínú ìmọ̀ Syẹ́nsì.[4] Ilé-ẹ̀kọ́ Yábàá yí ni agbegbe ìkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ fún Fásitì ilẹ̀ Lọ́ndọ̀nù.[5] Ẹ̀wẹ̀, ilé-ẹ̀kọ́ náà ń fún ninní ìwé ẹ̀rí diploma oní gbèdéke fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó bá tún fẹẹ́ tẹ̀ síwájú si, yà ní ilẹ̀ baba wọn tàbí ilẹ̀ òkèrè, níoasẹ̀ ìlànà jókòó-sílé kàwé lókè òkun,tàbí nílànà jókòó nílé jàwé gboyè [6]
Ọ̀pọ̀ àọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríàtí wọ́n jẹ́ ọ́mọ̀wé ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ilé-ẹ̀kọ́ náà, pààpàá jùlọ ìwé ìròyìn olóhoojúmọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà tí a mọ̀ sí Nigerian Daily Times ni ó sọ àgvọ́ọ̀gbẹ ọ̀rọ̀ wípé: " ó jẹ́ èrò tó dára àti ọ̀nà tí ó tọ́ kí a má ṣe kọ́ ilé alárà sórí ìpìlẹ̀ tí ó mẹ́hẹ". Èyí nìwé ìròyìn yí fi ń tọ́ka sí àìperegedé ètò-ẹ̀kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ girama tí kò múná -dóko, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ibẹ̀ yóò fẹ́ láti wọn ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ ti Yábàá. Ẹ̀wẹ̀, ìwé ìròyìn náà tún fi kun wípé : " Óyẹ kí ìjọba ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé orílẹ̀-èdè yì kò ní fara mọ́ ètò-ẹ̀kọ́ tí kò péye tí ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀-èdè náà ń kojú ásìkò náà". [3]Àwọn ẹgbẹ́ Nigerian Youth Movement, tí wọ́n jẹ́ alátakò ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n tún padà di ẹgbẹ́ òṣèlú nílẹ̀ Nàìjíríà.[7]
Ìbẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nígbà tí ilé-ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1935, àqọn tí wọ́n pọ̀jù lọ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ìran Hausa, tí aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ ìgbà náà ìyẹn Morris, ṣe da lábà ní ọdún 1939 wípé kì ilé-ẹ̀kọ́ Yábàá bí láti kọ́ ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọ́n tí wọ́n wá láti Gúsù ilẹ̀ Nàìjíríà í wọ́n sì di olùkọ́ fún ìgbaradì ètò-ẹ̀kọ́ tó yanrantí nílé-ẹ̀kọ́ girama ní agbègbè Gúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ iwájú. Olùdarí Morris tún fi kun wípé kíkọ́ àwọn ará Gúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lẹ́kọ̀ọ́ gidi nílé-ẹ̀kọ́ Yábàá, kí wọ́n le dara pọ̀ mọ́ àwọn akẹ́gbẹ́ wọ́n láti Ìlà-Óòrùn níbi ètò ìgbani síṣẹ́ ìjọba. Àwọn aláṣeẹ mìíràn tún sọ qípé iṣẹ́ ka náà ni ilé-ẹ̀kọ́[8] Kaduna College.[9] yóò ṣe bí ti Yábàá tàbí kí ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ .[9]
Látàrí àìfẹsẹ̀ rinlẹ̀ ètò ìlànà ẹ̀kọ́ Yábàá College láwọn àsìkò kan, àwọn omilẹgbẹ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń wá láti wọlé sílé-ẹ̀kọ́ Fásitì ni wọ́n lọ aí ilé-ẹ̀kọ́ Fourah Bay College ní orílé-èdè Sierra Leone, tàbí kíbwọ́n lọbsí orílẹ̀-èdè USA tàbí Hnjted Kingdom tí wọ̀n bá lówóọ̀wọ́ .[10]Ní 1948 wọ́n gbé ilé-ẹ̀kọ́ Yábàà síwájú ai ibi tí wọ́n sì sọọ́ di University College of Ibadan.[11] Wọ́n gbé Yaba College of Technology, dìde ní ọdún 1947 nírọ̀ọ́pò Yaba Higher College, tíbwọ́n sì sọọ́ di ìpele ẹ̀kọ́ kejì lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ girama ọlọ̀dún mẹ́fà ẹ̀kejì, lẹyìn Fásitì ìlú Ìbàdàn.[12]
Lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ̀ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- T. M. Aluko, Novelist
- Ishaya Audu, Minister of External Affairs (Foreign Minister) from 1979 to 1983 under Shehu Shagari
- Stephen Oluwole Awokoya, minister of education in the old Western Region of Nigeria
- Olumbe Bassir, Sierra Leonean scientist and academic
- Saburi Biobaku, scholar and historian, pro-chancellor of the Obafemi Awolowo University.
- Akintola Deko, Minister for Agriculture in the Western region of Nigeria
- Joseph Chike Edozien, traditional ruler of Asaba, Nigeria in Delta State
- Erediauwa, Oba of Benin
- Samuel Fawehinmi, pioneering Nigerian furniture magnate
- Eni Njoku, First Vice-Chancellor of the University of Lagos and later Vice-Chancellor of the University of Nigeria
- Michael Okpara, Premier of Eastern Nigeria during the First Republic, from 1959 to 1966
- Ayo Rosiji, politician, statesman and former Minister for Health and Minister of Information
- Shehu Shagari, President of the Nigerian Second Republic (1979–1983)
- Tunji Sowande, Nigeria-born UK lawyer and musician
- Jaja Wachuku, first Nigerian Ambassador and Permanent Representative to the United Nations
- Akintola Williams, chartered accountant, founder of the Nigerian Stock Exchange and the Institute of Chartered Accountants of Nigeria
- Frederick Rotimi Williams, the first Nigerian to become a Senior Advocate of Nigeria
Àwọn ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Nwauwa 1997, pp. 58.
- ↑ Nwakanma 2010, pp. 48.
- ↑ 3.0 3.1 Nwauwa 1997, pp. 60.
- ↑ Nkulu 2005, pp. 52.
- ↑ Nkulu 2005, pp. 53.
- ↑ Nwakanma 2010, pp. 61.
- ↑ Nwauwa 1997, pp. 62.
- ↑ Hubbard 2000, pp. 97.
- ↑ 9.0 9.1 Hubbard 2000, pp. 98.
- ↑ Ekundare 1973, pp. 359.
- ↑ Nkulu 2005, pp. 54.
- ↑ Obiakor, & Gordon 2003, pp. 129.
Àwọn ìwé
- Ekundare, R.O. (1973). An Economic History of Nigeria 1860-1960. Holmes & Meier. ISBN 084190135X. https://books.google.com/books?id=GrcNAAAAQAAJ&pg=PA359.
- Hubbard, James Patrick (2000). Education under colonial rule: a history of Katsina College, 1921-1942. University Press of America. ISBN 0-7618-1589-9. https://books.google.com/books?id=BJsmQMRiHg0C&pg=PA97.
- Nkulu, Kiluba L. (2005). Serving the common good: a postcolonial African perspective on higher education. Peter Lang. ISBN 0-8204-7626-9. https://books.google.com/books?id=Ms9Bs9fUmpcC&pg=PA52.
- Nwakanma, Obi (2010). Christopher Okigbo 1930-67: Thirsting for Sunlight. Boydell & Brewer Ltd. ISBN 1-84701-013-X. https://books.google.com/books?id=SXBQwSO6VAgC&pg=PA61.
- Nwauwa, Apollos Okwuchi (1997). Imperialism, academe, and nationalism: Britain and university education for Africans, 1860-1960. Routledge. ISBN 0-7146-4668-7. https://books.google.com/books?id=_Lau0OF-6N4C&pg=PA60.
- Obiakor, Festus E.; Gordon, Jacob U. (2003). African perspectives in American higher education: invisible voices. Nova Publishers. ISBN 1-59033-683-6. https://books.google.com/books?id=lJ2t_GOXnMYC&pg=PA129.