Ini Dima-Okojie

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ini Dima-Okojie
Ọjọ́ìbíIpinlẹ Eko, Naijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaCovenant University
Iṣẹ́Osere,
Ìgbà iṣẹ́2014–iwoyi

Ini Dima-Okojie jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Dima-Okojie ní 24, Oṣù Kẹẹ̀fà, Ọdún 1990 sínu ìdílé eléyàn mẹ́rin. Ini Dima-Okojie ni àbígbẹ̀yìn. Ini wá láti ilé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n. Dókítà Ìṣògún ni bàbá rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Olùtọ́jú-òwò. Wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ Kátólìkì tọkàntọkàn.

Nígbà tí Ini n dàgbà, Ini súnmọ́ ìya rẹ̀ gaan ó sì fẹ́ láti dàbi rẹ̀. Ó fẹ́ràn láti máa wo ìya rẹ̀ nígbà tí ó bá n múra láti lọ ìdi iṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo bí ìya rẹ̀ ti máa n múra maá n dùn mọ́ Ini. Nítorínà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ràn oge ṣíṣe àti ìmúra bótilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ onítìjú èyàn, Ini bẹ̀rẹ̀ sí ní ní ìgboyà tó bá di toge ṣíṣe

Ní ìdà kejì, arábìnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́ ọ̀dọ́mọdé oníràwọ̀ tí ó tí kópa nínu eré “Mr. Jack’s Dog” eré kan tí ó gbajúmọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Eré náà fún Ini ní ànfàní láti káàkiri àgbáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀. Ní àkókò kan, ó lọ sí Istanbú, ní ìlu Tọ́kì níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìyàwòrán ijó Tọ́kì kan fún eré náà. Wọ́n fi lọ Ini láti ṣe ipa kan nínu eré ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣé nítorí ìtìjú rẹ̀.

Fún ìgbà pípẹ́, Ini n gbé nínu ọkàn rẹ̀. Yóó maa wo ìfihàn àwọn àmì ẹ̀yẹ tí yóó sì ma wùú bi pé kí ó wà níbè.

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ini lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ Air Force Comprehensive Secondary School ní ìlú Ìbàdàn Nàìjíríà. Lẹ́hìn èyí, ó tẹ̀síwájú sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Covenant University ní Nàìjíríà bákan náà

Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ àti àgúnbánirọ̀ rẹ̀, ó ríṣẹ́ sí ilé-iṣẹ́ ìtọ́jú òwò.

Àṣàyàn àwọn eré tí ó ti ṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]