Kàbà
Kabba | |
---|---|
Coordinates: cities7°50′00″N 6°04′00″E / 7.83333°N 6.06667°ECoordinates: 7°50′00″N 6°04′00″E / 7.83333°N 6.06667°E | |
Country | Nàìjíríà |
State | Kogi State |
Area | |
• Total | 330 km2 (130 sq mi) |
Time zone | UTC+1 (WAT (UTC+1)) |
National language | Yorùbá |
Kàbà jẹ́ ìlú kan tí ó wà ní inú ìpínlẹ̀ Kogi ní apá ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú yí wà ní ẹ̀bá odò Ọ̀sẹ́ tí ó súnmọ́ ojú ọ̀nà tí ó ń bọ̀ láti ìlú Lọ́kọ́ja, Okene, Ogidi, Ado-Ekiti àti ìlú Ẹ̀gbẹ̀. [1] It is 511 kilometers from Lagos.[2]
Ìtàn Ìwàṣẹ̀ àti ìmú lẹ́rú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nígbà ìwáṣẹ̀, ìlú kàbà jẹ́ ìlú amọ́nà Bida Emirate, lábẹ́ ìṣàkóso àwọn Fúlàní, Àwọn ọmọ ogun Bida lábẹ́ àkóso àwọn Fúlaní a máa kógun ja àwọn ẹ̀yà míràn tí wọn a sì ma mú wọn lẹ́rú. Lásìkò tí àwọn òyìnbó àmúnisìn ṣì ń jẹ gàba, wọ́n pín kàbà sí ọ̀nà mẹ́rin, tí wọ́n sì gbé ilé-ẹjọ́ ti ìgbàlódé ti ìjọba gẹ̀ẹ́sì àti ti ìbílẹ̀ náà kalẹ̀ fún ètò ìdájọ́ tó pinmirin. Ìjọba gẹ̀ẹ́sì dá àgọ́ ọlọ́pá sí ibi tí ó di ojúnà Lokoja lónìí.[3]
Bí ìlú náà ṣe rí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kàbà jẹ́ ojúkò fún kọfí, kòkó, iṣus, ẹ̀gẹ́, àgbàdo, ọjà bàbà, òrí, ẹ̀pà, ẹ̀wàs, òwú àti aṣọ híhun ilẹ̀ Yorùbá àti Ebira. Àwọn ènìyàn Kàbà a màá ń sọ ẹ̀ka èdè Yorùbá tí wọ́n ń pè ní Owé.
Ìlú Kàbà ni ó ń ṣe akóso ìjọba ìbílẹ̀ Kabba/Bunnu ní Ìpínlẹ̀ Kogi. Ẹni tí ó jẹ́ adarí fún ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Hon.E. O. Olorunleke Moses. Ìjọba alákòóso Kàbà pín sí mẹ́ta, àwọn: Obaro, Obadofin àti Obajemu. Obaro ni ó jẹ́ alákòóso tí ó wà nípa Ọba. Obaro tí ó wà nipò lọ́wọ́ yii ni Oba Solomon Owoniyi (Obaro Oweyomade 1), ẹni tí ó gorí àpèrè ní ọdún 2018 lẹ́yìn tí Oba Michael Olobayo (Obaro Ero Il) wàjà.[4] Ààfin rẹ̀ ni ó wà ní ibi tí wọ́n ń pè ní Odo-Aofin.
Àwọn ìletò tí ó wà ní Kàbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Aiyeteju,
- Odi-olowo,
- Kajola,
- Odo-ero,
- Odolu,
- Fehinti,
- Surulere,
- Ikowaopa
- Iyah,
- Otu,
- Egbeda,
- Gbeleko,
- Okedayo,
- Kakun,
- Ohakiti,
- Obele,
- Ogbagba,
- Ayonghon,
- Ayedun,
- Ayetoro Egunbe ti Obangogo,
- Iduge,
- Adesua,
- Asanta,
- Korede,
- Okekoko,
- Katu,
- Apanga àti bbl.
Ìpínsísọ̀rí Kàbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n pín kàbà sí ọ̀nà mẹ́ta tí àwọn ìdílé tó wà níbiẹ̀ jẹ́ mẹ́rìnlá, àwọn ni:
- Kabba – ìdílé mẹ́fà.
- Katu – ìdílé mẹ́ta
- Odolu – ìdílé márùn ún.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Distance Kabba – Abuja". cutway.net. Cutway.
- ↑ "Distance Kabba – Lagos". cutway.net. Cutway.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedEB1911
- ↑ "Ooni of Ife to Grace 2018 Kabba Day, Congratulates New Obaro". Kogi Reports. October 25, 2018.
- ↑ Reporter (November 4, 2017). "Kabba day 2017 records landmark success". City People Magazine. Retrieved 2021-01-15.