Jump to content

Thomas Babington Macaulay

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Thomas Babington Macaulay
Ọjọ́ìbí(1826-01-17)17 Oṣù Kínní 1826
Kissy, Sierra Leone
Aláìsí17 January 1878(1878-01-17) (ọmọ ọdún 52)
Lagos, Lagos Colony
Resting placeAjele Cemetery
Gbajúmọ̀ fúnfounder of first secondary school in Nigeria
Olólùfẹ́
Abigail Crowther (m. 1854)
Àwọn ọmọHerbert Macaulay
Parents
  • Ojo-Oriare (father)
  • Kilangbe (mother)
Àwọn olùbátanOliver Ogedengbe Macaulay (grandson)
Samuel Ajayi Crowther (father-in-law)

Thomas Babington Macaulay (ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kejìlá 1826[1] – ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù Kejìlá 1878[2]) jẹ́ alùfáà àti olùkọ́ ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ olùkọ́ àgbà àkọ́kọ́ àti olùdásílẹ̀ CMS Grammar School ní ìpínlẹ̀ Èkó, àti baba olóòtú ìlú Nàìjíríà, Herbert Macaulay.[3]

Wọ́n bí Thomas Babington Macaulay ní Kissy, Sierra Leone, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kínní ọdún 1826 sí àwọn òbí Yorùbá, tí àwọn ológun West Africa Squadron ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbà nínú ìsàkọ́lé ẹrú Trans Atlantic. Bàbá rẹ̀ jẹ́ Ojo-Oriare láti Ikirun ní agbègbè Ilẹ̀ Òyọ́ àtijọ́ (tí ó jẹ́ Ìpínlẹ̀ Òṣun ní ìsinsìnyí), ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Kilangbe láti Ile-Ogbo, èyí tí ó tún wà nínú Ilẹ̀ Òyọ́. Macaulay kẹ́kọ̀ ní CMS Training Institute, Islington, àti King's College ní ilú London.[4][5] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí kékeré tí ó bá Bishop Samuel Ajayi Crowther ṣiṣẹ́, ẹni tí ó fẹ́ ọmọbìnrin kejì rẹ̀, Abigail, ní ọdún 1854.[2]

Macaulay kú ní ọjọ́ ìbí rẹ̀ (ọjọ kẹtàdínlógún Oṣù Kínní 1878) ní Èkó[2] nítorí àrùn "Chicken-pox". Wọ́n sin ín ní ìtẹ́ Ajele.

Babington Macaulay Junior Seminary, ilé ẹ̀kọ́ àtìlẹ́yìn tí ó jẹ́ fún àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ní Ikoroduìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n sọ lorúkọ́ rẹ.[6]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Elebute, Adeyemo (2013). The Life of James Pinson Labulo Davies: A Colossus of Victorian Lagos. Kachifo Limited/Prestige. p. 1. ISBN 9789785205763. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Macaulay, Thomas Babington 1826 to 1878 Anglican Nigeria". Dictionary of African Christian Biography. Archived from the original on 19 August 2014. Retrieved 23 January 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Jacob Oluwatayo Adeuyan (2011). Journey of the First Black Bishop: Bishop Samuel Ajayi Crowther 1806 - 1891. AuthorHouse. ISBN 978-1-463-4073-22. https://books.google.com/books?id=SE6RS010iQgC&pg=PA310. 
  4. E. O. Olúkọ̀jú (2001). A golden heritage: essays in celebration of Saint Andrew's College, Ọyọ. Heinemann Educational Books (Nigeria) Plc. p. 50. ISBN 9789781294273. https://books.google.com/books?id=14gmAQAAIAAJ. 
  5. Georgia State University. Dept. of African-American Studies (1970). Drum: A Magazine of Africa for Africa. African Drum Publications. https://books.google.com/books?id=T3w6AQAAIAAJ. 
  6. "About – Diocese Of Lagos" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 13 February 2020. Retrieved 8 February 2021.