Ìpínlẹ̀ Akwa Íbọm

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
onijo Akwa ibom
Imura Ak


Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè ẹkù-ìjọba Gúúsù-Gúúsù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà ní ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Cross River State, ní ìwọ̀-oòrùnon ìpínlẹ̀ Rivers àti Ìpínlẹ̀ Abia, àti ní gúúsù pẹ̀lú Òkun Atlantic. Ìpínlẹ̀náà mú orúkọ rẹ̀ látara orúkọ odò Qua Iboe tí ó pín Ìpínlẹ̀ náà sí ọgbọọgba kí ó tó sàn wọ inú Bight ti Bonny.[1] Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom yapa wá látara Ìpínlẹ̀ Cross River nínú ọdún 1987 pẹ̀lú olú-ìlú rẹ̀ Uyo pẹ̀lú àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom jẹ́ ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀karùndínlógún ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù márùn-ún-àbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[2]

Meridien Akwa Ibom golf course

Ayé òde-òní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ní olùgbé láti bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn tí ó kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ àbátan Ibibio, Anaang, àti Obolo - Oron àwọn ènìyàn ní àríwá-ìlà-oòrùn, àríwá-ìwọ̀-oòrùn, àti agbègbè gúúsù Ìpínlẹ̀ náà, lẹ́sẹsẹ. Ní àkókò ìmúnisìn, Ohun tí a wá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ Akwa Ibom báyìí pín sí oríṣiríṣi ìlú-ìpínlẹ̀ bíi Ibom Kingdom àti Akwa Akpa kí ó tó padà di Ìpínlẹ̀ lẹ́bẹ́ àbò ìjọba aláwọ̀-funfun ní 1884 gẹ́gẹ́ bí apákan Oil Rivers Protectorate.[3]


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Onyeakagbu, Adaobi (5 October 2021). "See how all the 36 Nigerian states got their names". Pulse.ng. Retrieved 22 December 2021. 
  2. "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Retrieved 14 December 2021. 
  3. Àdàkọ:Cite EB1911