Jump to content

Gaàrí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Garri flour
Cooked garri (eba) on a plate in Cameroon
Whole cassava tubers
Peeled cassava pieces

Ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, gaàrí (tí a tún mọ̀ sí gari, galli, tàbí gali) /{{{1}}}/ ó jẹ́ ìyẹ̀fun tí a rí láti ara ẹ̀gẹ́.

Nínú èdè Hausa, gaàrí túmọ̀ sí ìyẹ̀fun ti guinea corn, àgbàdo, ìrẹsì, iṣu, ọ̀gẹ̀dẹ̀, àti jéró. Fún àpẹẹrẹ, garin dawa jẹ́ èyí tí a rí láti ara guinea corn, garin masara àti garin alkama jẹ́ èyí tí a rí láti àgbàdo àti wíìtì bákan náà, nígbà tí garin magani jẹ́ irinṣẹ́ ìyẹ̀fun.

A máa ń pò ó papọ̀ mọ́ omi tútù àti omi gbígbóná ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Áfíríkà bíi: Nàìjíríà, Benin, Togo, Ghana, Guinea, Cameroon àti Liberia.

Ẹ̀gẹ́, èyí tí ó jẹ́ egbò tí a ti rí gaárí, ó kún fún àwọn èròjà tí ó pọ̀.[1]

Gaàrí tún fara jọ farofa tí orílẹ̀-èdè Brazil, tí wọ́n máa ń lò láti pèsè àwọn onírúurú oúnjẹ, pàápàá jùlọ ní Ìpínlẹ̀ Bahia.

Bí a ṣe ń ṣe é

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Process of garri making

Láti ṣe ìyẹ̀fun gaàrí, a máa wú ẹ̀gẹ́, bẹ ẹ́, lẹ́yìn náà ni a máa fọ̀ ọ́ tónítóní kí á tó gún un. A le fi òróró sí i kí a tó dà á sínú àpò, lẹ́yìn náà ni a máa gbé e sí abẹ̀ ẹ̀rọ tí a fi máa fún un fún wákàtí kan sí wákàtí mẹ́rìnlélógún láti fún àwọn omi tí ó wà lára rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó bá gbẹ tán ni a máa yan án nínú agbada ńlá, a le fi òróró sí i tàbí kí a má fi sí i. Lẹ́yìn èyí ni ó máa fún wa ní Gaàrí, a le rọ́ pamọ́ fún ọjọ́ pípẹ́. A le gún un lódó tàbí kí á lọ̀ ọ́ lẹ́rọ láti fún wa ní ìyẹ̀fun.[2] Gaàrí pín sí oríṣiríṣi, lébú, èyí tí kò kúná àti èyí tí kò kùnà púpọ̀, èyí tí a le lò láti ṣe onírúurú oúnjẹ.

Àwọn oúnjẹ tí a le rí láti ara Gaàrí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀bà ó jẹ́ oúnjẹ tí a pèsè láti ara Gaàrí pẹ̀lú omi gbígbóná tí a sì fi orógùn rò ó títí tí ó fi máa dì papọ̀. A máa ń jẹ ẹ pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi ọbẹ̀, lára àwọn ọbẹ̀ tí a fi le jẹ ẹ̀bà ni: ilá, ẹ̀gúsí, Ẹ̀fọ́ rírò, Afanga, Banga, Ewúro, Ewébú, Gbẹ̀gìrì, abbl.

Eba and egusi soup

Kókóró jẹ́ oúnjẹ kan tí a fi máa ń panu, èyí tí a sáábà máa ń rí ní gúúsù ìlà-oòrùn àti ẹkùn gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní àwọn Ìpínlẹ̀ bíi: Abia, Rivers, Anambra, Enugu àti ìpínlẹ̀ Imo. Èyí tí a ṣe láti ara ìyẹ̀fun àgbàdo tí a dà papọ̀ mọ́ gaàrí àti ṣúgà tí awá dín in.

Gaàrí, gẹ́gẹ́ bí ìpanu tàbí oúnjẹ àsáréjẹ; a le rẹ ẹ́ sínú omi tútù (èyí tí a máa jẹ́ kí ó silẹ̀) pẹ̀lú ṣúgà tàbí oyin àti ẹ̀pà yíyan, nígbà mìíràn a le fi mílìkì mu un, bẹ́ẹ̀ ni a le lo àwọn onírúurú èròjà láti mu gaàrí.

Ní orílẹ̀-èdè Liberia, a máa ń lo gaàrí fún kanyan èyí tí wọ́n máa ń lò pẹ̀lú ẹ̀pà àti oyin.

Dry garri flour

A máa ń lo gaàrí gbígbẹ pẹ̀lú ẹ̀wà ṣíṣè àti òróró. Oúnjẹ tí a dàpọ̀ ni wọ́n máa ń pè ní is yoo ke garri, tàbí garri-fɔtɔ/galli-fɔtɔ nínú èdè àwọn Ga ní orílẹ̀-èdè Ghana ati Gen tí ó jẹ́ ẹ̀ka èdè àwọn tí wọ́n wà ní ẹkùn àríwá orílẹ̀-èdè Togo àti Benin. Irúfẹ́ gaàrí yìí jẹ́ èyí tí a pò papọ̀ mọ́ tòmátò, òróró, iyọ̀, àti àwọn ohun èlò ìṣebẹ̀, wọ́n sáábà máa ń jẹ ẹ́ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ọ̀sán.[2] Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń fi jẹ àkàrà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gaàrí tí ó kúná (ni a tún mọ̀ sí lẹ́bú láàrin àwọn Yoruba) a máa ń yí i papọ̀ mọ́ ata àti àwọn ohun ìṣebẹ̀ mìíràn. A máa fi omi tí ó lọ́wọ́ọ́rọ́ díẹ̀ pẹ̀lú òróró sí i lẹ́yìn náà ni a máa fi ọwọ́ rò ó papọ̀. Irúfẹ́ Gaàrí yìí jẹ́ èyí tí a máa ń fi ẹja jẹ.

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ẹ̀yà Efik máa ń lo po gaàrí mó àwọn ọbẹ̀ bíi; ọbẹ̀ ẹyin àti ọbẹ̀ funfun (tí wọ́n tún ń pè ní ọbẹ̀ òkè àti ilẹ̀) láti jẹ́ kí wọn ó ki.

Ní ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, oríṣi gaari méjì ni ó wà, àwọn náà ni gaàrí funfun yẹ́lò. Gaàrí yẹ́lò jẹ́ èyí tí wọ́n fi epo pupa sí nígbà tí wọ́n bá ń yan án. [3]

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Cameroon ni a ti le rí Gaàrí funfun àti yẹ́lò. Irúfẹ́ Gaàrí funfun kan ni wọ́n ń pè ní Gaàrí-Ìjẹ̀bú. Èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ilẹ̀ Yorùbá lọ́dọ̀ àwọn ará Ìjẹ̀bú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní orílẹ̀-èdè Ghana, gaàrí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń pín sí ìsọ̀rí pẹ̀lú bí wọ́n bá ṣe dùn/kan sí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe pọ̀ sí.

Àwọn tó bá fẹ́ ra gaari máa ń ra èyí tí ó bá kan dáadáa tí ojú rẹ̀ sì rẹwà.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Nwosu, Martin (2023-08-23). "10 Amazing Health Benefits of Garri". Nccmed (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-08-23. Retrieved 2023-08-23. 
  2. 2.0 2.1 "Garri". African Foods. Retrieved August 6, 2015. 
  3. "Garri: A Guide to West Africa's Staple Food". The Wisebaker. 16 September 2020. Retrieved 2021-06-13. 


Àdàkọ:African cuisine