Immanuel Kant

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Immanuel Kant
Immanuel Kant
OrúkọImmanuel Kant
Ìbí22 Oṣù Kẹrin 1724
Königsberg, Prussia
Aláìsí12 February 1804(1804-02-12) (ọmọ ọdún 79)
Königsberg, Prussia
ÌgbàÌmòye ọ̀rúndún 18th
AgbègbèÌmòye Apáìwọòrùn
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́Isekantiani, imoye olaju
Ìjẹlógún ganganOro-ijinle, Oro=adanida, Iwawiwu, Ogbon
Àròwá pàtàkìCategorical imperative, Transcendental Idealism, Synthetic a priori, Noumenon, Sapere aude, Nebular hypothesis
Ìtọwọ́bọ̀wé

Immanuel Kant (Pípè nì Jẹ́mánì: [ɪˈmaːnu̯eːl ˈkant]) (22 April 1724 – 12 February 1804) je amoye ara Jemani ti orundun 18th lati ilu Königsberg ni Prussia. Kant lo je amoye gbeyin tonipa ni Europe odeoni ninu afinuro imo nigba Olaju to bere pelu awon alayan bi John Locke, George Berkeley, ati David Hume.[1]

Kant seda ona igbewo tuntun ninu imoye to ni ipa kakiri lori imoye kakiri orundun 21st. O satejade awon ise pataki lori oro-ijinle, lori esin, ofin, ati itan. Ikan ninu iwe re pataki ni Agbeyewo Ironu Sasa, to je iwadi lori opin ati opo ironu fun ra re gan. O gbogun ti awon iru oro-adanida ati oro-ijinle to wa tele, o si falasi afikun Kant gan si awon eyi. Awon ise miran to tun se bi agbalagba ni Agbeyewo Ironu Alagbese, to dawo lori iwawiwu, ati Agbeyewo Idajo, to sewadi which investigates oro-ewa ati iwadopin.

Kant damoran pe oro-adanida se tunse pelu oro-ijinle.[2] O so pe nipa liloye awon orisun ati awon opin imo omo-eniyan a le bere awon ibere oloro-ijinle ti yio ni eso. O bere boya ohun kan le je mimo pe o ni awon ini pato kan ki o to di pe iriri ohun na waye. O pinu pe gbogbo awon ohun ti emi le ro nipa won gbodo je bi iru ero re. Nipa bayi ti emi ba le ro lasan nikan bi titori (causality) – ti Kant gba pe o je be – nigbana a le mo won ki a to ni iriri won pe gbogbo awon ohun ti a ni iriri won gbodo je itori tabi ìṣẹlẹ̀. Sibe, o je bayi pe o se e se pe awon ohun kan wa ti eda won ko se fi emi ro, nitorie opo titori, fun apere ko se mulo laisi iriri: o je be pe a ko le mo, fun apere, boya ile-aye ti wa lailai tabi boya ohun kan lo fa wa. Bi be awon ibere ninla oro-ijinle alafinuro ko l ni idahun pelu emi omo-eniyan, sugbon sayensi fidimule sansan ninu awon ofin emi.[3] Iwadi lri idimule ati idagba opolo ninu awon eranko satileyin ironusi Kant, botileje fun ifuramo aaye; eyun, isoju aaye ayika lamupo ohun kan to siwaju ifuramo gangan ayika na fun ra re.[4][5][6]

Kant gbagbo pe ohun unda ilaja laarin awon oluseiriri ati awon oluselaakaye. Awon oluseiriri gbagbo pe imo unwa latinu iriri nikan, sugbon awon oluselaakaye tenumo pe imo le bo si abe iyemeji Kartesi ati pe ironu nikan lo le fun wa ni imo. Sugbon ijiyan Kant nipe, lilo ironu lai mulo mo iriri yio fa itanraenije wa, nigba ti iriri yio je tonitoun ti a ko ba koko fi ironu saka wo.

Ero Kant nipa ni Jermani igba aye re, nipa mimu imoye losiwaju ijiyan larin awon oluselaakaye ati oluseiriri. Awon amoye Fichte, Schelling, Hegel ati Schopenhauer ri ara won bi eni to satunse ati samufe sistemu Kantiani, bi be won samuwa orisi iru Isearowa ti Jermani. Titi doni Kant unnipa pataki lori imoye, nipa ipa re lori imoye alatuwo ati imoye orile Europe.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Crane Brinton. "Enlightenment". Encyclopedia of Philosophy. Vol. 2, p. 519. Macmillan, 1967.
  2. Kitcher., Patricia (intro.); W. Pluhar (trans.), I. Kant (author) (1996). Critique of Pure Reason. Indianapolis: Hackett. xxviii. 
  3. Baird, Forrest E.; Walter Kaufmann (2008). From Plato to Derrida. Upper Saddle River, New Jersey: Pearson Prentice Hall. ISBN 0-13-158591-6. 
  4. Linda Palmer and Gary Lynch (18 June 2010). "A Kantian View of Space". Science 328: 1487. 
  5. Rom J. Wills et al. (18 June 2010). "Development of Hippocampal Cognitive Map in Preweanling Rats". Science 328: 1573. 
  6. Rosamund F. Langston et al. (18 June 2010). "Development of the Spatial Representation System in the Rat". Science 328: 1576.