Jump to content

Karl Marx

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Karl Heinrich Marx
OrúkọKarl Heinrich Marx
ÌbíMay 5th, 1818
Trier, Prussia
AláìsíOṣù Kẹta 14, 1883 (ọmọ ọdún 64)
London, United Kingdom
Ìgbà19th-century philosophy
AgbègbèÌmọ̀òye Apáìwọ̀òrùn
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́Young Hegelian, Hegelianism, Marxism, socialism
Ìjẹlógún ganganPolitics, Economics, Philosophy, Sociology, class struggle, History,
Àròwá pàtàkìCo-founder of Marxism (with Engels), the Theory of Surplus Value, alienation and exploitation of the worker, The Communist Manifesto, Das Kapital, Materialist conception of history
Ìtọwọ́bọ̀wé

Karl Heinrich Marx (May 5, 1818 – March 14, 1883) je ara Jemani[1] amoye, aseoro-okowo oloselu, akoitan, aserojinle oloselu, aseoro-awujo, ati asekomunisti alajidide, ti awon irookan re ko ipa pataki ninu idagbasoke isekomunisti ati isesosialisti odeoni. Marx se soki ohun to unso niu ila akoko ori kinni iwe re Manifesto Komunisti, to je gbigbejade ni 1848: "Itan gbogbo awujo titi doni je itan awon ijakadi ipo." Marx jiyan pe isekapitalisti, gege bi awon sistemu awujo-oro-okowo tele, n a yio se isoro ninu re ti yio mu iparun ara re wa.[2]

Soṣiọlọ́jì Lítíréṣọ̀ tó tẹ̀lé Èrò Karl Marx Ojú-Ìwé 36-39.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tíọ́rì soṣiọ́lọ́jì tó tẹ̀lé ìlànà àti èrò Karl Marx kì I ṣe tíọ́rì oni, ó ti pẹ́ ti ó tí dáyé. Oludasilẹ tíọ́rì yìí ni Karl Marx. Orúkọ rẹ̀ ní àwọn abẹnugan tíọ́rì náà fí ń pe ìlànà wọn. Láti nǹkan bí ọdún 1840 ni Karl Marx fúnra rẹ̀ ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí awujọ ati àṣà, ṣùgbọ́n ní nǹkan bí Sẹ́ńtúrì ogún ni tíọ́rì náà búrẹ́kẹ láwùjọ àwọn akadá.


Tíọ́rì ìṣègbèfábo Ojú-Ìwé 40-52.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tíọ́rì ti a pè ni ìṣègbèfábo lédè Yorùbá ni èdè Gẹ̀ẹ́sì pè ni “Feminism”. Láti inú èdè Látìnì ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ya ọ̀rọ̀ náà lò èyíni “Femina”- ó túmọ̀ sí ohun gbogbo tó jẹ mọ́ abo tàbí àwọn obìnrin. Ògíní (1996:11) sọ pé ọ̀nà méjì ni àlàyé lórí tíọ́rì yìí lè pín sí.

Tíọ́rì Aṣàtakò Ìmúnisìn Ojú-Ìwé 53-57.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tíọ́rì Aṣàtakò imúnisìn jẹ́ tíọ́rì lítíréṣọ̀ àkọ́kọ́ tó kanlẹ̀ wa fún lámèyító lítíréṣọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ti fojú gbooru iná ìjọba amúnisìn tẹ́lẹ̀. Yorùbá bọ̀, wọn ni, abini tún bini, àbèrè tun bèèrè ni kì í jẹ́ ká a pe àbúrò ẹni lọ́mọ ẹni, gbogbo àwọn tíọ́rì lítéṣọ̀ tí a ti tọ́ka sí tàbí ṣe àlàyé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí ifojuààtò-wò, ìfojú-ìhun-wò títí ó fi de tíọ́rì Makisiisi kò kanlẹ̀ wà fún lámèyítọ́ lítíréṣọ̀ àwọn adúláwọ̀ tàbí àwọn orílẹ̀ èdè ti kì í ṣe ara Yúróòpù àwọn onímọ̀ kan wulẹ̀ n ra tíọ́rì náà bọ lítíréṣọ̀ adúláwọ̀ lọ́rùn lasan ni.

Ìṣàmúlò Tíọ́rì lítíréṣọ̀ Mélòó kan Ojú-Ìwé 58-104.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣíṣe àmúlò tíọ́rì fún lámèyítọ́ iṣẹ́ ọnà alàwòmọ́ lítíréṣọ̀ ṣe pàtakì lóde òní. Lámèyítọ́ tí kò bá lo tíọ́rì kan pàtó fún iṣẹ́ rẹ̀ kò ní ìpìlẹ̀ tó dúró lé. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kò sí ni wọ àjọ àwọn onímọ̀ lámèyítọ́, ko sí ibi ti a kò tí lè lo tíọ́rì fún àlàyé tàbí ìgbélé-wọ́n iṣẹ́, ewì, eré-oníse tàbí eré-onítàn ìtàn àròsọ tí o fí kan eré inú fíìmù àgbéléwò tàbí alágbèéká.

Tíọ́rì Ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wò Ojú-Ìwé 25-26.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí sọ pé iṣẹ́ tí lítéṣọ̀ máa ń ṣe ni láti dáàbò bo àṣà àti iṣẹse àwùjọ kan, nítorí náà ohun tó gbọdọ̀ jẹ lámèyítọ́ lógún ni ṣíṣe àfihàn irú àwọn àṣà tó ṣúyọ nínú iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀. Ọjọ̀gbọ́n Wándé Abímbọ́lá sọ pé:

Therefore, in order to envolve an acceptable format for the appreciation of oral literature, we must blend our knowledge of the most up-to-date tecxxhniques of literary criticism and stylistics with a thorough understanding of Yoruba culture. Without this, any critical work is bound to be sterile.

(Kí a tó lè ri ìlànà lámèyítọ́ lítíréṣọ̀ ti yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, a niláti jẹ́ ki irú ìlànà bẹ́ẹ̀, bí o ti wù ki ó jẹ́ ti òde òní tó, ni ọwọ́ àṣà Yorùbá nínú, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ òfégè lásán ni iṣẹ́ lámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ (1982:78)

Tíọ́rì Ìfojú-ìtàn-ìgbesi-ayé òǹkọ̀wé-wò Ojú-Ìwé 27-28.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tíọ́rì mìíràn tí ó tún ṣe pàtàkì ni tíọ́rì tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé òǹkọ̀wé. Ohun tí tíọ́rì yìí sọ nip é láti ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọnà kan, ó ṣe pàtàkì láti mọ irú ẹni tí ó ṣe náà, ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ àti àwọn ǹkan mìíràn tó kó ipa pàtàkì kí ẹni náà tó dáwọ́ lé iṣẹ́ náà àti ohun tí ó mú kí ó gbé iṣẹ́ náà gba ìlànà tí ó gbé e gbà.

Tíọ́rì Ìfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ-wo-lítíréṣọ̀ tàbí soṣiọlọji lítẹ́ṣọ̀ Ojú-Ìwé 29-35.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rọ̀ tí a pè ní Soṣiọ́lọ́jì lítíṛọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí onímọ̀ èrò ìjìnlẹ̀ kan ti à ń pè ní Taine ọmọ orílẹ̀ èdè Faranse rọ fúnra rẹ̀. Oníṣẹ́ lámèyítọ́ ni Taine láàárín ọdún 1828-1893. Ète láti sọ àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ọnà dàbí ti ìmọ̀ sáyẹ́nsì ló fa ìṣẹ̀dá Soṣiọ́lọ́jì lítíréṣọ̀. Ìmọ̀ tuntun sì ló jẹ́ lágbooloé ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ọnà.

iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Lérè Adéyẹmí (2006) Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ Ní Èdè Yorùbá Sgevuituni Shebiotimo Publications, Ijebu-Ode, Nigeria; ISBN 978-2530-78-6.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Karl Marx". Karl Marx. Microsoft Corporation. 1993–2008. http://encarta.msn.com/encyclopedia_761555305/karl_marx.html. Retrieved 2008-12-02. "German political philosopher ...".  Archived 2008-07-24 at the Wayback Machine. Marx's political philosophy developed from Western philosophical tradition, especially under the influence of Hegel; and Marx grew up in a Germanophone cultural milieu. In terms of citizenship, his birth in Trier made Marx a subject of the Kingdom of Prussia; in December 1845 he renounced his Prussian citizenship and thereafter became a stateless exile from his native Rhineland.
  2. Baird, Forrest E.; Walter Kaufmann (2008). From Plato to Derrida. Upper Saddle River, New Jersey: Pearson Prentice Hall. ISBN 0-13-158591-6.