Jump to content

Juan Martín del Potro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Juan Martín del Potro
Orílẹ̀-èdè Argentina
IbùgbéTandil, Argentina
Ọjọ́ìbí23 Oṣù Kẹ̀sán 1988 (1988-09-23) (ọmọ ọdún 36)
Tandil, Argentina
Ìga1.98 m (6 ft 6 in)
Ìgbà tódi oníwọ̀fà2005
Ọwọ́ ìgbáyòRight-handed (two-handed backhand)
Olùkọ́niSebastián Prieto
Ẹ̀bùn owóUS$ 25,889,586 [1]
Ẹnìkan
Iye ìdíje439–173 (71.73% in ATP Tour and Grand Slam main draw matches, and in Davis Cup)
Iye ife-ẹ̀yẹ22
Ipò rẹ̀ gígajùlọNo. 3 (13 August 2018)
Ipò rẹ̀ lọ́wọ́No. 120 (6 January 2020)[2]
Grand Slam Singles results
Open AustrálíàQF (2009, 2012)
Open FránsìSF (2009, 2018)
WimbledonSF (2013)
Open Amẹ́ríkàW (2009)
Àwọn ìdíje míràn
Ìdíje ATPF (2009)
Ìdíje ÒlímpíkìF (2016)
Ẹniméjì
Iye ìdíje41–44 (48.24% in ATP Tour and Grand Slam main draw matches, and in Davis Cup)
Iye ife-ẹ̀yẹ1
Ipò rẹ̀ gígajùlọNo. 105 (25 May 2009)
Ipò rẹ̀ lọ́wọ́No. 443 (13 January 2020)
Grand Slam Doubles results
Open Fránsì1R (2006, 2007)
Wimbledon1R (2007, 2008)
Àwọn Ìdíje Ẹgbẹ́ Agbáyò
Davis CupW (2016)
Last updated on: Àdàkọ:Date.

Juan Martín del Potro Lucas (Pípè: [xwan maɾˈtin del ˈpotɾo])[3] (ọjọ́ìbí 23 September 1988), tàbí Delpo (IPA: [ˈdelpo]), jẹ́ agbá tẹ́nìs ará Argentina tó wà ní ipò No. 122 lágbàyé ní tẹ́nìs àwọn ọkùnrin ẹnìkan Association of Tennis Professionals (ATP).[4][5]

Àṣeyọrí rẹ̀ tó tọ́bi jùlọ ṣẹlẹ̀ nígbà tó gba ife-ẹ̀yẹ Open Amẹ́ríkà 2009 nígbà tó borí Rafael Nadal ní semifinal àti Roger Federer ní final. Òhun ni ẹni àkọ́kọ́ tó borí Federer àti Nadal nínú ìdíje grand slam kannáà àti ẹnìkan soso lẹ́yìn àwọn tí a mọ̀ sí Big Four (Roger Federer, Rafael Nadal, Novak Djokovic àti Andy Murray), tọ́ gba ife-ẹ̀yẹ grand slam láàrin Open Fránsì 2005 àti Open Amẹ́ríkà 2013. Òhun náà tún ni ará Argentina kejì tó gba ife-ẹ̀yẹ Open Amẹ́ríkà nígbà Open Era.[6]