Jump to content

Èrúwà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Èrúwà

Ojoko
Ìlú
Ìtàn ṣókí nípa Èrúwà ní èdè Èrúwà Ìbàràpá láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Èrúwà.
Nickname(s): 
Omo Agbe dudu
Motto(s): 
Ojoko A gbe wa o
Èrúwà is located in Nigeria
Èrúwà
Èrúwà
Location in Nigeria
Coordinates: 7°32′59″N 3°27′0″E / 7.54972°N 3.45000°E / 7.54972; 3.45000Coordinates: 7°32′59″N 3°27′0″E / 7.54972°N 3.45000°E / 7.54972; 3.45000
Country Nàìjíríà
Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Founded byObaseeku
Government
 • ElérúwàVacant
Population
 • Religions
Christianity, Islam, Yoruba religion
Time zoneUTC+1 (WAT)
ClimateAw
Websitehttp://www.oyostate.gov.ng/

Èrúwà tàbí (Èrú wà níbí o) ni ó túmọ̀ sí wípé ẹ̀rún iṣu wà ní ibí, jẹ́ olú ìlú fún agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ìlà Oòrùn ÌbàràpáÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Èrúwà sí ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn tó kìlómítà ọgbọ́ta 60 km nígbà tí ó tó kìlómítà 72 km sí ìlú ÌbàdànÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́[1]

Ìlú Èrúwà rí orúkọ rẹ̀ láti ara bí àwọn ọláọ́jà ṣe ń ìpolówó iṣu sísè fún àwọn àrìnrì-àjòapá òkè ọya tí wọ́n bá ń kọjá ní ìgboro ìlú náà nígbà ìwáṣẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń polowó náà ni Èrú wà níbí oooo! . Àwọn agboolé mẹ́rin bíí: An ko, Ìwà bá, Òkè Ọba, àti Abọ́rẹ́rìn tí wọ́n wà ní inú Èrúwà nígbà náà ni wọ́n tẹ̀dó sí orí òkè Ilewu, tí Òkè náà sì ma ń ṣíji bo wọ́n ní àsìkò ogun pàá pàá jùlọ bí ogun ṣe pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ní nkan bí (1830 sí 1890). Àwọn tí.wọ́n ta.Èrúwà do ni wọ́n ṣẹ̀ wá láti ìlú Ọ̀yọ́. Ẹni tí.ó jẹ́ adarí wọn nígbà náà ni a mọ̀ sí Ọba Sẹ̀ẹ́kú tí ó jẹ́ Arẹ̀mọ, jagun-jagun àti Oníṣègùn. Ọba Sẹ̀ẹ́kú fẹ́ aya rẹ̀ Oyinlọlá tí ó jẹ́ ọmọ Ọba láti ìlú Ọ̀yọ́, tí ó sì bí mọ ọkùnrin méjì. Ọmọ ọkùnrin akọ́kọ́ ni wọ́n sọ ní Àkàlàkòyí nígbà tí ìkejì ń jẹ́ Ọláríbikúsí ìdílé awọn méjèèjí yí ni ó di Èrúwà lóní. Àwọn òrìṣà oríṣiríṣi ni wọ́n ma ń bọ́ ní Èrúwa, lára wọn ni òrìṣà Orò, Ṣàngó, Egúngún, Orisa oko, Osanyin, Yemọja ati Ifá. Ilé akọ́kọ́ tí wọ́n fi páànù bò ní Èrúwà ni wọ́n kọ́ ní ọdún 1908, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ń fi páanù kọ́lé lẹ́yìn tí iná jo púpọ̀ nínú àwọn ilé ikí tí àwọn ti kọ́ ní ọdún 1922. Ọba Elérúwà ni ó jẹ́ alákòóso àti aláṣẹ fún gbogbo Èrúwà, àmọ́ àwọn Bàálẹ̀ ń ràn ọ́lọ́wọ́ lórí ìṣàkóso ìlú náà. Gómìnà tẹ́lẹ̀ tí ó ṣàkóso Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níọdún 1977 tí ó jẹ́ lásìkò ológun ìyẹn Jemibibeon ni ó to Elerúwa sí ipò Karùn-ún nínú ipò àwọn lọ́ba lọ́ba gẹ́gẹ́ ó ti wà nínú ètò Ìjọba Ìpínlẹ̀. Oríṣiríṣi nkan ni ìlú Èrúwà fi pegedé, lára rẹ̀ ni wípé ibẹ̀ ni ìṣàkóso g ogbo ilẹ̀ Ìbàralá méjèèje wà. Èrúwà yí kan náà ni Aláàfin Ọ̀yọ́ gbà wípé oun ni aṣojú gbogbo ìẹ̀ Ìbaràpaá pátá ní àsìkò ìmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ìbàràpá méjèèje náà: IgbóỌrà, Ìgàngàn, Ayétẹ̀, Lànlátẹ̀, Ìdèrè, Tápà, àti Èrúwà fúnra rẹ̀. Èrúwà yí kan náà ni wọ́n gbé ilé ìṣeẹ́ ìṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ìbàrapá sí ní àsìkò awọ Èèbó àmúnisìn ní ọdún 1915, tí wọ́n sì tún kọ́bilé-ẹjọ́ akọ́kọ́ síbẹ̀ nígbà náà ní ọdún tí ó tẹ̀le. [2] [3] [4]


Àwọn olùgbé ibẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iye àwọn tí wón wà ní ìlú Èrúwà ní ọdún 1934 lápapọ̀ jẹ́ 9,110. Nígbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríàyóò fi ṣe ètò ìkànìyàn akọ́kọ́ ní ọdún 1951, iye àwọn olùgbé ibẹ̀ ti tó 11,000. Nígbà tí ó di ọdún 1963 ti ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tún ṣe ètò ìkànìyàn míràn, iye àwọn olùgbé ibẹ̀ ti wọ 26,963. Ní ọdún 2006, wọ́n ti tó 118,288.[5]

Ètò Ẹ̀sìn wọn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Papọ̀ nínú àwọn ènìyàn Èrúwàw ni wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tàbí ọmọ lẹ́yìn Jésù, ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni ó ṣìkejì tí ó gbajúmọ̀ láàrín wọn, ba kan náà ni àwọn ẹlẹ́sìn abáláyé náà ń ṣe tiwọn ní mẹ̀lọ mẹ̀lọ. Gbogbo wọn sì ń gbà pọ̀ láì sí ìyọnu bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ nílé, lẹ́nu ìṣeẹ́ àti nílé ẹ̀kọ́ pẹ̀lú

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "About: Eruwa". DBpedia Association. 1999-02-22. Retrieved 2021-07-01. 
  2. J.A. Adewoyin (1993). History of Eruwa. ISBN 9789783209619. https://books.google.com/books?id=e4YuAQAAIAAJ. 
  3. Rev. Samuel Johnson (1921). History of Eruwa. ISBN 9789783209619. https://books.google.com/books?id=e4YuAQAAIAAJ. 
  4. Childs, E. (1934). Intelligence Report on the Western District of Ibadan Division of Oyo Province. 
  5. "Detailed Information of the 33 Local Governments in Brief :: The Official Website of the Oyo State Government | The Pacesetter State". www.oyostate.gov.ng. Archived from the original on 23 May 2016. Retrieved 28 May 2016.