Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìlàòrùn Ibarapa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ibarapa East
Country Nigeria
StateOyo State
Government
 • Local Government Chairman and the Head of the Local Government CouncilOlugbenga Obalowo (PDP)
Time zoneUTC+1 (WAT)

Agbegbe Ijoba Ibile Ilaorun Ibarapa jẹ́ ọ̀kan lára àọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní Nàìjíríà. Àwọn ènìyàn Ìbàràpá ló pọ̀ jù níbẹ̀. Olú-ìlú náà wà ní Eruwa.

Ó ní ìwọ̀n ilẹ̀ tó tó 838 km2 àti iye ènìyàn tó tó 118,226 ní ìka orí tó wáyé ní ọdún 2006.

Kóòdù ìfìwérá́nṣẹ́ ìlú náà ni 201.[1]

Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Agbegbe Ijoba Ibile Ilaorun Ibarapa ní ọdún 1989, pẹ̀lú olú-ìlú rẹ̀ ní Eruwa. Ó ní ìwọ̀n ilẹ̀ tó tó 705.78sq km2   120, 220 ní ìka orí tó wáyé ní ọdún 2006. Agbègbè náà ní àwọn ọmọ Yorùbá nínú àti àwọn ẹ̀yà mìíràn, bíi Fulanis, Igbos, TIVs, Jukuns among others.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n yàn láàyò ní ìlú náà, tí wọ́n sì ń gbin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀gbìn. Àwọn ilé-iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ pọ̀ gan-an ní agbègbè náà, lára wọn ni Nico Oil Palm Plantation, Zartech, Global-West, oko Obasanjo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí èyí, agbègbè yìí ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga méjì, àwọn náà ni Adeseun Ogundoyin Polytechnic, Eruwa àti Oyo State College of Education, Lanlate.

Àwọn ènìyàn ìmíì sì ń ṣe idokowo àti aṣọ híhun.

Lára àwọn ìlú tó wà ní agbègbè náà ni: Eruwa, Lanlate, Okolo, Maya, Temidire, Idi-Ope, Adeagbo, Elere, Onirope, Akete, Obanese, Alapa, Lagaye, Abule Baale, Ijesa, Babamogba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́wọ́wọ́wọ́, agbègbè Ibarapa East ní ẹ̀ka-ìdìbò mẹ́wàá.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 2009-10-07. Retrieved 2009-10-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)