Jump to content

Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Iwajowa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Agbegbe Ijoba Ibile Iwajowa)
Iwajowa
Ijio Hill is located in Ijio Community, Iwajowa LGA of Oyo State, Nigeria.
Ijio Hill is located in Ijio Community, Iwajowa LGA of Oyo State, Nigeria.
Country Nigeria
StateOyo State
Government
 • Local Government Chairman and the Head of the Local Government CouncilOyinloye Jelili Adebare (PDP)
Time zoneUTC+1 (WAT)

Agbègbè Ìjoba Ìbílè Ìwàjowá` jé agbègbè ìjoba ìbílè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. tí ibùjókò rè wà ní Ìwéré-ilé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú Ìwéré jẹ́ ìlú tó lààmì-laaka tí ó wà lábẹ́ àkóso ìlú Ọyọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá láti ayé atijọ́ nípa akínkanjú àti ogun jíjà. Pẹ̀lú bí ìlú Ọ̀yọ́ ṣe jẹ́ ibùjókòó agbára láyé àtijọ́, síbẹ̀ wọn kìí fi ọwọ́ pa idà Ìwéré-ilé lójú, bákan náà ni àwọn Aláàfin kìí ṣígun síbẹ̀. Wọ́n sọ Ìwéré-ilé di ibùjókó ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejìlá ọdún 1996 látàrí bí ọ̀gágun àpàṣẹ wàá Sanni Abacha. Àwọn ìlú míràn tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà ni ìlú Ìgànná, Ilaji-Ile, Idiko-Ile, Ayétòrò Ilé, Itasa, Ìdìko Àgọ́, Ẹlẹ́kọọ̀kan, Ijió, Ayégún Wasimi àti àwọn ìlú,abúlé àti abà òun àrọko tí wọ̀n tó irinwódínláàdọ́ta . Àwọn ònilẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ olùgbé agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ yí ni wọ́n jẹ́ Yorùbá tí wọ́n sì ń gbé nírọ̀rùn pèlú àwọn ẹ̀yà tókù tí wọ́n jẹ́ àjòjì bíi ẹ̀yà Tiv, ẹ̀ya Egede, Hausa àti àwọn Fulani. Púpọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ àjòjì ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ oko dídá bí àwọn onílùú tí àwọn míràn sì ń ṣiṣẹ́ eran sísìn àti ọdẹ ṣíṣe.

Bákan náà ni wọ́n ma ń gbé àṣà àti ìṣe Yorúbá lárugẹ nì agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ yí, lára àwọn ọdún ìbílẹ̀ ni ọdún Orò, ọdún Ògún, ọdún Egúngún, ọdún Gẹ̀lẹ̀dẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Awọn ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]