Ajàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Sierra Leone
Ajàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Sierra Leone |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Arrival date | 31 March 2020 (4 years, 8 months, 2 weeks and 5 days) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 1,843 (as of 02 August) |
Active cases | 401 (as of 02 August) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 1,375 (as of 02 August) |
Iye àwọn aláìsí | 67 (as of 02 August) |
Official website | |
facebook.com/mic.gov.sl |
Ajàkálẹ̀-àrùn COVID-19 tàn kálẹ̀ dé Orílẹ̀-èdè ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone ní ọjọ́ kọkanlélọ́gbòn oṣù kẹta ọdún 2020.[1]
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí On 12 January 2020.[2][3] Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003. Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpò ènìyàn lágbáyé. [4][5][6][4]
Àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan tí ó ń ṣẹlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àdàkọ:COVID-19 pandemic data/Sierra Leone medical cases chart
Oṣù kẹta ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sierra Leone ọ̀gbẹ́ni Julius Maada Bio, kéde ìtánká arùn Kòrónà tí ó wọ orílẹ̀-èdè wọn ní ọjọ́ kọkanlélọ́gbọ̀n oṣù kẹ́ta ọdún 2020 lára arákùnrin kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì tí ó ń darí ìrìn-àjò bọ̀ láti ìlú Faransé ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta ọdún 2020, amọ́ tí wọ́n ti fi sí iyará àdágbé láti ìgbà náà.[7] This single case remained active at the end of the month.[8]
Oṣù kẹrin ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ Kíní oṣù kẹ́rin ọdún 2020, orílẹ̀-èdè Sierra Leone ní akọsílẹ̀ àrùn Kòrónà ìkejì lára 3nìkan tí ó ṣèrín ajò pẹ́lú 3ni akọ́kọ́ tí ó ti kọ́kọ́ ní arùn náà.[9] The government announced a 3-day lockdown starting on 5 April.[10]
Wọ́n tún ní akọsílẹ̀ méjì méjì ní ọjọ́ kẹrin àti ìkarùún oṣù kẹrin, tí ó mú kí iye àwọn aláàrẹ̀ COVID-9 jẹ́ mẹ́fa. [11] Ní ọjọ́ kẹsàán oṣù kẹrin, lẹ́yìn ìsénimọ́lé ọlọjọ́ mẹ́ta, ìjọba kéde àwọn ìgbésẹ̀ míràn. Wọ́n ṣòfin kónílé-ó-gbélé tí àwọn ènìyàn yóò ní ànfaní láti rìn láti agogo mẹ́sàán àrọ̀ sí agogo mẹ́fà ìrọ̀lẹ́, àwọn òsìṣẹ́ ìjọba tí iṣẹ́ wọn ṣe pàtàkì jùlọ ni wọ́n ní ànfaní láti ma jáde. Òfin yí wà bẹ́ẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko. Wíwọ ìbòjú ní àkókò àtànkálẹ̀ àrùn kòrónà di dan dan fún ẹnìkan tí ó bá fẹ́ jáde lọ sí àárín ọ̀pọ̀ èrò.[12]
Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin, ìjọba fi àtẹ̀jáde kan léde tí ó sọ wípé àwọn ènìyàn mẹ́ta lára àwọn mẹ́wá kan tí wọ́n fara kó àrùn COVID-9 ti wà ní iyará àdágbé, tí àwọn mẹ́wéwá sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn ilé ìwòsàn ìjọba. Ìjọba ti kó ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùún mẹ́ta ai àádọ́ta ó lé mẹ́rin, ni wọ́n ti wà ní iyará àdágbé fún ọ̀sẹ̀ méjì, nígbà tí wọ́n ti dá àwọn ọgọ́rùún méje àti mẹ́rìndínlógójì ti pada sí ilé wọn láyọ̀ àti alàáfía. [13]
Ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹrin, wọ́n ní akọsílẹ̀ àwọn ènìyàn mẹ́fà akọ́kọ́ tí wọ́n sí ìwòsàn gbà.
Wọ́n kéde rẹ̀ wípé Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sierra Leone ọ̀gbẹ́ni Julius Maada Bio náà ti wọn iyará àdágbé látàrí bí ó ṣe fara kásá àìsàn àrùn COVID-9 ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2020. [14] Ní ọjọ́ Kẹtalélógún oṣù kẹrin, wọ́n ní akọsílẹ̀ ẹnìkan tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sí ọwọ́ àrùn Kòrónà. Ẹni náà jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin. [15] Ẹnìkejì tí lú ni ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kandínlógóje tí wọ́n sì fìdí àìsàn Kòrónà múlẹ lára wọn lẹ́yin tí wọ́n ti gbé gùru-gaja.
Wọ́n kéde ikú ọkùnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ mẹ́tàdínlógójì tí ó jẹ́ ẹnìkẹta ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù kẹrin ọdún 2020.
Nígbà tí oṣù kẹrin yóò fi tẹnu bepo, àwọn ènìyàn ọgọ́rùún ni wọ́n ti lu gúdẹ àrùn yí nígbà tí àwọn méje gbẹ́mí mì. Àwọn mọ́kanlélógún ni wọ́n rí ìwòsàn gbà tí wọ́n sì padà lọ sílẹ́ wọn, ó wá ku àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́rùún tí wọ́n sì ń bá àìsàn náà jà. [16]
Oṣù Karùún ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjọba ṣòfin kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ mẹ́ta tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta oṣù Karùún. Nígbà tí yóò fi di ọjọ́ yìí, iye àwọn tí wọ́n ti wà ní iyará àdágbé ti tó ẹgbẹ̀rún kan ati ọgọ́rùún mẹ́ta ó lé mọ́kànlélógójì ènìyàn, àwọn mọ́kandínlọ́gbọ̀n ni wọ́n rí ìwòsàn gbà tí wọ́n sì lọ sílé wọn.[17]
Ní inú oṣù Karùún, wọ́n rí akọsílẹ̀ tuntun tí ó tó ogóje ó lé mẹ́tàdínlógójì tí ó mú kí gbogbo akọsílẹ̀ àwọn aláàrẹ̀ àrùn Kòrónà lápapọ̀ jẹ́ 9gọ́jọ àti mọ́kanlé ọgọ́ta. Àwọn tí wọ́n kú jẹ́ mẹ́rìndín láàdọ́ta. Àwọn tí wọ́n gbádùn jẹ́ ọgọ́rùún mẹ́rin àti mẹ́rìndínlọ́góta ní ìparí oṣù Karùún. [18]
Oṣù Kẹfà ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láti ọ́jọ́ kíní oṣù Kẹfà, wọ́n ṣe wí From 1 June, wearing of face masks became compulsory.[19] Also on this day, frontline workers declared a strike because of unpaid salaries.[20] Nígbà tí yóò gi di ọjọ́ kẹrin oṣù Kẹfà, àwọn ènìyàn tí wọ́n tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti àádọ́rin ó lé mẹ́tadínlógún tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ fún tí ọgọ́rin léní mẹ́jìdínláàdóje jẹ́ obìnrin nígbà tí àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé mẹ́rìndíláàdọ́ta jẹ́ ọkùnrin.
Ní ìparí oṣù Kẹfà, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò fún tí ayẹ̀wọ̀ sì fìdí arùn yí múlẹ̀ lára wọn jẹ́ ọgọ́rùú mẹfa ó lé mẹ́ta ènìyàn, àwọn ọgọ́ta ènìyàn ṣaláìsí, nígbà tí àwọn tí ara wọ́n yá jẹ́ ọgọ́ta lápapọ̀. [21]
Oṣù keje ọdún 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejì oṣù keje, ìjọba orílẹ̀-èdè Sierra Leone fagilé ìrìnà ọkọ̀ òfurufú àti lílọ-bíbọ̀ àwọn ènìyàn nípa lílo ọkọ̀ òfurufú tí tí di ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje. Ní ọjọ́ Kẹwàá oṣù keje, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sierra Leone pàṣẹ pé kí wọ́n ṣí àwọn ilé-ìjọsìn ati àwọn pápákọ̀ òfurufú gbogbo pátá padà ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n tó ọgọ́rùún mẹ́ta àti mọ́kalélọ́gọ́ta tí wọ́n ní àrùn COVID-9 ni wọ́n tún rí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní arùn COVID-9 ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti àádọ́rin ó lé mètàlélógún tí àwọn mẹ́tadínlógóje papò dà nígbà tí àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan ati ọgọ́rùún mẹ́ta ó lé méjìlélọ́gọ́ta rí ìwòsàn tí wọ́n sì gbádùn. Àwọn kòkú-kòyè jẹ́ ọgọ́rùún mẹ́ta àti mẹ́rìnléláàzdọ́sàán.[22]
Àwọn ìgbésẹ̀ Ìjọba
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ṣáájú kí wọ́n tó ní akọsílẹ̀ akọ́kọ́, ìjọba orílẹ̀-èdè Sierra Leone ti kéde ìṣèjọba ti pàjáwìrì tí yóò ṣíṣe fún oṣù méjìlá gbáko tíń ṣe odidi 9dún kan gbáko. [23] Wọ́n fagilé ètò ìrìnà gbogbo, wọ́n sì fagilé àwọn ilé-ìjọsìn gbogbo pẹ̀lú. Wọ́n tún kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ méta tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 9jọ́ Karùún oṣù Kẹrin.[24]
Ilé ìfowó-pamọ́ agbáyé kéde owó ìrànwọ́ tí ó tó mílíọ́nù méje àbọ̀ dọ́là fún orílẹ̀-èdè Sierra Leone kí wọ́n fi kojú Ìbúrẹ́kẹ́ ajàkálẹ̀ àrùn COVID-9
Ẹ tún lè wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Sierra Leone confirms first case of COVID-19". WHO | Regional Office for Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-20.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ 4.0 4.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Sierra Leone has confirmed its first case of coronavirus, president says". Reuters. 31 March 2020. https://www.reuters.com/article/us-health-coronavirus-leone-idUSKBN21I1MY. Retrieved 2020-03-31.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 72" (PDF). World Health Organization. 1 April 2020. p. 8. Retrieved 19 July 2020.
- ↑ "Sierra Leone records its second case of COVID-19". April 2020. Retrieved 1 April 2020.
- ↑ "Sierra Leone imposes 3-day nationwide lockdown over covid-19". africafeeds.com. April 2020.
- ↑ "The Ministry of Information and Communication". www.facebook.com. Retrieved 2020-04-04.
- ↑ "MIC Press Release". facebook.com. Retrieved 9 April 2020.
- ↑ "MIC Press Release". facebook.com. Retrieved 12 April 2020.
- ↑ "Africa updates". BBC News.
- ↑ "The Ministry of Information and Communication". www.facebook.com.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 102" (PDF). World Health Organization. 1 May 2020. p. 6. Retrieved 19 July 2020.
- ↑ "Coronavirus – Sierra Leone: COVID-19 Updates 3 May 2020". CNBCAfrica. 3 May 2020. Archived from the original on 19 July 2020. Retrieved 19 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 133" (PDF). World Health Organization. 1 June 2020. p. 6. Retrieved 19 July 2020.
- ↑ "Sierra Leone coronavirus: Compulsory wearing of face masks starts". Africanews.
- ↑ "Coronavirus Frontline Workers In Sierra Leone Declare Strike". Archived from the original on 28 July 2020. Retrieved 11 August 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 163" (PDF). World Health Organization. 1 July 2020. p. 6. Retrieved 19 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 194" (PDF). World Health Organization. 1 August 2020. p. 5. Retrieved 2 August 2020.
- ↑ "Sierra Leone declares 12-month state of emergency". www.aa.com.tr. https://www.aa.com.tr/en/africa/sierra-leone-declares-12-month-state-of-emergency-/1778433. Retrieved 4 April 2020.
- ↑ "Sierra Leone Tightens Restrictions After First 2 Coronavirus Cases | Voice of America - English" (in en). www.voanews.com. https://www.voanews.com/science-health/coronavirus-outbreak/sierra-leone-tightens-restrictions-after-first-2-coronavirus. Retrieved 4 April 2020.