Ernest Shonekan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ernest Shonekan
9th President of Nigeria
In office
August 26, 1993 – November 17, 1993
AsíwájúIbrahim Babangida
Arọ́pòSani Abacha
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Kàrún 9, 1936 (1936-05-09) (ọmọ ọdún 87)

Ernest Adégúnlé Oládéìǹdé Shónèkàn, (ọjọ́ kẹẹ̀sán, oṣù Ebi ọdún1936 ní Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà) jẹ́ agbejọ́rò ará ilẹ̀ Nàìjíríà. Shónékà jẹ́ Ààrè ilè Nàìjíríà fún ìgbà díẹ̀ láti ọjọ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́jọ, ọdún 1993 títí dé ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kọkànlá, ọdún 1993 tí ọ̀gágun Sani Abacha fipa gbà joba lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n fun ní oyè Abese tí ilẹ Ègbá láti 1981 pẹ̀lú àwọn oyè mìíràn[1].

Shónẹ́kàn ti jẹ́ alága àti olùdarí United African Company of Nigeria ( èyí tí ó rọ́pò The Niger Company) Ilé-iṣẹ́ tí ó gbòòrò tí ó sì jẹ́ pé òun ni ilé-iṣẹ́ Áfíríkà tí ó gbòòrò jù ní ilẹ̀ Sub-Saharan Africa.[2]

Ìgbé ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọjọ́ kẹẹ̀sán, oṣù Ebi ọdún 1936 ní wọ́n bí Shónẹ́kàn ní ìlú Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ̀ bí.[3]. Ilé-ìwé CMS Grammar School àti Igbobi College ni Shónẹ́kàn lọ.[4] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ òfin ní University of London, wọ́n sì pè é sí iṣẹ́. Lẹ́yìn náà ni ó tún lọ sí Harvard Business School.[5]

Wàhálà tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rìpọ́bíkì kẹ́ta.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù Ṣẹrẹ, ọjọ́ kejì, ọdun 1993, Shonekan kọ́kọ́ di olórí ìgbìmọ̀ ìyípadà àti olórí ìjọba lábẹ́ Ibrahim Babangida. Nígbà náà ìgbìmọ̀ ìyípadà jẹ́ ìpele tó kẹ́yìn nínú gbígbé agbára fún olórí tí wọ́n yàn ní Rìpọ́bíkì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kẹ́ta.[6] Ní oṣù Ògún, ọdún 1993, Babangida kọ̀wẹ́ fipò sílẹ̀, nípa títẹ̀lé ìdìbò June 12. Ó bọwọ́ lú òfin tí ó fi ìdí ìjọba-fìdí-hẹ múlẹ̀ tí Shonekan darí lẹ́yìn tí wọ́n búra fun gẹ́gẹ́ bí olórí orilẹ̀-èdè.[7][8]


Ernest Shonekan

9th Head of State of Nigeria
Interim
26 August 1993 – 17 November 1993
AsíwájúIbrahim Babangida as Military President of Nigeria
Arọ́pòSani Abacha as Military Head of State of Nigeria
Head of Government of Nigeria
In office
2 January 1993 – 26 August 1993
ÀàrẹIbrahim Babangida
Vice PresidentAugustus Aikhomu
AsíwájúIbrahim Babangida
Arọ́pòInterim National Government
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1936-05-09)9 Oṣù Kàrún 1936
Lagos, British Nigeria (now Lagos, Lagos State, Nigeria)
Aláìsí11 January 2022(2022-01-11) (ọmọ ọdún 85)
Lekki, Lagos State, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúIndependent
(Àwọn) olólùfẹ́Margaret Shonekan
Alma materUniversity of London
Harvard Business School
ProfessionLawyer and businessman




Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "40 Egba chiefs we hardly talk about". citypeopleonline.com. 4 September 2017. Retrieved 30 December 2020. 
  2. "Stronger Moves Towards Manufacturing", Financial Times (London, England), 3 March 1986
  3. Abe, Bankole (11 January 2022). "Ernest Shonekan (1936-2022): His role in Third Republic debacle". International Centre for Investigative Reporting (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 January 2022. 
  4. "Ernest Shonekan (1936 – 2022)". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-21. Retrieved 2022-03-10. 
  5. Latestnigeriannews. "Ernest Shonekan Celebrates His 84th Birthday Today". Latest Nigerian News (in English). Retrieved 30 May 2020. 
  6. Opara, Bartholomew Nnamdi (2007) (in en). June 12, 1993 Presidential Election. Subavic International. ISBN 978-978-028-666-8. https://books.google.com/books?id=G8sjAQAAIAAJ&q=Ernest+shonekan. 
  7. "A Leader in Time of Real Crisis – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2022-09-12. 
  8. Noble, Kenneth B. (27 August 1993). "Nigerian Ruler Cedes Power to Civilian (Published 1993)" (in en-US). The New York Times. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/1993/08/27/world/nigerian-ruler-cedes-power-to-civilian.html.