Yemi Osinbajo
Yẹmí Òṣínbàjò | |
---|---|
Yẹmí Òṣínbàjò, Vice President of Nigeria, at the 43rd G7 summit | |
14th Vice President of Nigeria | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 29 May 2015 | |
Ààrẹ | Muhammadu Buhari |
Asíwájú | Namadi Sambo |
President of Nigeria Acting | |
In office 7 May 2017 – 19 August 2017 | |
Asíwájú | Muhammadu Buhari |
Arọ́pò | Muhammadu Buhari |
In office 19 January 2017 – 13 March 2017 | |
Asíwájú | Muhammadu Buhari |
Arọ́pò | Muhammadu Buhari |
In office 6 June 2016 – 19 June 2016 | |
Asíwájú | Muhammadu Buhari |
Arọ́pò | Muhammadu Buhari |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Oluyemi Oluleke Osinbajo 8 Oṣù Kẹta 1957 Lagos, British Nigeria (now Nigeria) |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Oludolapo Osinbajo |
Àwọn ọmọ | 3 |
Education | University of Lagos (LLB) Nigerian Law School London School of Economics (LLM) |
Website | Official website |
Olúyẹmí Olúlékè Òṣínbàjò (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹjọ oṣù karùn-ún ọdún 1947) jẹ́ òṣèlú àti igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kàrún ọdún 2015 sí 2023.[1] [2] Ó gorí àléfà fún sáà àkọ́kọ́ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015. Lọ́dún 2019, ó tún wọlé lẹ́ẹ̀kejì gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ, òun ti Ààrẹ Muhammadu Buhari. Òṣínbàjò jẹ́ agbẹjọ́rọ̀-àgbà (Senior Advocate of Nigeria, SAN). Ní oṣù kẹrin ọdun 2022, Osinbanjo kẹ́de ète rẹ̀ láti du ipò Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà nínú ìdìbò Ìdìbò ààrẹ 2023 ti Nàìjíríà.[3] Òun ni ó gbé ipò Kẹ́ta nínú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òsèlú All Progressive Congress(APC) tí wón se ní oṣù kẹfà ọdun 2022 pẹ̀lú ìbò 235.[4]
Ìgbéyàwó, ẹbí àti ìgbésí ayé.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yemí Òşínbàjò ni wón bí sí'nú ebí Opéolúwa Òşínbàjò ní ọjọ́ kẹjọ oşù kẹta (Oşù Erénà), ọdún 1957 ní ilé ìwòsàn ti Kíríkìì (Creek Hospital) ní Ìlú Èkó. Òşínbàjò şe ìgbeyàwó pèlú Dolápò Òşínbàjò, ẹni tí orúkọ bàbá rẹ̀ ń jé Şóyodé. Dolápò jé ọmọ sí ọmọ bíbí inú olóyè Obáfémi Awólówò. Wón ní àwon ọmọ méta; méjì nínú u won jé ọmọbìnrin tí orúkọ wọn sì ń jé Dámilólá àti Kányinsólá, àti tí ọmọkùnrin won a sì má a jé Fìyìnfólúwa Òşínbàjò.[5]
Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yemí Òşínbàjò kó ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ́ Kòrónà (Corona) ní ìlú Èkó ní orílè èdè Nàìjíríà. Láàárín-in ọdún 1969 sí ọdún 1975,[6] ó lọ sí Kọ́lẹ́èjì Igbóbì, Yaba ni Ìpínlè Èkó bákan náà, níbi tí ó ti gba àmì ẹ̀yẹ ti Ìpínlẹ̀ ní ọdún 1971. Ó gba ẹ̀bùn ti ilé - iwé fún fífọ́ èdè Gèésì ní ọdún 1972; ẹ̀bùn ti Adé Ọba fún fífọ́ èdè Gèésì l'áti odún 1972 títí di odún 1975; èbùn Elias fún eni tí işé e rè dára jù lọ nínú èkó ìtàn (History) nínú èsì ìdánwò oníwè é méwàá (WASCCE) ti odún 1973. Ó tún gba èbùn ilé ìwé gíga ti HSC fún èkó Lítíréşò ní odún 1975.[7] Léhìn náà, ó lọ k'ékọ̀ọ́ gb'oyè àkọ́kọ́ ní ilé èkọ́ gíga Yunifásitì Èkó láàárín ọdún 1975 sí ọdún 1978. Ìgbà yì ni ó k'ẹ́kọ̀ gba oyè onípele ìkejì ní ilé -ìwé gíga l'órí ìmọ̀ òfin. Níbí ni ó tún ti gba àmì ẹ́yẹ ti Graham-Douglas fún òfin ìdókòwò (Commercial Law).[8] Ní ọdún 1979, ó parí ikẹkò àmọ̀dájú olọ́dún kan tí ó pọn dandan ní ilé ẹ́kọ ìmọ̀ òfin Nàìjíríà níbi tí wọ́n ti gbà á l'áti má a ş'işé gẹ́gẹ́ bí i amòfin àti agbẹjọ́ro ilé ejọ́ gíga (Supreme Court) ti ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1980.[9]
Iṣé Òfin.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]L'áti odún 1979 sí odún 1980, Òşínbàjò kó'pa ní'nu sínsin orílẹ̀ èdè e rẹ èyí tí ó pọn dandan fún odún kan, gégé bí ògá amòfin pèlú ilé işé tí ó ń rí sí ìdàgbàsókè àti ètò Béńdèl (BDPA) ní Ìpínlè Béńdèl.
Ní ọdún 1981, wọ́n gba Òşínbàjò sí'şé gẹ́gẹ́ bí i olùkóni ní'mò òfin ní ilé èkó gíga Yunifásítì ìlú Èkó, Nàìjíríà. L'áti odún 1983 sí odún 1986, ó jé olùkó àgbà l'órí i ìmò òfin ní Yunifásitì ìlú Èkó. L'áti ọdún 1988 sí ọdún 1992, ó jé ónímọ̀ràn (ónímọ̀ràn òfin àti ejó) sí Agbejórò Gbogboògbò (Attorney General) àti Mínísìtà fún ìdájọ́, Bólá Ajíbólá. Òşínbàjò bẹ̀rẹ̀ işé olùkóni ní ọmọ odún métàlélógùn.[10]
Láti ọdún 1997 sí ọdún 1999, wọ́n sọ Òşínbàjò di òjogbọ́n nínú ìmọ̀ òfin àti olórí ẹ̀ka òfin ti gbogbo ènìyàn ti ẹ̀ka ìkekoo òfin ní Yunifásiti Èko. Láti odún 1999 sí ọdún 2007, Òşínbàjò jẹ ọmọ ẹgbé ìgbìmò ilé işé ìdájọ́ ti Ìpínlè Èkó. Ní odún 2007 bákan náà, wọ́n fi Òşínbàjò jẹ́ ọ̀gá alábàáşepò ti àwon alábàáşepò SimmonsCooper (àwon Amòfin àti àwon Agbejóro) ní Nàìjíríà.[11] Òşínbàjò tún jé olùkóni àgbà ní Yunifásiti ti Ìpínlè Èkó. Òun tún ni Agbejoro Gbogboògbò (Attorney General) àti Komíşánnà fún ètò ìdájọ́ . L'áti odún 2007 sí ọdún 2013, Òşínbàjò tún gba işé gẹ́gẹ́ bí i òjògbọ́n onímọ̀ òfin ní Yunifásiti Èkó.
Iṣé Olùşó Àgùntàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yemí Òşínbàjò ni olùşó àgùntàn tí ó ń şe àmójútó ẹkùn ilé ìjosìn ìkejì-dín-l'áàdóta ti Igi Ólíífì (Olive Tree Provincial Headquarter) ti Ìjọ Ìràpadà Ti Krístì tí ó wà ní Ìlú Èkó.[12]
Igbákejì Ààre
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìgbà àkókó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìdìbò ọdún 2015
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Léhìn tí won şe ìdásílè egbé onígbàálè (All Progressive Congress) ní odún 2013, wón fún Yemí pèlú u àwon olókìkí omo ilè Nàìjíríà mìíràn ní işé láti şe àgbékalè àkosílè àwon ètò àti oun tí egbé tuntun yì í má a múlò. Eléyì í ló yo'rí sí àkójopò tí wón pè ní "ìlànà sí Nàìjíríà tuntun", èyí ni ìwé àkosílè kan tí egbé onígbàálè (All Progressive Congress) ké'de rè gégé bí àkosílè ètò àti ìşe tí egbé yì í má a şe nígbà tí wón bá yàn wón sí orí i àlèéfà. Àwon ohun pàtàkì nínú un ìlànà yì í ni ètòt oúnje òfé fún àwon omo ilé ìwé, fífi owó ránşé pèlú u gbè-n-déke (conditional cash transfer) sí mílíònù méèdógbòn àwon aláìní jù lo omo ilè Nàìjíríà tí wón bá fi orúko omo won sí'lè l'áti lo ilè ìwé, tí wón sì tún gba abéré àjesára fún won. Àwon onírúurú u ànfààní ètó sí orò ajé fún òpòlopò òdó omo Nàìjíríà ni ó tún wà.[13]
Ní ojó ketàdínlógún odún 2014, olùdíje fún Ààre l'ábé e egbé e Onígbàálè (All Progressive Congress), ògágun-fèhìntì Mòhámmódù Bùhárí ké'de Òşínbàjò gégé bí i amúgbálégbè é rè àti olùdíje fún igbákejì Ààrẹ fún ìdìbò gbogboògbò ti odún un 2015.[14][15][16][17]
Ní ojó kokànlélógbòn oşù keta (Oşù Erénà) odún un 2015, àjo tí ó ń rí sí ètò ìdìbò jérì í sí yíyan Bùhárí gégé bí i eni tí ó bo'rí ìdìbò ti Ààre. Báyì í ni Òşínbàjò şe di igbákejì Ààre tí a d'ìbò yàn fún orílè èdè Nàìjíríà. Wón bú'ra fún àwon méjèèjì ní ojó kokàndínlógbòn oşù karùn un (Oşù Èbìbí) odún 2015. Ní ojó ketàdínlógún oşù kejo (Oşù Ògún) odún 2017, igbákeji Ààre Yemí Òşínbàjò şe àpèjúwe òrò ìkóríra gégé bí i èyà ìpaniláya.
Àkókò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yemí Òşínbàjò dá'wó lé işé gegegégé bí i igbákejì Ààre orílè èdè Nàìjíríà ní ojó kokàndínlógbòn oşù karùn ún ní gbàgede ti Eagle Square ní Àbújá. Ojúşe rè ni l'áti bójútó àti l'áti ròyìn nípa egbé tí ó ń rí sí ètòt orò ajé, kí ó sì şe ètò nípa ìgbani ní ìyànjú lo sí òdò Ààre, eni tí yí ò mú ìpinnu wá gbèhìn. Gégé bí i ìpìnlè e rè niínú ìmò ò ofin àti ìrírì i rè gégé bí i komísánnà fún ètò ìdájó ní Ìpínlè Èkó fún odún méjo, òpò ènìyàn l'érò pé yí ò k'ópa tó jo'jú nínú u àtúnşe tí a ní'lò ní'nú ètò òfin orí'lè èdè e wa. Nígba tí egbé Onígbàálè (All Progressive Congress) ń polongo fún ìbò ní odún 2014/15, Yemí Òşínbàjò şe òpòlopò ìpàdé pèlú àwon ará ìlú yíká orílè èdè ní ìlòdì sí ìpòlo-n-go gba-n-gba tí òpò omo orí'lè èdè Nàìjíríà òun olóşèlú u won má a ń şe télè. Òkan nínú àwon ìlérí tí ó şe ní'gbà ìpolo-n-go ìbò, tí ó sì tún so láìpé yìí ni ti ètò l'áti fi oúnje èèkan l'ójúmó bó omo ilé ìwé kòòkan. Yàtò sí fífún omo ilé ìwé ní oúnje, ó tún te'nu mo láìpé pé ètò yìí yó ò pèsè oríşiríşi işé (ilérí ìpolo-n-go ìbò míràn) fún àwon tí ó bá da'ra pò l'áti ş'işé l'ábé e ètò yìí l'áti mu wá sí ìmúşe.
Adelé Ààre
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààre Mùhámmádù Bùhárí ko àkosílè ní ojó kesàán osù karùn-ún odún 2017 sí Ààre ilé ìgbìmò aşòfin àgbà àti ti ilé ìgbìmò aşòfin kékeré lórí i ìpinnu rè láti bèrè ìrìn àjò fún ìtójú àìlera rè. Wón ka ìwé yì í ní ojó kesàn án oşù karùn ún odún 2017 ní ibi àpérò àwon ilé méjèèjì, ti aşòfin àgbà àti ti kékeré ní şíşè-n-tèlé. Igbákejì Ààre, òjògbón Yemí Òşínbàjò ni wón jíròrò lé so di adelé Ààre fún àkókò tí Ààre Bùhárí yí ó ò fi wà ní ìsinmi nítorí i àìlera rè.
Ní ojó keje oşù kejo odún 2018, Òşínbàjò yo ògá àgbà tí ó ń rí sí ààbò ará ìlú, Làwál Dàùra kúrò l'énu işé fún wíwo ilé Aşòfin ti àwon tí ó di ìhámóra ogun pèlú u ìbòjú l'áti èka ilé işé rè wà á ní ònà tí kò tó. Dàùra ni wón ti fi Mathew Seiyefa ró'pò o rè.
Àkókò Kejì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kíkéde ète láti dupò ààre
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ojo kokanla, osù kerin, odun 2022(April 11, 2022), ígbákejì ààré, òjògbón Yemi Osinbajo kede ète rè láti dupo ààre Nàìjíríà ní odún 2023 lábé egbé oselu APC, ó padà fi ìdí rẹmi sí ipò kẹta nínú ìdìbò abẹ́lé APC.[18]
Awon itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "BREAKING: Shettima Sworn In As Nigeria’s Vice President". Sahara Reporters. May 29, 2023. Retrieved June 17, 2023.
- ↑ "Vice President Yemi Osinbajo". The Statehouse, Abuja. 2018-05-06. Archived from the original on 2022-06-27. Retrieved 2021-09-11.
- ↑ Oyeleke, Sodiq. "BREAKING: Osinbajo officially declares for President". The Punch. Retrieved 11 April 2022.
- ↑ "APC presidential primaries winner: Bola Tinubu win All Progressives Congress ticket". BBC News Pidgin. 2022-06-08. Retrieved 2022-06-08.
- ↑ Ogechukwu, Nwabugo (14 December 2021). "Prof. Yemi Osinbajo Biography, Children, Wife, Family, Quick Facts". BuzzNigeria.com (BuzzNigeria). https://buzznigeria.com/facts-must-know-prof-yemi-osinbajo/.
- ↑ "Vice President Yemi Osinbajo". Statehouse.gov.ng. Archived from the original on 20 February 2018. https://web.archive.org/web/20180220052449/http://statehouse.gov.ng/vice-president-yemi-osinbajo/.
- ↑ Admin (8 March 2018). "Yemi Osinbajo at 61". The Boss Newspaper. Retrieved 26 January 2019.
- ↑ "About Prof Osinbajo". Prof. Yemi Osinbajo (SAN) (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-19.
- ↑ Etu, Kayode (18 December 2014). "Profile of Yemi Osinbajo". Vanguard. Retrieved 26 January 2019.
- ↑ "Lectured at 23, borrowed to pay school fees... 7 things you didn't know about Osinbajo". thecable.ng. 8 March 2017. Retrieved 2 April 2017.
- ↑ "I'm Still a RCCG Pastor, Says Vice President Yemi Osinbajo". connectnigeria. Archived from the original on 2015-07-11. https://web.archive.org/web/20150711003409/http://connectnigeria.com/articles/2015/06/12/im-still-a-rccg-pastor-says-vice-president-yemi-osinbajo/#sthash.HPknXDLn.dpuf.
- ↑ "Meet Buhari's running mate, Prof Yemi Osinbajo". Vanguard. 17 December 2014. Retrieved 29 January 2015.
- ↑ "APC unveils Manifesto, Code of Ethics – Premium Times Nigeria". Premiumtimesng.com. 6 March 2014. Retrieved 1 April 2015.
- ↑ "Meet Buhari's running mate, Prof Yemi Osinbajo". Vanguardngr.com. 17 December 2014. Retrieved 1 April 2015.
- ↑ "Meet Buhari's Running mate, Prof Yemi Osinbajo". All Progressive Congress. Archived from the original on 2014-12-28. Retrieved 2023-03-06.
- ↑ "APC is govt in waiting – Tinubu". The Punch – Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 22 January 2015. Retrieved 1 April 2015.
- ↑ NewsPunch. "APC VP Ticket: Tinubu shuns Fashola, Amaechi, others; favours Osinbajo". Newspunch.org. Archived from the original on 21 March 2015. Retrieved 1 April 2015.
- ↑ Times, Premium (2022-04-11). "2023: Osinbajo declares intention to run for president". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-04-27.