Patrick Aga
Patrick Aga ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí Aṣòfin fún agbègbè Nasarawa ti eka Ariwa (North) ti ìpínlẹ̀ Nasarawa, Nàìjíríà ní ìbẹ̀rẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kẹrin, tí ó ń dije lati egbe Peoples Democratic Party (PDP). Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kọkàndínlọgbọn oṣù karùn-ún ọdún 1999.[1]
Lẹ́yìn tí ó gba ìjókòó rẹ̀ ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní oṣù kẹfà ọdún 1999, wọ́n yàn án sí ìgbìmọ̀ lórí Ìwà, Ìdájọ́, Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin, Ìṣòwò, Ẹ̀kọ́, Àwọn Iṣẹ́ Àkànṣe àti Gbèsè Ìbílẹ̀ & Ajeji (igbákejì alága).
Ní àsìkò ìdìbò ọdún 2003, Aga gbé lọ sí ẹgbẹ́ Alliance for Democracy (AD) pẹ̀lú ìrètí láti di gómìnà Nasarawa lórí ìkànnì yẹn.
Lẹ́yìn ìdìbò naa, ẹgbẹ́ AD pín sí ẹgbẹ́ alátakò méjì.
Ní oṣù Kejìlá ọdún 2003 wọ́n yàn Aga gẹ́gẹ́ bí igbákejì alága orílẹ̀-èdè fún agbègbè Àríwá-Àárín nínú ẹgbẹ́ tí Olórí Adebisi Akande ń darí.[2]
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Federal Republic of Nigeria Legislative Election of 20 February and 7 March 1999". Psephos. Retrieved 2010-06-24.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Bolade Omonijo, Emmanuel Aziken & Olasunkanmi Akoni (17 December 2003). "Akande Emerges Lagos AD Faction Chairman, Akinfenwa Wins in Abuja.". Vanguard. Archived from the original on 2012-10-22. Retrieved 2010-06-25. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)
- All articles with dead external links
- Articles with dead external links from March 2025
- Articles with invalid date parameter in template
- Articles with permanently dead external links
- Pages with citations using unsupported parameters
- Pages using duplicate arguments in template calls
- Àwọn olóṣèlú ará Nàìjíríà