Jump to content

Ìpínlẹ̀ Cross River

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Cross River)
Ipinle Cross River
State nickname: The People's Paradise
Location
Location of Cross River State in Nigeria
Statistics
Governor
(List)
Benedict Ayade (PDP)
Date Created 27 May 1967
Capital Calabar
Area 20,156 km²
Ranked 19th
Population
1991 Census
2005 estimate
Ranked 28th
1,865,604
3,104,446
ISO 3166-2 NG-CR

Ìpínlẹ̀ Cross River jẹ́ kan láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní agbègbè Gúúsù-Gúúsù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n sọọ́ lórúkọ fún àwọn ará Cross River, wọ́n dá Ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ látara ìlà-oòrùn ní agbègbè ìlà-oòrùn ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 1967. Olú-ìlú rẹ̀ ni Calabar, Ó pín ààlà sí àríwá pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Benue, sí ìwọ̀-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ebonyi pẹ̀lú sí Ìpínlẹ̀ Abia , àti sí gúúsù-ìwọ̀-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom nígbàtí ààlà ìlà-oòrùn rẹ̀ parapọ̀ di ààlà orílẹ̀ èdè pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Cameroon.[1] Ìpínlẹ̀ Gúúsù-Ìlà-oòrùnni wọ́n mọ̀ọ́ sí kí wọ́n tó yí orúkọ rẹ̀ padà ní ọdún 1976, Ìpínlẹ̀ Cross River tẹ́lẹ̀rí ṣàkóónú agbègbè tí ó wá di Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom báyìí, tí ó di ìpínlẹ̀ tí ó dá yàtọ̀ ní ọdún 1987.[2]

Láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Cross River jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́tàlélẹ́gbẹ̀rin-ọgọ́rùn-ún gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[3]

Láyé òd-òní Ìpínlẹ̀ Cross River ti ní olùgbé láti bí ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà, pàáp̀á àwọn ará Efik ti gúúsù ni apá odò àti Calabar; àwọn ará Ekoi (Ejagham) ti erékùṣù gúúsù; àwọn ará Akunakuna, Boki, Bahumono, àti Yakö (Yakurr) ti àáríngbùngbùn agbègbè náà; àti àwọn ará Bekwarra, Bette, Igede, Ukelle (Kukele) ti agbègbè àríwá. Ní àkókò ìmúnisìn, ibi tí awá mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Cross River báyìí pín sí àwọn ẹ̀yà tí àwọn kún àwọn ará E̩gbé̩ Aro nígbà tí àwọn ará Efik ṣẹ̀dá Akwa Akpa (Calabar àtijọ́) ìlú-ìpínlẹ̀.[1]



  1. 1.0 1.1 E.J. Alagoa, Tekena N. Tamuno (1989). Land and people of Nigeria: Rivers State. 
  2. "This is how the 36 states were created". Pulse.ng. 24 October 2017. Retrieved 15 December 2021. 
  3. "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Archived from the original on 14 December 2021. Retrieved 14 December 2021.