Mùhammádù Bùhárí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Muhammadu Buhari
Muhammadu Buhari - Chatham House.jpg
President of Nigeria
Lọ́wọ́
Ó bọ́ sí orí àga
29 May 2015
Vice President Yemi Osinbajo
Asíwájú Goodluck Jonathan
Head of State of Nigeria
Lórí àga
31 December 1983 – 27 August 1985
Asíwájú Shehu Shagari
Arọ́pò Ibrahim Babangida
Governor of the Northeastern State
Lórí àga
August 1975 – March 1976
Asíwájú Musa Usman
Arọ́pò Position abolished
Federal Commissioner of Petroleum and Natural Resources
Lórí àga
March 1976 – June 1978
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìbí 17 Oṣù Kejìlá 1942 (1942-12-17) (ọmọ ọdún 73)
Daura, Colonial Nigeria[1][2]
Ọmọorílẹ̀-èdè Nigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlú All Progressives Congress
Tọkọtaya pẹ̀lú Àdàkọ:Plainlist
Àwọn ọmọ
Alma mater Àdàkọ:Plainlist
Ẹ̀sìn Islam
Website thisisbuhari.com
Iṣé ológun
Asìn  Nigeria
Ẹ̀ka ológun Nigerian Army
Ìgbà ìṣiṣẹ́ 1961–1985
Okùn Major General


Muhammadu Buhari

Muhammadu Buhari ti a bi ni odun 1942 ti o si je okan lara awon ti o gbe apoti fun ipo Are ni odun 2003 ati 2007 labe asia egbe ANPP ni a so itan re si isale yii ni ede Geesi. Fulani ni. Elesin Musulumi ni. Ipinle Katsina ni o ti wa.

(1) Ààrè Kéje orílè-èdè Nàìjíríà

(2) Lati Dìsémba ojo kokànlélógbòn odún 1983 sí ógósì ojó ketàdínlógbòn odún 1985.

(3) Èni tí ó wà níbè kí ó tó bó sórí àlééfà ni Shehu Shagari

(4) Eni tí ó tèlè e nígbà tí ó kúrò níbè ni Ogagun Ibrahim Gbàdàmósí Babangida.

(5) Odún ti a bí i: Dìsémbà odún 1942.

(6) Ìpínlè tó ti wa: Ìpínlè Katsina, orile-èdè Náíjíríà

(7) Egbé òsèlu tí ó wà: Ologun/Egbe gbogbo omo orílè-èdè Nàijíríà. (All Nigeria People’s Party)

(8) Èsìn Mùsùlùmí. Muharmmadu Buhari ti je àarè orílè-èdè Náíjíríà nígbà kàn rí. Èyí jé ní odún 1983 sí 1985. Ó tún jé òkan lára àwon olùdije fún ipò ààre tí ko rówó mú ni Epiri 19, 2003. Èyà Fúlàní ni, ó sì ní ìgbàgbó nínú èsìn Mùsùlùmí. Katsina ní ìpínlè ti idile tó ti sè wá ti wá. Ògagun Muhamadù Buhari àti Ògagun Túndé Ìdíàgbon ni wón yan láti se asáájú orílè-èdè Nàìjíríà léyìn tí àwon ológun dìtè gbàjoba lówó ààre orílè-èdè Shehu Shagari ní Dìsèmbà 31. 1983.

Buhari nígbà náà lóhùn ún ni wón yan gégé bí ààre orílè-èdè àti olórí pátápátá fún gbogbo egbé omo ogun orílè-èdè nígbà tí a fi Túndé ìdíagbon se igbákeji re. Nígbà tí won so o di aare orílè-èdè, ó fi gbogbo enu so pé ó tó kí ìgbà yípadà kúró lówó àwon ìjoba alágbádá tí wón je jegúdújerá àti pé nígbà ìsèjoba rè ni a gbé àjo Ìlúmòóká kan kalè tí wón pè ní (WAI) “War Against Indiscipline” Igbogunti ìwà kòlòbòròsí, ìwà àìbíkítà, ìwà ìbàjé péépèèpé láwùjo. Bú o tilè jé pe làbé ijoba ológun apàsé wàá ni wón ti gbé àjo yìí kalè, ìgbétasì tàbí ìpolongó yìí fesè ranle débì pé yàtò sí pé òpò ènìyàn ló mú u lò, ó sì ń nípa lórí àwon ìwa tó bétòómú tó ye kí ojúlówó omo orílè-èdè máa hu ni kòro àti ní gbangba títí di òní olónìí.

Ijoba rè nígbà náà lóhùn-ún jé èyí tí a mo bí eni mowo àmó àwon ènìyàn bèrè sí dèyìn léyìn ìjoba rè nígbà tí òun ati Ìdíàgbon bérè sí gbé àwon ìgbásè tó lekoko jù. Àwon òfin idiwon kan-n-pa (Decree) tí wón mú lò. Lára àwon òfin yìí ní pé kí ìjòba lágbára láti so ènìyàn séwòn láìlèjáde mó, láìsí sejó onítòhún, láìsí rí pé ó jé aditè ló lodi si ìjoba.

Ogagun Ibrahim Babangida ló sòtè gbajoba lówó Ogagun Mahammadu Buhari ni odún 1985 nítorí pé ó fé sèwádìí àwon owó tí wón kona lénu ise ológun. Bó bá jé pe lóòótò ni ogagun Ibrahim Babamgida sèwádìí yìí. Òpò àwon lógàlógà lénu isé ológun ni wón kó bá ní kí won kógbá sílé. Irírí yìí ló jé èyí tí ó da ogagun Muhammdu Buhari lókanru ju nínú ìtàn ìgbésí-ayé rè.

Léyìn àkókò yìí, ìgbà tí a tún gbúròó rè ni nígbà ìsèjoba ogagun Sanni Abacha. Ó sise gégé bí olórì àwon ti o bójúto òrò ìnáwó epo ronì (petroleum trust fund).

Ní odun 2003, Buhari díje fún ipò ààre lábé ìjoba alágbádá láti inú egbé (All Nigeria People’s Party ANPP). Wón fi èyin rè gbálè tàbí ó fidirémi láti owó àwon (People Democratic Party PDP). Ààrè Olúségun Obásanjo ni ó là a mólè nínú Ìbò náà. Àwon onímò ìsirò so pé èyí tí ó fi là á ju mílíònù mókànlá lo.

Ó seniláànú pé ògagun Buhari kò ní àwon ohun tó se koko láti borí ìdíje fún ipò ààre ní orílè-èdè Náíjíríà,:- fún àpeere owó ìyen àpèkánukò, àti àwon eléte tí wón lè so ogún ìbò rè di ogójì tàbí di ààdóta pàápàá. Òòtó ni pé òpò èsùn ìwà àìsóótó ni wón gbé dìde ní ilé-ejo lòdìsí ìbò náà. Àjo “Commonwealth” náà si bènu àté lu ìwà màkàrúru tí o selè nígbà ìdìbò náà síbè ohun tí won so fún Ogagun Muhammadu Buhari ní ilé ejó ni pé kí ó má fàkókò re sofo nítorí pé kò ní ohun tó pe fi ra ohun tí wón ń pé ní ìdájó òdodo. Siwájú síì wòn só fún un pé òpò omo orílè-èdè Nàíjíríà ni kò lágbára láti máa gbé pátáko “a ò lè gbà” kan kiri ojú pópó mó. Wón ní bó bá jo bíi pé ìreje wà, wón ní kó fówó wónú won ni ko fi sosùn kó fi para. Léyìn-ò-reyìn Ilé ejó wá gbé àbájáde kan jáde pé sogún dogódì tàbí Ogbón àlùmòkóróyí tó wà nínú ìbò náà kíì se ohun táa lè fowó dan-in-dan-in mú láti le mu ká fagile odindi ìbò ààre náà pátápátá. Ohún tí wón ń so ni pè èsùn tí ògagun Bùhárí gbé wá kò lése nílè tó nítorí náà, won jé kó mò láti ilé ejó pé ó fidíremi.

Ní ojo kejìdínlógún Dìsémbá 2006, Ogagun Mahammodu Buhari ni won. yan kale láti díje fún ipò ààre ní odún 2007 nínú egbé òsèlú (ANPP). Yorùbá ní bá –ò-kú ìse ò tán. Eni tí wón ń reti tí yóò je olúdije pèlú re ni odún 2007 ni eni tí o n sakoso egbé òsèlú PDP lówólówó. Ògbeni Umaru Musa Yar’adua.

Yàtò sí Ògagun JTU Aguiyi-Ironsi, Buhari jé òkan lára ààre orílè-èdè yìí to ti fèyìntì tí kò sowó ilu básubàsu. Léyìn tí won yo o kúrò nínú àhámó tí wón fí sí kò ní ilé tí ó lè dé sí. Nsé ló lo yáwó nílé ìfowo pamó tó fí ra kaadi ìdìbò fún ipò ààré tí egbé (ANPP). Èyí tí o ná an ni mílíònù méwàá náirà. Òwó ìfeyìnti rè lénu isé ológun ni òna kansoso tí owó ń gbà wolé fún un lónìí.

Ó sì wà láàyè, oun àti àwon ìdílè ré wà, tí won ń gbé ní ìpínlè Katsina nílu rè, tí ó fowólérán tí ó ń dúró dì ìgbá ìbò odun 2007


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]