Olokun Festival
Ìkọ awọ́lẹ́ẹ̀gbẹ́
Olokun Festival | |
---|---|
Water, Health, and Wealth | |
Member of Orisha | |
Script error: The module returned a nil value. It is supposed to return an export table. | |
Other names | Olocún, Olókun |
Venerated in | Yoruba religion, Candomble, Santeria |
Region | Nigeria, Benin, Cuba, Brazil |
Ethnic group | Yoruba people Bini people |
Àdàkọ:Yoruba people Olokun (Yorùbá: ni à ń pé ní Olókun) jẹ́ Òrìsà ní ilé Yorùbá tí wọn sì ń sìn. Àwọn Yorùbá gbà gbọ́ pé Olókun ní ó bí Aje, èyí tí ó jẹ́ Òrìsà fún Ọrọ̀, Ọlá, tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkun. Olókun jẹ́ òrìsà tí ó ń darí àwọn ohun tí ó wà lábé Omi òkun, Ó sí jẹ́ òrìsà tí ó lágbára jù gbogbo ohùn tí ó wà lábé Omi òkun tàbí àwọn òrìṣà kékéèèké tí ó wà lábé Omi òkun. Olókun jẹ́ Òrìsà nlá tí wọn máa ń gbórínyìn fún nípa bí ó ti lágbára láti fún àwọn olúsín rẹ ní Owó, Ọlá, Ọrọ̀, àti àṣeyọrí nígbà tí wọn bá kìí tán. Àwọn olùgbé agbègbè ní ilé adúláwọ̀ pàápàá jùlọ ní ìwọ̀ oòrùn Áfríkà àti ní Ilé Áfíríkà lápapọ̀ rí Olókun gẹ́gẹ́ Obìnrin, àwọn kàn sí gbàgbó pé Okùnrin ní Olókun, tí àwọn mìíràn sí pé méjèèjì ní Olókun jẹ́.[1][2][3]
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ayẹyẹ Olókun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọdún àṣà ọlọ́dọ́ọdún ní orílé èdè Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá máa ń ṣe káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, tí àwọn Ẹdó sí tún ń ṣe. Ní èdè Yorùbá, Òkun túmọ sí odò Òkun, nígbà tí Ọ̀sà túmọ sí Lagoon (òkun paade). Olókun ní orúkọ tí wọn máa ń pè Òrìsà inú òkun, nígbà Ōlọ́sà tí a tún lè pè ní Ọ̀ṣárá jẹ́ Òrìṣà inú Ọ̀sà àti àwọn inú rẹ́ mọ́ àwọn ohun tí ó wà ní ìgbèrí rẹ. Méjèèjì ni wón je ìṣẹ̀ṣe, wọn sì ní bí wọ́n tí ń sìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí Àjọ̀dún.[4][5]
"Ìbà Olókun fẹ́ mi ló’re.
Ìbà Olókun ọmọ re wa se fun oyi o.
Olokun nu ni o si o ki e lu re ye toray.
B’omi ta’afi."
B’emi ta’afi. Ase.
Ní ilé Yorùbá, ìjọsìn Olókun wà ní agbègbè Ilóde ní Ilé Ìfẹ. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè kan ní Ilé-Ifè, Oloye Kọ́láwọlé Ọmọtáyọ̀, ẹni tó jẹ́ Abọrẹ̀ (Olórí Àlùfáà) tí ó sàlàyé ohun tí Olókun jẹ́: “Olókun ní Òrìsà tí ó kó gbogbo omo ayé papọ́, àwọn ẹdá náà ó yọlé, tí ó sí gbé e sí inú rẹ́.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ Ipò-Okun
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé, ilẹ̀ ayé kò ní ìrísí, ó sì kún fún omi. Olódùmarè pàṣẹ fún Obatala, Olóyè kàn tí ó jẹ́ Òrìsà, láti lọ sí àgbáyé láti bẹ̀rẹ̀ ìlànà lórí ilẹ. Báyìí ní Obatala, tí ó ní ihamọra ìgbà ìwà, sọ̀kalẹ láti ọ̀run nípasẹ ẹ̀wọn. “Lati Ilode, nibi ti a duro bayii, Orisa nla Olokun ti bere si ni fa gbogbo omi papo. Lẹ́yìn èyí, ó kó gbogbo nǹkan gba Ilare lọ sí apá ibi tó jìnnà gan-an ní ilẹ̀ ayé nígbà yẹn tó jẹ́ òkun òde òní.
Lára àwọn Ìlájé tí wọ́n gbé èbá Òndó gbà pé Òrìsà Olókun pé òrìsà òkun ni, tí ó ní agbára láti fí ọmọ fún àwọn Obìnrin àgàn. Wọ́n tún gbàgbọ́ pé ó wà ní ìṣàkóso àwọn ìgbì omi òkun, àti pé ó lè rì àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n bá jẹ́ olùṣe búburú. Olókun tún jẹ́ Òrìsà Ọrọ̀, ó sí ní agbára láti mú àwọn olúfọkànsì rẹ di olówó. Gbogbo àwọn olùjọsìn Olókun ní wọn máa ń wọ aṣọ funfun aláìlábàwọ́n tí wọn sì fi àtíkè funfun sójú. Gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ àkíyèsí láàárín àwọn Ìlájẹ̀, Ọ̀yọ̀ Olókun jẹ́ ọ̀wọ̀ gíga, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́ pé ó ní ipa díwọ̀n lórí ìgbésí ayé wọn.
Ní ìwọ̀orùn áfríkà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òrìsà jẹ́ ohun tí ó wà níbí kíbi, wọ́n sì jẹ́ ohun pàtàkì ní orílé èdè Nàìjíríà.";[6] Àwọn tí wọn ń sin Olókun a máa wà nílé tí àwọn elédè Yorùbá bá wà àti pé àwọn tí wọn wà ní ìpínlè Ẹ́dó ní apá gúúsù ní orílé èdè Nàìjíríà. Ní àwọn ilé ìwọ̀orùn áfríkà nítòsí etí òkun, Ọkúnrin ní Olókun jẹ́ fún àwọn olúsín rẹ, nígbà tí àwọn mìíràn gbàgbọ́ pé Obìnrin ní òrìsà Olókun.[2]
Gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀sẹ̀ àti ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nipa lórí ohùn àdáyébá, Olókun gẹ́gẹ́ bí obìnrin jẹ́ Aya àkọ́kọ́, tó sì jẹ́ olórí àwọn ìyàwó tí Odùduwà fẹ. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti àwon ìyàwó yòókù ló ṣe òkùnfà bí ó tí di ohun tí à ọ ní Okun lóni.[7]
Ní Candomblé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní Ìpínlè Candomble ní orílé èdè Biràsílí, en gbàgbọ́ pé Olókun ní ẹni tí ó bí Yemọja àti pé òun ló ní Òkun. Wọ́n mọ rírì Olókun ní ìpínlè Candomble àti àwọn àgbègbè rẹ̀, èyí tí kò sí nínú àwọn ọdún wọn. Nípa èyí, kòsí ìyàtọ̀ láàrin Odùduwà àti Ọ̀rúnmìlà; àwọn wọnyí ní ipá pàtàkì tí wọ́n ní ní orílé Adúláwọ̀ ṣùgbọ́n tí ipá rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ múlẹ ní Àwọn agbègbè kàn tí àwọn èèyàn aláwò dúdú wà ní Brazil tí wọ́n ń sìn wọ́n. Kòsí ọfò kàn tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún Olókun èyí tí àwọn Oríṣà yóò ku ní. Àwọn èèyàn Candomble mọ rírì Olókun gẹ́gẹ́ ní òrìsà, àmọ́ wọn kò rí gẹ́gẹ́ bí Òrìsà tiwon. Ìjọsìn fún Olókun tí kú tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rẹ̀ sì ní sìn padà ní ọ̀rúndún méjì sẹyìn nígbà tí àwọn Àgbà Awo rírìn àjọ lọsí orílẹ̀-èdè Brazil tí wọn sì rí bí wọ́n ti gbé Olókun.[8]
Wọn máa ṣe ayẹyẹ Olókun nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún Yemọja tí wọn ń pè ní (Festa de Iemanjá).
Ní Santería
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olókun jẹ́ Òrìsà tí wọ́n ń sìn ní Santeríà. Olókun jẹ́ òrìsà kan tí ó jẹ́ akọ àti abo, èyí tí ó máa ń jẹyọ nígbà tí ó bá jẹ́ Olókun ifá tàbí Olókun Ocha ni wọ́n bá bẹ̀wò.[2][9]
Ayẹyẹ Olókun ní ìlú Èkó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olúàṣẹ Olókun Àgbáyé àti olùpéjọ Ọdún Olókun, Yéye Lára Fáṣọlá-Fánimòkun, sọ pé àjọyọ náà ní èrò láti ṣe ayẹyẹ àṣà àti ìṣẹ̀ṣe tí Yorùbá tí ó ní ìmọràn, ó tẹnumọ́ pé ó tún jẹ́ ayẹyẹ tí òrìṣà Yorùbá tí ó ni ṣe pẹlú ọrọ̀ nlá àti ìdàgbàsókè ajé. Ní ọdún 2021, ọdún Olókun tí ó wáyé ní Monarch Event Centre Lẹ́kí ní ìlú Èkó, tí ro pé ó nílo láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mímọ̀ sí ìgbàlà àṣà ọlọrọ̀ tí Ìpínlè Èkó àti ìran Yorùbá ní gbogboògbò láti má lọ sí ìparun.[10][11]
Ó sàlàyé pé àṣà àti ohun-iní wà ní àayé àkọkọ nínú Ètò Írín-àjò tí Ìpínlè láìpé tí Gómìnà Sanwó-Olú gbékalẹ̀ sí àwọn arínrín àjò láìpé, ní ìdánilójú pé Èkó ti pinnu láti ṣẹ àtìlẹ́yìn fún gbogbo ìpìlẹṣẹ tí a tọ́ka sí tọ́jú àwọn ohun-ìní àṣà rẹ̀.
Ayẹyẹ Olókun ní ìlú Ẹdọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ẹdọ́ ń ṣe ayẹyẹ tiwọn ní òpin oṣù Kejì ( 'òsùpá kinni'' lẹ́yìn oṣù Kejìlá) tí ó wáyé ní Usonigbe, ibí ìjọsìn Olókun, ní ìpínlè Ẹdọ́. Òmíràn, ayẹyẹ ìgbàlódé díẹ síi tí wáyé ní Ìpínlè Èkó èyí tí wọn máa ń ṣe ní Oṣù kọkànlá.
Ayẹyẹ Olókun tí wọn ṣe kẹ́yìn, èyítí ó ti wáyé láti ọdún 2002, tí ṣètò nípasẹ Olókun Festival Foundation àti pé ó tí di arinrin àjò pàtàkì àti ìfàmọ́ra agbègbè. Ọ̀túnba Gàní Adams ló tún darí Ẹgbẹ́ Oódua People’s Congress.
Pàtàkì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ówà ninu Ẹsẹ ifá, Inú bí Olókun, èyí ló mú kí o kún wà sí Orí ilé. Olókun ṣe èyí láti gbé àwọn èèyàn lọ nígbà tí inú bíi, àwọn Òrìṣà yòókù bá tọ Ọ̀rúnmìlà lọ láti mọ bí wọn yóò ṣe tú Olókun. Ọ̀rúǹmìlà wí fún wọn pé Ògún ní yóò rọ ẹ̀wọ̀n tí yó gún gán, èyí tí gùn jùlọ. Àtipé Ọbàtálà ni yóò ṣe iṣẹ́ tó jù, nípa pé òun ní yóò fi ẹ̀wọ̀n yìí fí dé Olókun, tí yóò fi wá ní ìkápá rẹ̀ ìyẹn Ọbàtálá. Lẹ́yìn tí wøn tí gbọ́ èyí ní Ọbàtálá bá lọ bá Ògún pé kí ó ṣe ẹ̀wọ̀n, èyí tí Ògún náà sì gbọ́. Ọbàtálá bá ṣe bẹ́ lọ sínú Òkun, ó sí fi ẹ̀wọ̀n náà dé Olókun náà.
Ewo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Adeoye, C. L. (1989) (in yo). Ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn Yorùba. Ibadan: Evans Bros. Nigeria Publishers. pp. 227–236. ISBN 9781675098.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 Clark, Mary Ann (2007). Santería : correcting the myths and uncovering the realities of a growing religion. Westport, Conn.: Praeger Publishers. pp. 62. ISBN 978-0-275-99079-4.
- ↑ Harvey, Marcus (2015). "Engaging the Orisa: An Exploration of the Yoruba Concepts of Ibeji and Olokun as Theoretical Principles in Black Theology". Black Theology 6 (1): 61–82. doi:10.1558/blth2008v6i1.61. ISSN 1476-9948.
- ↑ Olokun: On the trail of the sea goddess | National Mirror (archive.org)
- ↑ Who is OLOKUN? | Oyeku Ofun Temple
- ↑ Murphy, Joseph (2001). Ọ̀ṣun across the waters: a Yoruba goddess in Africa and the Americas. Bloomington: Indiana University Press. p. 238. ISBN 9780253108630.
- ↑ "Olokun, Osaara: The Making Of The Atlantic Ocean And The Lagos Lagoon". The Sun. https://www.sunnewsonline.com/olokun-osaara-the-making-of-atlantic-ocean-lagos-lagoon/.
- ↑ Silva, Marcel Franco da (2012). "A polissemia do sagrado em do amor e outros demônios de Gabriel García Márquez". INTERAÇÕES: Cultura e Comunidade 7 (12): 69–90.
- ↑ Babalawo, Santeria's High Priests: Fathers of the Secrets in Afro-Cuban Ifa, Por Frank Baba Eyiogbe, Olokun
- ↑ ‘WHY WE SUPPORTED OLOKUN FESTIVAL’ – LASG – Tourism, Arts & Culture – Lagos State Government
- ↑ Odu Ifa | Farinade Olokun