Jump to content

Whoopi Goldberg

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Whoopi Goldberg
Goldberg in New York City, November 2008
Ọjọ́ìbíCaryn Elaine Johnson
13 Oṣù Kọkànlá 1955 (1955-11-13) (ọmọ ọdún 69)
New York City, New York, US
Iṣẹ́Actress, comedienne, radio disc jockey, producer, author, singer-songwriter, talk show host, activist
Ìgbà iṣẹ́1981 – present
Olólùfẹ́Alvin Martin (1973–1979)
David Claessen (1986–1988)
Lyle Trachtenberg (1994–1995)
Alábàálòpọ̀Frank Langella (1996–2001)

Whoopi Goldberg (play /ˈhwʊpi/; oruko abiso Caryn Elaine Johnson, November 13, 1955) je is an American alawada, osere, akorin-akoweorin, alakitiyan oloselu, ati olootu eto iforojomotoro-oro[1].


Ìgbèsi Àyé Àrabinrin naa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Whoopie ni a bini Manhattan, New York City ni óṣu November ni ọdun 1955. Iya óṣèrè lóbinrin Emma Johnson naa jẹ Nurse ati ólùkọ (1931-2010), baba rẹ Robert James (1930-1993) jẹ Baptist ati Clergyman. Whoopi ni a tọ ni ilè public project, Ilè Chelsea-Elliot ni New York City[2][3].

Ni ọdun 1970s, Goldberg ko lọ̀ si San Diego, California nibi to ti di waitress lẹyin naa ni óṣèrè lóbinrin naa kó lọ̀ si Berkeley nibi to tin ṣisẹ gegebi bank teller, cosmetologist ti mortuary ati bricklayer[4].

Goldberg fẹ ọkọ lẹmẹtahas been married three times. Óṣèrè lóbinrin naa ṣè igbeya pẹlu Alvin Martin lati ọdun 1973 dè 1979; Igbèyawò pẹlu David Claessen lati ọdun 1986 dè 1988; Igbèyawó pẹlu Lyle Trachtenberg lati 1994 dè 1995[5][6]. Ni ọdun 1973, Goldberg bi ọmọ óbinrin Alexandrea Martin to pada di óṣèrè lóbinrin ati producer to si bi ọmọ mẹ̀ta[7].Iya Goldberg ku ni óṣu August, ọdun 2010 lori aisan stroke.

Ipà Óṣèrè lóbinrin ninu èrè àgbèlèwó

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Goldberg se filmu akoko re pelu The Color Purple (1985) gege bi Celie, obinrin adulawo ti won seka si ni Guusu Amerika. O gba idaloruko fun Ebun Akademi fun Osere Obinrin Didarajulo be si ni o gba and won her first Ebun Wura Roboto re akoko fun ere re ninu filmu yi. Ni 1990, o sere bi Oda Mae Brown, abokusoro to unran okunrin oku kan lowo (Patrick Swayze) lati wa eni to seku pa ninu filmu Ghost. Ere re ninu filmu yi je ji o gba Ebun Wura Roboto re keji ati Ebun Akademi fun Osere Obinrin Keji Didarajulo. Awon filmu re miran tun ni Sister Act ati Sister Act 2, The Lion King, Made in America, How Stella Got Her Groove Back, Girl, Interrupted ati Rat Race, Star Trek: The Next Generation ati Jumpin' Jack Flash. Filmu to se gbeyin ni bi ohun fun Stretch ninu Toy Story 3[8][9].

Whoopi lọsi Ilè Iwè catholic, St Columba. Lẹyin naa ni óṣèrè lóbinrin naa kuró ni ilè iwè Washington Irving[10].

Ami Ẹyẹ ati Idànilọla

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Goldberg ti je didaloruko fun Ebun Emmy 13 fun ise re lori telifisan. Ohun lo je atokun eto ere-ibere telifisan Hollywood Squares lati 1998 de 2004. O ti je olootu eto iforojomitoro-oro ori telifisan The View lati 2007. Goldberg ti gba Ebun Grammy kan, Ebun Emmy meji, Ebun Wura Roboto meji, Ebun Tony kan, ati Ebun Oscar kan. Bakanna, Goldberg tun gba Ebun Akademi Filmu Britani kan, four Ebun Asayan People's merin be sini o ti gba eye pelu irawo lori Ojuona Agbajumo Hollywood ati ikan larin awon eniyan die ti won ti gba Ebun Oscar, Emmy, Grammy, ati Tony[11][12].