Jump to content

Eileen Heckart

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Eileen Heckart
Eileen Heckart
Ọjọ́ìbíAnna Eileen Herbert
(1919-03-29)Oṣù Kẹta 29, 1919
Columbus, Ohio, U.S.
AláìsíDecember 31, 2001(2001-12-31) (ọmọ ọdún 82)
Norwalk, Connecticut, U.S.
Iléẹ̀kọ́ gígaOhio State University (B.A.)
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1943–2000
Olólùfẹ́
John Harrison Yankee, Jr.
(m. 1942; died 1997)
Àwọn ọmọ3

Eileen Heckart ni a bi ní oṣù kẹta, ọdún 1919 to sÌ kú ní oṣù kejìlá, ọdún 2001. Ó jẹ́ òṣèré obìnrin tó siṣẹ́ fún ọgọ́ta ọdún[1].

Ìgbésí Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Heckart ni a bí sí ọ̀dọ̀ Anna Eileen Herbert ní Columbus, Ohio. Orúkọ ìyá òṣèré náà ń jẹ́ Esther ti bàbá rẹ̀ sí ǹ jẹ́ Leo Herbert.[2][3] Ní ọdún 1942, Heckart fẹ́ John Harrison Yankee tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ láti kọ́lẹ́ẹ̀jì. Àwọn méj́éjì bí ọmọ ọkùnrin mẹ́ta tí ìkan nínú àwọn ọmọ náà Luke Yankee kọ nípa ìtàn ìgbésí ayé ìyá rẹ̀.[4][5][6].

Heckart jẹ́ ènìyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìṣèlú tàbí àwùjọ́ ìdọ́gba ti gbogbo ènìyàn tó sì pàdé Ààrẹ nígbà náà Lyndon B. JohnsonWhite House ní ọdún 1967[7]. Òṣèré obìnrin náà jẹ́ ọmọ ìjọ Roman kátólíìkì.[8].

Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2001, òṣèré náà kú sí ilé rẹ̀ ní Norwalk, Connecticut ní ọmọ ọdún méjì-lé-lọ́gọ́rin lórí àìsàn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀foro. Wọ́n fi iná sun òkú rẹ̀, wọ́n sì tú eérú rẹ̀ káàkiri ìta gbangba ilé sinimá Music Box Theatre ní Manhattan, New York[9][10][11][12].

Eileen jáde láti ilé ìwé gíga ti ìpínlẹ̀ Ohio níbi tí ó ti ka eré orítàgé.[13]. Ó tẹ̀síwájú láti kọ eré orí ìtàgé ní HB Studio ní New York City.[14].

Àmì Ẹ̀yẹ àti Ìdánilọ́lá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eileen gba Ebun Akademi fún Obìnrin Òsèré Kejì tó dára jùlọ. Òṣèré náà gba Àmì Ẹ̀yẹ ti Tony, Emmy, Drama Desk, Drama league àti Golden Globe.[15][16][17]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]