Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Olusẹgun Ọbasanjọ)
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Olusegun Obasanjo
Olusegun Obasanjo (Brasilia 6 September 2005).jpg
Aare ìkejìlá Naijiria
Lórí àga
29 May, 1999 – 29 May, 2007
Vice President Atiku Abubakar
Asíwájú Abdulsalami Abubakar
Arọ́pò Umaru Yar'Adua
5th Olori Orile-ede Naijiria
Lórí àga
February 13, 1976 – October 1, 1979
Vice President Shehu Musa Yar'Adua
Asíwájú Murtala Mohammed
Arọ́pò Shehu Shagari
3rd Vice President of Nigeria
Lórí àga
July 29, 1975 – February 13, 1976
President Murtala Mohammed
Asíwájú J.E.A. Wey
Arọ́pò Shehu Musa Yar'Adua
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìbí Oṣù Kẹta 5, 1937 (1937-03-05) (ọmọ ọdún 79)
Abeokuta, Ipinle Ogun, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlú People's Democratic Party
Tọkọtaya pẹ̀lú Lynda Obasanjo (ex-wife, aláìsí), Stella Obasanjo (aláìsí)
Ẹ̀sìn Christianity

Mathiew Àrẹ̀mú Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ (ojoibi 5 March, 1937) jé ògágun tó tifèyìntì kúrò nínú iṣẹ́ Ológun ilè Nàìjíríà ati olóṣèlú ọmọ ilè Naijiria. Ohun ni Ààre ilè Naijiria lati odún 1999 títí dé ọdún 2007. Èyí ni ìgbà kejì tí Obasanjo yíò jé Ààre orílè-èdè Nàìjírìa. Obasanjo ni Aare laarin odun 19761979.

Igba ewe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Leyin ti o feyinti, o bere ise adase tire, iyen ni ise agbe. Ile-ise agbe re, iyen Obasanjo Farms, gbooro; o fere ma si abala ise agbe ti ko si nibe. Laarin odun 1976 si 1999, oruko Obasanjo di eni mimo ni gbogbo agbaye. Akinkanju ni ninu eto oselu agbaye. O wa ninu awon Igbimo to n petu si aawo ni awon orile-ede to n jagun, paapaa ni ile adulawo. O je ogunna gbongbo ninu egbe kan to koriira iwa ibaje, iyen ni Transparency International. Ni odun 1999, Obasanjo tun di aare alagbada fun orile-ede Naijiria, labe asia egbe PDP. A tun fi ibo yan an pada gege bi aare ni 2003. Okan pataki ninu afojusun ijoba Obasanjo ni igbogun ti iwa jegudujera (Anti-Corruption). Obasanjo gbiyanju dida ogo Naijiria pada laarin awon akegbe re ni agbaye (Committee of nations). O tun iyi owo naira to ti di aburunmu bi gaari omí se, gbigbowo-lori-oja (inflation) ti dinku jojo. Iye owo afipamo-soke-okun (external reserves) Naijiria ti ga gan-an ni, o to $40 billion bayii. Obasanjo tun fidi awon banki wa mule, pipo ti won po yeeriye tele ti dinku, won o ju meeedogbon lo mo bayii. Eyi mu ki awon eniyan ni igbekele ni fifi owo pamo si banki, won si tun le ya owo fun idagbasoke okowo won gbogbo. Lara awon eto ti ijoba Obasanjo n se ni tita awon ogun ijoba fun awon aladaani (privatisation policy). Eto yii ku die kaato. Idi ni pe awon olowo lo le ra awon ogun bee, talika kankan ko le ra won.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]