Sílíkọ́nù, tí èdè ìperí rẹ̀ ń jẹ́ tetravalentmetalloid, ni ó jẹ́ kẹ́míkà tí ó bí àmì Si tí atomic number rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìnlá. Sílíkọ́nù kìí sábà á gbéra tó àwọn èròjà inú rẹ̀ bíi analog carbon. Wọ́n ṣàwárí sílíkọ́nù fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1823, wọ́n sì fun ní orúkọ rẹ̀ Sílíkọ́nù ní ọdún 1808 láti ara (flang Látìnì: silicis, flints), àti -ium , ọ̀rọ̀ tí gbẹ̀yìn yí ninú orúkọ rẹ̀ ni ó ń túmọ̀ wípé ẹ̀yà irin ni. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fun ní orúkọ Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ ní ọdún 1817.
Sílíkọ́nù yí ni ó ṣìkẹ́jọ nínú àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àlùmọ́nì jùlọ lágbàáyé, amọ́ kò wọ́pọ̀ láti rí. Àwọn ayè tí a ti lè ṣe alábala-pàdé rẹ̀ ni àwọn bíi: eruku, iyẹ̀pẹ̀ ,planetoid àti inú àwọn ìgbàjà ahòho sánmọ̀ (planets). Ó ma ń wà gẹ́gẹ́ bí silixon dioxide tàbí silicates, nígbà tí ó jẹ́ wípé ìdá àádọ́rùn orí ilẹ̀ àgbáyé ni ó ní èròjà silicates minerals tí ó sì mú kí sílíkọ́nù ó ya mùrá ní orí-ilẹ̀ ayé lẹ́yìn afẹ́fẹ́ oxygen.[9]
Púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n ń ṣe àmúlò sílíkọ́nù ni wọn kìí sábà ń yàá-sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èròjà ilẹ̀ tí ó ba wá ṣáájú kí wọ́n tó lòó, . Lára àwọn ohun tí wọ́n ma ń lo sílíkọ́nù fún ni pípèsè ohun ìkọ́lé bíi amọ̀, iyẹ̀fun sílíkọ́nù fún bíríkì ìkọ́lé. Wọ́n tún ma ń po èròjà sílíkọ́nù mọ́ iyẹ̀fun símẹ́ntì láti fi ṣe kọnkéré ilé. Sílíkọ́nù tún ma ń ní àwọ̀ funfun bíi ceramic. Àwọn èròjà inú sílíkọ́nù ayé òde-òní ni silicon carbide tí ó ní agbára láti di sẹ̀rámíìkì tí ó nípọn gidi.
Sílíkọ́nù ṣe pàtàkì nínú ìsesí ilẹ̀ àti ewéko, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìwọ̀nba diẹ̀ nínú èròjà sílíkọ́nù ni àwọn ẹranko nílò. [10]
Bákan náà ni ìgbì àti ìdì omi bí omi òkun nílò sílíkọ́nù láti lara jọ, pàá pàá jùlọ àwọ ewéko orí omi.
↑ 5.05.15.25.3[1] Hopcroft, et al., "What is the Young's Modulus of Silicon?" IEEE Journal of Microelectromechanical Systems, 2010
↑Weeks, Mary Elvira (1932). "The discovery of the elements: XII. Other elements isolated with the aid of potassium and sodium: beryllium, boron, silicon, and aluminum". Journal of Chemical Education: 1386–1412.
↑Voronkov, M. G. (2007). "Silicon era". Russian Journal of Applied Chemistry80 (12): 2190. doi:10.1134/S1070427207120397.