Jump to content

Àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Áfíríkà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Five African dishes with three buns from Nigeria

Ilẹ̀ Áfíríkà jẹ́ ilẹ̀ tí ó tóbi sìkejì jùlọ ní gbogbo orílẹ̀ àwa ènìyàn, ó sì jẹ́ ilé fún ogunlọ́gọ̀ àwọn onírúurú àṣà àti àwọn onírúurú ẹ̀yà pẹ̀lú. Bí ilẹ̀ Áfíríkà ṣe gbọrọ̀gẹ̀jigẹ́ yìí náà ni ó ṣe hàn nínú àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn; nínú èròjà ìsebẹ̀, ọ̀nà tí à ń gbà dáná, àti ọgbọ́n àtinúdá tí a máa ń lò láti fi dáná.

Àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (Áfíríkà)

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Orúkọ oúnjẹ Àwòrán Orílẹẹ̀-èdè/Ẹkùn Àpèjúwe
Achu/Achou Cameroon Oúnjẹ tí wọ́n ti má ń lo iṣu kókò tí wọ́n gún níyán, ọbẹ̀ tí wọ́n fi epo pupa pèèlò, wọ́n a máa jẹ oúnjẹ yìí pẹ̀lú pọ̀nmọ́, tinú ẹran àti àwọn ẹran mìíràn.
Ming'oko Tanzania oúnje tí wọ́n ṣe láti ara àwọn iṣu tí wọ́n máa ń gbó gan-an.
Afang soup Nigeria Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ tí a le tọ ipasẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ẹ̀yà Ẹ́fíìkì Efik tí wọ́n wà ní gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ahriche Morocco Tripe wọn máa ń lọ́ ọ mọ́ igi tí wọn yóò sun ún. Ó dà gẹ́gẹ́ bí àsun.
Àkàrà, tàbí koose Nigeria, Benin, Ghana and Sierra Leone Oúnjẹ àwọn ẹ̀yà Yorùbá èyí tí a ṣe láti ara ẹ̀wà tí a gbo dáadáa tí a sì dín in, àwọn ẹ̀yà Hausa àti Ghana wọ́n a máa pè é ní Koose, a le jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìpanu ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà a máa fi ń mùkọ tàbí jẹ ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ láti fi ṣe oúnjẹ àárọ̀.
Alloco Cote d'Ivoire Ọ̀gẹ̀dẹ̀ díndín tí a máa ń jẹ pẹ̀lú ata gígún àti àlùbọ́sà.
Àmàlà Nigeria, Benin, Togo Oúnjẹ àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí a máa ṣe pẹ̀lú èlèbú èyí tí a le fi onírúurú ọbẹ̀ tó bá wù wá jẹ.
Asida North Africa Oúnjẹ tí a ṣe láti ara èlùbọ́ wíìtì, a máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú bọ́tà tàbí oyin nígbà mìíràn.
Attiéké Côte d'Ivoire Ìpanu tí a ṣe láti ara Ẹ̀gẹ́ [citation needed]
Banga soup Nigeria, Ghana, àti Cameroon A ṣe é láti ara èkùrọ́, wọ́n máa ń jẹ ẹ́ ní apá kan Nàìjíríà. Àwọn ẹ̀yà Akan ni orílẹ́-èdè Ghana máa ń pè é ní Abenkwan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú fuand fufu.
Bazeen Libya A máa ń fi tòmátò, ẹyin, àti iṣu ànàmọ́ jẹ ẹ́.
Bichak Morocco Àsun amúnúró
Biltong, Kilichi tàbí Segwapa Southern Africa, Zimbabwe, Botswana, South Africa, Cameroon, Niger, Nigeria, Zambia, Namibia ó fẹ́ fi ara jọ jerky. Ẹran tútù, bíi ẹran màálù tàbí ẹran ìgbẹ́, èyí tí a gé sí kéékèèké tí a fi èròjà sí kí a tó sá wọn kí wọn ó gbẹ.
Bobotie South Africa Spiced ground meat with an egg topping.
Boerewors South Africa, Zimbabwe Zambia, Namibia ó jẹ́ oúnjẹ tí ó wá láti orílẹ̀ èdè South Africa, èyí ni wọ́n ti máa ń da ẹran gidi àti ẹran elédè papọ̀ tí wọn yóò yí i láta.
Boerewors South Africa Oúnjẹ yìí gbajúgbajà ni orílẹ̀ èdè South-Africa
Braaibroodjies South Africa, Namibia Oúnjẹ yìí gbajúmọ̀ ní orílẹ́-èdè South Africa wọ́n máa ń sè é pẹ̀lú ẹ̀yẹ iná tàbí igi tí wọ́n dáná sí
Brik Tunisia Àjẹpọ́n-ẹnu-lá.
Briouat Morocco Olóyin aládùn
Bunny chow South Africa, Zimbabwe Wọ́n máa ń pè ní "Bunny", oúnjẹ tí a le tètè sè ni, a máa ń fi búrẹ́dì tí ó kún fún kọrí sè é.
Cachupa Cape Verde, São Tomé and Príncipe Ọbẹ̀ tí a fi ẹ̀wà àti ẹran sè.
Calulu Angola, São Tomé and Príncipe Ẹja gbígbẹ pẹ̀lú ẹ̀fọ́, nígbà mìíràn a le lo àlùbọ́sà, tòmátò, ilá, iṣu ànàmọ́, òróró àti àwọn nǹkan mìíràn. A máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrẹsì abbl.
Chakalaka South Africa, Zimbabwe Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́
Chakhchoukha Algeria Ọbẹ̀ tí a sè pẹ̀lú ẹran ọmọ àgùntàn tòmátò pẹ̀lú àwọn onírúurú èròjà.
Chermoula North Africa Oúnjẹ tí a sáábà máa ń fi òróró jẹ.
Cocada amarela Angola Oúnjẹ tí a pèsè láti ara ẹyin àti àgbọn
Couscous North Africa Oúnjẹ tí a pèsè láti ara semolina.
Dabo kolo Eritrea, Ethiopia, Democratic Republic of the Congo Búrẹ́dì kékeré tí a dín pẹ̀lú òróró.
Dambou Niger Ẹ̀yà oúnjẹ semolina kan èyí tí a máa ń pèsè pẹ̀lú ewé moringa. Èyí tí à le jẹ ní ìta àti àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó.
Delele Zimbabwe, Botswana Ilá tí a sè pẹ̀lú sódà ìdáná.
Draw soup Nigeria Ọbẹ̀ ilá.
Droëwors South Africa, Zimbabwe, Namibia Eléyìí jẹ́ boerewors tí wọ́n ti yan gbẹ.[citation needed]
Duqqa Egypt Àkójọpọ̀ àwọn egbòogi àti àwọn ohun èlò mìíràn.
Ẹ̀bà West Africa, Nigeria, Ghana Oúnjẹ tí a pèsè láti ara garri.
Echicha Nigeria Ẹ̀gẹ́, pigeon pea, àti òróró.
Edikang ikong Nigeria Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ tí a le tọpa lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Ẹ́fíìkì (Efik) ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Efo Riro Nigeria Ọbẹ̀ àwọn Yorùbá tí wọ́n máa ń lo ẹ̀fọ́ àti irú pẹ̀lú àwọn ohun èlò ọbẹ̀ mìíràn láti pèsè.
Egusi soup Nigeria Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí a máa ń lo ẹ̀gúsí láti pèèlò.
Ekwang Cameroon/Nigeria Oúnjẹ tí a ti mú ewé kòkó láti fi pèèlò tí a ṣe pẹ̀lú ọbẹ̀ ata. [1][2]
Eru Cameroon Ọbẹ̀ tí a sè pẹ̀lú ewé (eru) àti ewé gbúre. A sáábà máa ń fi ọbẹ̀ yìí jẹ fùfú.
Ẹ̀wà Àgànyìn Nigeria Oúnjẹ àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí a máa ń lo ẹ̀wà láti fi sè, a máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ata gúngún tàbí ata díndín.
Feijoada Southern Africa Ọbẹ̀ ẹ̀wà, ẹran màálù, àti ẹran Ẹlẹ́dẹ̀.
Felfla North Africa sàláàdì tí a fi ata, tòmátò, àti òróró pèsè.
Fesikh Egypt Tí a yan, tí a sì ṣe lọ́jọ̀.
Fio Fio Nigeria Ọbẹ̀ àwọn ẹ̀yà Igbo tí wọ́n ṣe láti ara piguean pea àti Achi
Fit-fit Ethiopia and Eritrea Oúnjẹ àwọn ará Ethiopia tí wọ́n máa ń fi ṣe oúnjẹ òwúrọ̀, wọ́n sì máa ń lò ó pẹ̀lú àwọn oúnjẹ mìíràn.
Frejon Nigeria Ẹ̀yà ọbẹ̀ kan tí a fi ẹ̀wà ṣè, tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Kristi sáábà máa ń jẹ nígba ọ̀sẹ̀ mímọ́ káàkiri àgbáyé.
Fufu West Africa and Central Africa Oúnjẹ àwọn tí wọ́n wà ní apá ìwọ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà àti ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Central Africa, ara ẹ̀gẹ́ ni a ti máa ń rí i.
Funkaso Nigeria Oúnjẹ àwọn ará Nàìjíríà tí wọ́n máa ń fi àgbàdo àti ṣúgà sí.
Ga'at Ethiopia and Eritrea A máa ń ṣe é pẹ̀lú ìyẹ̀fun barley, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan a máa lo ìyẹ̀fun wíìtì.
Gaàrí Cameroon, Nigeria, Sierra Leone, Benin, Togo, Ghana (in Ghana it is known as gari) oúnjẹ tó gbajúgbajà tí a yọ láti ara ẹ̀gẹ́. A le lò ó láti fi tẹ̀bà.
Gored gored Ethiopia and Eritrea ó jẹ́ ẹran tútù.
Harira Algeria and Morocco oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ará ìlú Algeria àti Morocco pẹ̀lú ọbẹ̀ àwọn Maghreb.
Harqma Maghreb North Africa Ọbẹ̀ tàbí ata tí a pèsè pẹ̀lú ẹran ọmọ àgùntàn.
Hawawshi Egypt oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ará Egypt
Himbasha Ethiopia and Eritrea oúnjẹ àjọyọ̀ àwọn Ethiopian àti [[Eritrea] èyí tí kìí fi bẹ́ẹ̀ dùn. [3]
Injera Ethiopia and Eritrea A yeast-risen flatbread with a unique, slightly spongy texture. Traditionally made out of teff flour, ó jẹ́ oúnjẹ tó gbajúgbajà ní Ethiopia àti Eritrea. Èyí tí ó fẹ́ fara jọ ti Somalia (níbi tí wọ́n ti ń pè é ní: canjeelo tàbí lahooh) àti Yemen (tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n sí: lahoh).
Iru Nigeria A máa ń lò ó láti fi ṣe àwọn onírúurú oúnjẹ tàbí ọbẹ̀. Ó gbajúgbajà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Isi ewu Nigeria oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ẹ̀yà kan tí wọ́n ń bẹ ní apá ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Orí ewúrẹ́ ni wọ́n fi máa ń ṣe ọbẹ̀ yìí.
Isidudu Southern Africa Ẹ̀kọ jíjẹ pẹ̀lú ẹ̀dọ̀ ẹran.
Jollof rice West Africa Oúnjẹ yìí gbajúgbajà káàkiri gbogbo àgbáyé. Ìrẹsì àti àwọn ohun èlò ìdáná mìíràn ni a fi máa pèèlò rẹ̀. [4]
Kachumbari East Africa Tòmátò tí ó jẹ́ ojúure àti àlùbọ́sà.
Kamounia Sudan, Tunisia Ọbẹ̀ ẹran àti ẹ̀dọ̀ tí a pèsè pẹ̀lú cumin.
Kapana Namibia Àsun àláta tí a fi máa ń jẹ chakalaka àti ìrẹsì.
Kedjenou Côte d'Ivoire Ọbẹ̀ àláta díndín tí a fi síkìnnì, ẹyẹ awó àti ẹ̀fọ́ sè.
Kitcha Ethiopia and Eritrea Búrẹ́dì tí a ṣè tí ó máa ń fara jọ èyí tí ó ti fẹ́ jóná.
Kitfo Ethiopia and Eritrea Raw beef marinated in mitmita (a chili powder based spice blend) and niter kibbeh.
Koeksister South Africa, Namibia and Botswana ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn ará ilẹ̀ South Africa.
Kuli-kuli Nigeria, Cameroon Oúnjẹ àwọn ẹ̀yà Hausa èyí tí wọ́n ṣe láti ara ẹ̀pà. Ó gbajúgbajà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Kushari Egypt Oúnjẹ tí a ṣe láti ara ìrẹsì, lentil, àti macaroni tí ó kún fún tòmátò àti àlùbọ́sà díndín.
Makroudh Tunisia and Morocco and Algeria Oúnjẹ tí ó máa ń kún fún èso dàbínù tàbí
alímọndi.
Mala Mogodu Southern Africa, Botswana, Zimbabwe Ọbẹ̀ ata tí wọ́n fi máa ń jẹ ẹ̀kọ́ gbígbóná ní orílẹ̀ èdè Southe Africa. Ó máa ń wọ́pọ̀ ní àsìkò ọyẹ́.
Marghi special Nigeria Ọbẹ̀ ẹja tí a sè pẹ̀lú ẹ̀fọ́ tí ó kún fún ata ilẹ̀, ata gígún àti àwọn ohun èlò ìsebẹ̀ mìíràn. [5]
Matbucha Morocco Tòmátò àti ata tàǹtàsé tí a sè papọ̀ pẹ̀lú ata ilẹ̀ àti ata gígún. [6]
Matoke Uganda Oúnjẹ tí a fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú tàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí kò pọ́n sè.
Mbongo Tchobi Cameroon Ọbẹ̀ dúdú tí a ṣe láti ara mbongo jíjóná, a sáábà máa ń sè é pẹ̀lú ẹran tàbí ẹja, tí a sì máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ọ̀gẹ̀dẹ̀ pípọ́n.
Méchoui North Africa, Cameroon Odidi àgùntàn tàbí ọmọ àgùntàn tí a yan. Ó wọ́pọ̀ ní North Africa àti ní àárín àwọn ẹ̀yà Bamileke tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Cameroon.
Moin moin Nigeria Oúnjẹ tí a ṣe láti ara ẹ̀wà, èyí tí a lọ ata mọ́ pẹ̀lú àwọn èròjà mìíràn.
Mrouzia Morocco tepo tiyọ̀
Mugoyo

Uganda

Mukhbaza Eritrea ìyẹ̀fun wíìtì, ọ̀gẹ̀dẹ̀, oyin, àti àwọn ohun èlò mìíràn.
Ndolé Cameroon oúnjẹ yìí gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Cameroon. Ó kún fún ọbẹ̀ èso Nut, ewúro, àti ẹja tàbí ẹran.
Nkwobi Nigeria Oúnjẹ àwọn ẹ̀yà Igbo tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ẹsẹ̀ màálù with cow foot, Ehu, epo pupa àti àwọn ohun èlò mìíràn.
Obusuma Kenya oúnjẹ àwọn ará Kenya tí wọ́n ṣe láti ara ìyẹ̀fun àgbàdo tí wọ́n máa ń fi omi gbígbóná rò. Ní Luhya ó jẹ́ oúnjẹ tí ó gbajúgbajà.
Ogbono soup Nigeria Oúnjẹ yìí wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Nàìjíríà, èso ogbono ni wọ́n máa ń lò, [7] with considerable local variation. Eso tí wọ́n bá lọ yìí ni wọ́n fi máa ṣe ọbẹ̀ ọ̀gbọ̀nọ̀ àti àwọn ohun èlò ìsebẹ̀ mìíràn. e,

[7] leaf vegetables and other vegetables.

Ogi Nigeria Ó jẹ́ oúnjẹ tí a rí láti ara àgbàdo àti jéró èyí tí ó wọ́pọ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [8]
Okpa Nigeria Oúnjẹ yìí gbajumo ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Owofibo Nigeria Ọbẹ̀ díndín tí a fi tòmátò àti akun ṣe nípa lílo òróró láti fi dín in.
Pampoenkoekies South Africa Oúnjẹ tí a tún ń pè ní "pumpkin fritters" nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Pap Southern Africa, Zimbabwe, South Africa, Malawi Oúnjẹ tí a rí láti ara àgbàdo lílọ tí awá fi omi gbígbóná pò.
Pepper soup West Africa, notably Nigeria Ọbẹ̀ ata tí ó kún fún oríṣiríṣi ata.
Phaletšhe Botswana Àgbàdo tí ó gbajúmọ̀ ní Botswana. Ẹ̀kọ yìí yàtọ̀ gédéńgbé sí sadza bẹ́ẹ̀ ni kìí ki tó phutu.
Phutu South Africa, Zimbabwe Oúnjẹ ìbílẹ̀ tí ó gbajúgbajà ní orílẹ̀ èdè South Africa
Placali Ivory Coast Placali jẹ́ oúnjẹ tí a rí láti ara ẹ̀gẹ́, ẹyìn, ilá, tàbí Kpala. Kò sí ẹni tí ó le sọ nípa orísun oúnjẹ yìí ṣùgbọ́n wọ́n sáábà máa ń pọ́n oúnjẹ yìí ní Ivory Coast.
Potjiekos Namibia and South Africa Wọ́n máa ń pè é ní oúnjẹ inú àwo kékeré. Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí wọ́n máa ń sè ní ìta gbangba lórí àrò. Oúnjẹ yìí ni wọ́n mú wá láti ilẹ̀ Netherlands sí orílẹ̀ èdè South Africa ní nǹkan bíi sẹ́ntúrì kẹtàdínlógún 17th century tí ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú máa jẹ nínú ilé wọn. [9]
Qatayef Egypt Oúnjẹ àwọn Lárúbáwá tí wọ́n sáábà máa ń jẹ nígbà àwẹ̀. Akkawi ní wọ́n máa ń lò láti fi pèèlò rẹ̀.[10][11]
Samosa Widespread Wọ́n máa ń dín in pẹ̀lú iṣu ànàmọ́, àlùbọ́sà, ẹran ṣínkìn àti àwọn èròjà ìsebẹ̀ mìíràn.
Serobe Botswana

South Africa

Irúfẹ́ oúnjẹ kan tí wọ́n máa ń sè pẹ̀lú ìfun ewúrẹ́ tàbí ti àgùntàn. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣètò rẹ̀ fara pẹ́ ti Mala Mogodu. Wọ́n máa ń j[gẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú [bogobe]], phaletšhe àti pé nígbà mìíràn wọn le jẹ ẹ́ pẹ̀lú (vetkoek) pàápàá jù lọ nígbà ọyẹ́.
Seswaa Botswana Oúnjẹ ìbílẹ̀ ti àwọn Botswana, èyí tí wọ́n máa ń fi ẹran màálù, ewúrẹ́ tàbí ti àgùntàn ṣe.[12] The fatty meat is generally boiled until tender in any pot, with "just enough salt",[13] and shredded or pounded.[14] Wọ́n sáábà máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú àgbàdo tàbí àsáró. [15][16]
Sfenj North Africa Donuts tí wọ́n sè pẹ̀lú òróró lẹ́yìn kí wọ́n ó tó rẹ ẹ́ sínú oyin tàbí wọ́n ṣúgà le lórí.
Shahan ful North Africa Oúnjẹ yìí gbajúmọ̀ ní Eritrea, Ethiopia, àti Sudan wọ́n sáábà máa ń jẹ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ òwúrọ̀.
Shish taouk North Africa
Skilpadjies South Africa Oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn South Africa, tí wọ́n tún máa ń pè ní àwọn orúkọ bí "muise", "vlermuise" àti "pofadder".{{citation needed|date=August 2016}
Suya Nigeria, Niger, Cameroon Oúnjẹ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Hausa tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, orílẹ̀ èdè Cameroon àti Niger. Suya jẹ oúnjẹ tí wọ́n máa ń pèsè láti ara ẹran màálù, ẹran ewúrẹ́, ẹja tàbí ṣínkìn. Wọ́n máa ń lo ata gígún, òróró, àti iyọ̀ láti fi jẹ ẹ́.
Ta'ameya Egypt Oúnjẹ ìgboro tí ó fẹ́ fara jọ falafel, ṣùgbọ́n tí wọn a máa lọ ẹ̀wà (Fava) dípò (chickpeas).
Tapalapa bread West Africa A traditional bread of western Búrẹ́dì ìbílẹ̀ tí àwọn ará ìlà oòrùn Áfíríkà, èyí tí ó wọ́pọ̀ ní Senegal, Gambia àti Guinea.
Tapioca pudding Widespread A máa ń ṣe é láti ara tapioca, mílìkì, àti àgbọn.[17] Its consistency ranges from thin (runny), to thick, to firm enough to eat with a fork.
Thieboudienne Senegal Wọ́n máa ń ṣe é pẹ̀lú ẹja, ìrẹsì àti tòmátò, bákan náà ni a le lo àlùbọ́sà, ègé, òróró ẹ̀pà àti àwọn èròjà mìíràn láti pèèlò rẹ̀.
Tomato bredie Namibia and South Africa Ọbẹ̀ àwọn ará orílẹ̀ èdè South Africa tí wọ́n máa ń pè ní "tamatiebredie".
Toum Levant Wọ́n máa ń jẹ oúnjẹ yìí ní Lebanon, the Levant, àti Egypt.
Ugali African Great Lakes Oúnjẹ tí a fi ìyẹ̀fun àgbàdo ṣe. [citation needed]
Umngqusho Widespread Oúnjẹ àwọn ará Bantu.
Wat Ethiopia and Eritrea Ọbẹ̀ àwọn ará Ethiopia àti Eritrea èyí tí a le sè pẹ̀lú ẹran ṣínkìn, ẹran màálù, ẹran àgùntàn, onírúurú ẹ̀fọ́ àti àwọn ohun èròjà mìíràn.[citation needed]
Waterblommetjiebredie Ọbẹ̀ tí a sè pẹ̀lú ẹran ọmọ àgùntàn.

Àdàkọ:Portal box

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "How to make delicious ekwang". Precious Core (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 14 November 2020. Retrieved 18 July 2021. 
  2. "Ekwang (Ekpang Nkukwo)". Immaculate Bites (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 27 December 2013. Retrieved 18 July 2021. 
  3. Warren, Olivia (2000). Taste of Eritrea: Recipes from One of East Africa's Most Interesting Little Countries. Hippocrene Books, Inc.. ISBN 978-0-7818-0764-7. https://archive.org/details/tasteoferitreare00warr. 
  4. Ellen Gibson Wilson (10 September 2008). A West African cook book. https://books.google.com/books?id=bZ0sAAAAYAAJ&q=jollof+rice. Retrieved 30 June 2016. 
  5. Afrolems. "Margi special". Retrieved 13 October 2020. 
  6. A Taste of Challah: A Comprehensive Guide to Challah and Bread Baking, Tamar Ansh, Feldheim Publishers, 2007, p. 150
  7. 7.0 7.1 Wright, Clifford A. (2011). The Best Soups in the World. John Wiley & Sons. p. 51. ISBN 978-1118109250. https://books.google.com/books?id=34sAwi6lJoUC&q=Ogbono+soup&pg=PT63. 
  8. "Fermented Cereals - A Global Perspective". United Nations FAO. Retrieved 22 July 2006. 
  9. Stan Engelbrecht; Tamsen de Beer; Ree Treweek (2005). African salad: A portrait of South Africans at Home. Day One Publishing. ISBN 0-620-35451-8. https://books.google.com/books?id=ateK_Ix3m4EC. 
  10. Sadat, Jehan; Sādāt, Jīhān (February 2002). A Woman of Egypt. ISBN 9780743237086. https://books.google.com/books?id=A5HkylcAkxoC&q=kunafa+egypt&pg=PA48. Retrieved 3 July 2015. 
  11. Abu-Zahra, Nadia (1999). The Pure and Powerful. ISBN 9780863722691. https://books.google.com/books?id=2unDlVK_AzEC&q=kunafa+egypt&pg=PA290. Retrieved 3 July 2015. 
  12. Matthew D. Firestone; Adam Karlin (February 2010). Botswana & Namibia. p. 70. ISBN 9781741049220. https://books.google.com/books?id=EgCSa3qJCoUC&q=%22seswaa%22&pg=PA70. Retrieved 30 June 2016. 
  13. Denbow, James Raymond; Thebe, Phenyo C.; Thebe, Phenyo C. (2006). Culture and Customs of Botswana. ISBN 9780313331787. https://books.google.com/books?id=8ycoVZ-DfrYC&q=%22seswaa%22+salty&pg=PA112. Retrieved 3 July 2015. 
  14. Edelstein, Sari (April 2010). Food, Cuisine, and Cultural Competency for Culinary, Hospitality, and .... ISBN 9781449618117. https://books.google.com/books?id=NQoWQTVcpVIC&q=%22seswaa%22&pg=PA353. Retrieved 3 July 2015. 
  15. Main, Michael; Smart!, Culture (13 October 2010). Botswana - Culture Smart!. ISBN 9781857335934. https://books.google.com/books?id=2rgBr_tmm1kC&q=%22seswaa%22&pg=PT118. Retrieved 3 July 2015. 
  16. Plessis, Heather Du (2000). Tourism Destinations Southern Africa. ISBN 9780702152726. https://books.google.com/books?id=NCWM_ht3-KcC&q=%22seswaa%22&pg=PA203. Retrieved 3 July 2015. 
  17. "Mango & Tapioca Pearls Dessert". christinesrecipes.com. 27 January 2010. Retrieved 6 September 2012. 

O tún le kà síwájú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:African cuisine Àdàkọ:Cuisine of the Mediterranean Àdàkọ:Cuisine Àdàkọ:Lists of prepared foods