Hope Uzodinma

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Hope Uzodinma jẹ́ olóṣèlú àti Gómìnà aṣẹ̀ṣẹ̀yàn ní [] ìpínlẹ̀ Imo]] lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà ti Nàìjíríà. Lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ (Supreme Court) dá Hope Uzodimma tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC láre lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí èsì ìbò tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Imo, tí ilé ẹjọ́ náà sìn pàṣẹ kí wọ́n búra fún un gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tó wọlé ní Ìpínlẹ̀ Imo. Èyí tako ìkéde àjọ tó ń ṣe kòkárí ètò ìbò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, (Independent National Electoral Commission, INEC) àti ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn (Appeal Court) pé Emeka Ihedioha tí ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party ní ó wọlé gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà.[1] [2] [3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "APC congratulates Senator Uzodinma on Supreme Court victory". TVC News Nigeria. 2020-01-14. Retrieved 2020-01-15. 
  2. "How Hope Uzodinma floored Ihedioha at Supreme Court - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2020-01-15. Retrieved 2020-01-15. 
  3. "BREAKING: Supreme Court Sacks Ihedioha As Imo Governor, Declares Hope Uzodinma Winner". Sahara Reporters. 2020-01-14. Retrieved 2020-01-15.